Luk 13:31-35
Luk 13:31-35 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ni wakati kanna diẹ ninu awọn Farisi tọ̀ ọ wá, nwọn si wi fun u pe, Jade, ki iwọ ki o si lọ kuro nihinyi: nitori Herodu nfẹ pa ọ. O si wi fun wọn pe, Ẹ lọ, ki ẹnyin si sọ fun kọ̀lọkọlọ nì pe, Kiyesi i, emi nlé awọn ẹmi èṣu jade, emi nṣe dida ara loni ati lọla, ati ni ijọ kẹta emi o ṣe aṣepe. Ṣugbọn emi kò jẹ má rìn loni, ati lọla, ati li ọtunla: kò le jẹ bẹ̃ pe woli ṣegbé lẹhin odi Jerusalemu. Jerusalemu, Jerusalemu, iwọ ti o pa awọn woli, ti o si sọ okuta lù awọn ti a rán si ọ pa; nigba melo li emi nfẹ iradọ bò awọn ọmọ rẹ, bi agbebọ̀ ti iradọ bò awọn ọmọ rẹ̀ labẹ́ apá rẹ̀, ṣugbọn ẹnyin kò fẹ! Sawõ, a fi ile nyin silẹ fun nyin li ahoro: lõtọ ni mo si wi fun nyin, Ẹnyin ki yio ri mi, titi yio fi di akoko ti ẹnyin o wipe, Olubukun li ẹniti o mbọ̀ wá li orukọ Oluwa.
Luk 13:31-35 Yoruba Bible (YCE)
Ní àkókò náà, àwọn Farisi kan wá sọ́dọ̀ Jesu, wọ́n sọ fún un pé, “Kúrò níhìn-ín nítorí Hẹrọdu fẹ́ pa ọ́.” Ó dá wọn lóhùn pé, “Ẹ lọ sọ fún ọlọ́gbọ́n ẹ̀wẹ́ yẹn pé, ‘Mò ń lé ẹ̀mí èṣù jáde, mo tún ń ṣe ìwòsàn lónìí ati lọ́la. Ní ọ̀tunla n óo parí iṣẹ́ mi.’ Mo níláti kúrò kí n máa bá iṣẹ́ mi lọ lónìí, lọ́la ati lọ́tùn-unla, nítorí bí wolii kan yóo bá kú, ní Jerusalẹmu ni yóo ti kú. “Jerusalẹmu! Jerusalẹmu! Ìwọ tí ò ń pa àwọn wolii, tí ò ń sọ òkúta lu àwọn tí a ti rán sí ọ, nígbà mélòó ni mo ti fẹ́ kó àwọn ọmọ rẹ jọ, bí adìẹ tií kó àwọn ọmọ rẹ̀ sí abẹ́ ìyẹ́ rẹ̀, ṣugbọn ẹ kò gbà fún mi! Ẹ wò ó! Ọlọrun ti fi ìlú yín sílẹ̀ fun yín! Ṣugbọn mo wí fun yín pé ẹ kò ní rí mi títí di ìgbà tí ẹ óo wí pé, ‘Alábùkún ni ẹni tí ó ń bọ̀ wá ní orúkọ Oluwa.’ ”
Luk 13:31-35 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ní wákàtí kan náà, díẹ̀ nínú àwọn Farisi tọ̀ ọ́ wá, wọ́n sì wí fún un pé, “Jáde, kí ìwọ sì lọ kúrò níhìn-ín yìí: nítorí Herodu ń fẹ́ pa ọ́.” Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ lọ, kí ẹ̀yin sì sọ fún kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ náà pé, ‘Kíyèsi i, èmi ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde, èmi ń ṣe ìmúláradá lónìí àti lọ́la, àti ní ọjọ́ mẹ́ta èmi ó ṣe àṣepé.’ Ṣùgbọ́n èmi kò jẹ́ má rìn lónìí, àti lọ́la, àti ní ọ̀túnla: dájúdájú wòlíì kan ki yóò ṣègbé lẹ́yìn odi Jerusalẹmu. “Jerusalẹmu, Jerusalẹmu, ìwọ tí o pa àwọn wòlíì, tí o sì sọ òkúta lu àwọn tí a rán sí ọ pa; nígbà mélòó ni èmi ń fẹ́ ràgà bo àwọn ọmọ rẹ, bí àgbébọ̀ adìyẹ ti í ràgà bo àwọn ọmọ rẹ̀ lábẹ́ apá rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò fẹ́! Sá wò ó, a fi ilé yín sílẹ̀ fún yín ní ahoro. Lóòtítọ́ ni mo sì wí fún yín, ẹ̀yin kì yóò sì rí mi títí yóò fi di àkókò tí ẹ̀yin ó wí pé, ‘Olùbùkún ni ẹni tí ó ń bọ̀ wá ní orúkọ Olúwa.’ ”