Luk 13:1-35

Luk 13:1-35 Bibeli Mimọ (YBCV)

AWỌN kan si wà li akokò na ti o sọ ti awọn ara Galili fun u, ẹ̀jẹ ẹniti Pilatu dàpọ mọ ẹbọ wọn. Jesu si dahùn o wi fun wọn pe, Ẹnyin ṣebi awọn ara Galili wọnyi ṣe ẹlẹṣẹ jù gbogbo awọn ara Galili lọ, nitoriti nwọn jẹ irú ìya bawọnni? Mo wi fun nyin, Bẹ̃kọ: bikoṣepe ẹnyin ronupiwada, gbogbo nyin ni yio ṣegbé bẹ̃ gẹgẹ. Tabi awọn mejidilogun, ti ile-iṣọ ni Siloamu wólu, ti o si pa wọn, ẹnyin ṣebi nwọn ṣe ẹlẹṣẹ jù gbogbo awọn enia ti mbẹ̀ ni Jerusalemu lọ? Mo wi fun nyin, Bẹ̃kọ: bikoṣepe ẹnyin ronupiwada, gbogbo nyin ni yio ṣegbé bẹ̃ gẹgẹ. O si pa owe yi fun wọn pe: Ọkunrin kan ni igi ọpọtọ kan ti a gbìn si ọgbà ajara rẹ̀; o si de, o nwá eso lori rẹ̀, kò si ri nkan. O si wi fun oluṣọgba rẹ̀ pe, Sawõ, lati ọdún mẹta li emi ti nwá iwò eso lori igi ọpọtọ yi, emi ko si ri nkan: ké e lulẹ; ẽṣe ti o fi ngbilẹ lasan pẹlu? O si dahùn o wi fun u pe, Oluwa, jọwọ rẹ̀ li ọdún yi pẹlu, titi emi o fi tú ilẹ idi rẹ̀ yiká, titi emi o si fi bu ilẹdu si i: Bi o ba si so eso, gẹgẹ: bi kò ba si so, njẹ lẹhin eyini ki iwọ ki o ke e lulẹ̀. O si nkọ́ni ninu sinagogu kan li ọjọ isimi. Si kiyesi i, obinrin kan wà nibẹ̀ ti o ni ẹmí ailera, lati ọdún mejidilogun wá, ẹniti o tẹ̀ tan, ti ko le gbé ara rẹ̀ soke bi o ti wù ki o ṣe. Nigbati Jesu ri i, o pè e si ọdọ, o si wi fun u pe, Obinrin yi, a tú ọ silẹ lọwọ ailera rẹ. O si fi ọwọ́ rẹ̀ le e: lojukanna a si ti sọ ọ di titọ, o si nyìn Ọlọrun logo. Olori sinagogu si kun fun irunu, nitoriti Jesu muni larada li ọjọ isimi, o si wi fun ijọ enia pe, Ijọ mẹfa ni mbẹ ti a fi iṣiṣẹ: ninu wọn ni ki ẹnyin ki o wá ki a ṣe dida ara nyin, ki o máṣe li ọjọ isimi. Nigbana li Oluwa dahùn, o si wi fun u pe, Ẹnyin agabagebe, olukuluku nyin ki itú malu tabi kẹtẹkẹtẹ rẹ̀ kuro nibuso, ki si ifà a lọ imu omi li ọjọ isimi? Kò si yẹ ki a tú obinrin yi ti iṣe ọmọbinrin Abrahamu silẹ ni ìde yi li ọjọ isimi, ẹniti Satani ti dè, sawõ lati ọdún mejidilogun yi wá? Nigbati o si wi nkan wọnyi, oju tì gbogbo awọn ọtá rẹ̀: gbogbo ijọ enia si yọ̀ fun ohun ogo gbogbo ti o ṣe lati ọwọ́ rẹ̀ wá. O si wipe, Kini ijọba Ọlọrun jọ? kili emi o si fi wé? O dabi wóro irugbin mustardi, ti ọkunrin kan mú, ti o si sọ sinu ọgbà rẹ̀; ti o si hù, o si di igi nla; awọn ẹiyẹ oju ọrun si ngbé ori ẹká rẹ̀. O si tún wipe, Kili emi iba fi ijọba Ọlọrun wé? O dabi iwukara, ti obinrin kan mu, ti o fi sinu oṣuwọn iyẹfun mẹta, titi gbogbo rẹ̀ o fi di wiwu. O si nlà arin ilu ati iletò lọ, o nkọ́ni, o si nrìn lọ si iha Jerusalemu. Ẹnikan si bi i pe, Oluwa, diẹ ha li awọn ti a o gbalà? O si wi fun wọn pe, Ẹ làkaka lati wọ̀ oju-ọ̀na tõro: nitori mo wi fun nyin, enia pipọ ni yio wá ọ̀na ati wọ̀ ọ, nwọn kì yio si le wọle. Nigbati bãle ile ba dide lẹkan fũ, ti o ba si ti sé ilẹkun, ẹnyin o si bẹ̀rẹ si iduro lode, ti ẹ o ma kànkun, wipe, Oluwa, Oluwa, ṣí i fun wa; on o si dahùn wi fun nyin pe, Emi kò mọ̀ nyin nibiti ẹnyin gbé ti wá: Nigbana li ẹnyin o bẹ̀rẹ si iwipe, Awa ti jẹ, awa si ti mu niwaju rẹ, iwọ si kọ́ni ni igboro ilu wa. On o si wipe, Emi wi fun nyin, emi kò mọ̀ nyin nibiti ẹnyin gbé ti wá; ẹ lọ kuro lọdọ mi gbogbo ẹnyin ti nṣiṣẹ ẹ̀ṣẹ. Ẹkún ati ipahinkeke yio wà nibẹ̀, nigbati ẹnyin o ri Abrahamu, ati Isaaki, ati Jakọbu, ati gbogbo awọn woli, ni ijọba Ọlọrun, ti a o si tì ẹnyin sode. Nwọn o si ti ìla-õrùn, ati ìwọ-õrùn wá, ati lati ariwa, ati gusù wá, nwọn o si joko ni ijọba Ọlọrun. Si wo o, awọn ẹni-ẹ̀hin mbẹ ti yio di ẹni-iwaju, awọn ẹni-iwaju mbẹ, ti yio di ẹni-ẹ̀hin. Ni wakati kanna diẹ ninu awọn Farisi tọ̀ ọ wá, nwọn si wi fun u pe, Jade, ki iwọ ki o si lọ kuro nihinyi: nitori Herodu nfẹ pa ọ. O si wi fun wọn pe, Ẹ lọ, ki ẹnyin si sọ fun kọ̀lọkọlọ nì pe, Kiyesi i, emi nlé awọn ẹmi èṣu jade, emi nṣe dida ara loni ati lọla, ati ni ijọ kẹta emi o ṣe aṣepe. Ṣugbọn emi kò jẹ má rìn loni, ati lọla, ati li ọtunla: kò le jẹ bẹ̃ pe woli ṣegbé lẹhin odi Jerusalemu. Jerusalemu, Jerusalemu, iwọ ti o pa awọn woli, ti o si sọ okuta lù awọn ti a rán si ọ pa; nigba melo li emi nfẹ iradọ bò awọn ọmọ rẹ, bi agbebọ̀ ti iradọ bò awọn ọmọ rẹ̀ labẹ́ apá rẹ̀, ṣugbọn ẹnyin kò fẹ! Sawõ, a fi ile nyin silẹ fun nyin li ahoro: lõtọ ni mo si wi fun nyin, Ẹnyin ki yio ri mi, titi yio fi di akoko ti ẹnyin o wipe, Olubukun li ẹniti o mbọ̀ wá li orukọ Oluwa.

Luk 13:1-35 Yoruba Bible (YCE)

Ní àkókò náà gan-an, àwọn kan sọ fún un nípa àwọn ará Galili kan tí Pilatu pa bí wọ́n ti ń rúbọ lọ́wọ́. Jesu sọ fún wọn pé, “Ẹ rò pé àwọn ará Galili wọnyi jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀ ju gbogbo ará Galili yòókù lọ ni, tí wọ́n fi jẹ irú ìyà yìí? Rárá o! Mò ń sọ fun yín pé bí ẹ kò bá ronupiwada, gbogbo yín ni ẹ óo ṣègbé bákan náà. Tabi àwọn mejidinlogun tí ilé-ìṣọ́ gíga ní Siloamu wólù, tí ó pa wọ́n, ṣé ẹ rò pé wọ́n burú ju gbogbo àwọn eniyan yòókù tí ó ń gbé Jerusalẹmu lọ ni? Rárá ó! Mo sọ fun yín pé bí ẹ kò bá ronupiwada, gbogbo yín ni ẹ óo ṣègbé bákan náà.” Ó wá pa òwe yìí fún wọn. Ó ní, “Ẹnìkan gbin igi ọ̀pọ̀tọ́ sinu ọgbà rẹ̀. Ó dé, ó ń wá èso lórí rẹ̀, ṣugbọn kò rí. Ó wá sọ fún olùtọ́jú ọgbà pé, ‘Ṣé o rí i! Ó di ọdún mẹta tí mo ti ń wá èso lórí igi ọ̀pọ̀tọ́ yìí tí n kò rí. Gé e lulẹ̀. Kí ló dé tí yóo kàn máa gbilẹ̀ lásán?’ Ṣugbọn olùtọ́jú ọgbà dá a lóhùn pé, ‘Alàgbà, fi í sílẹ̀ ní ọdún yìí, kí n walẹ̀ yí i ká, kí n bu ilẹ̀dú sí i. Bí ó bá so èso ní ọdún tí ń bọ̀, ó dára. Bí kò bá so èso, gé e.’ ” Jesu ń kọ́ àwọn eniyan lẹ́kọ̀ọ́ ninu ilé ìpàdé kan ní Ọjọ́ Ìsinmi. Obinrin kan wà tí ó ní irú ẹ̀mí èṣù kan tí ó sọ ọ́ di aláìlera fún ọdún mejidinlogun. Ẹ̀yìn rẹ̀ tẹ̀, kò lè nàró dáradára. Nígbà tí Jesu rí i, ó pè é, ó sọ fún un pé, “Obinrin yìí, a wò ọ́ sàn kúrò ninu àìlera rẹ.” Jesu bá gbé ọwọ́ mejeeji lé e. Lẹsẹkẹsẹ ni ẹ̀yìn rẹ̀ bá nà, ó bá ń fi ògo fún Ọlọrun. Ṣugbọn inú bí olórí ilé ìpàdé nítorí Jesu ṣe ìwòsàn ní Ọjọ́ Ìsinmi. Ó bá sọ fún àwọn eniyan pé, “Ọjọ́ mẹfa wà tí a níláti fi ṣiṣẹ́. Ẹ wá fún ìwòsàn láàrin àwọn ọjọ́ mẹfa yìí. Ẹ má wá fún ìwòsàn ní Ọjọ́ Ìsinmi mọ́!” Ṣugbọn Oluwa dá a lóhùn pé, “Ẹ̀yin alágàbàgebè! Èwo ninu yín ni kì í tú mààlúù tabi kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ sílẹ̀ ní ibùjẹ ẹran kí ó lọ fún un ní omi ní Ọjọ́ Ìsinmi? Ẹ wá wo obinrin yìí, ọmọ Abrahamu, tí Satani ti dè fún ọdún mejidinlogun. Ṣé kò yẹ kí á tú u sílẹ̀ ninu ìdè yìí ní Ọjọ́ Ìsinmi?” Nígbà tí ó sọ̀rọ̀ báyìí, ojú ti gbogbo àwọn tí ó takò o. Ńṣe ni inú gbogbo àwọn eniyan dùn nítorí gbogbo ohun ìyanu tí ó ń ṣe. Nítorí náà Jesu sọ pé, “Kí ni à bá fi ìjọba Ọlọrun wé? Kí ni ǹ bá fi ṣe àkàwé rẹ̀? Ó dàbí ẹyọ wóró musitadi kan, tí ẹnìkan mú, tí ó gbìn sí oko rẹ̀. Nígbà tí ó bá dàgbà, ó di igi, àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run wá ń ṣe ìtẹ́ wọn sí orí ẹ̀ka rẹ̀.” Ó tún sọ pé, “Kí ni ǹ bá fi ìjọba Ọlọrun wé? Ó dàbí ìwúkàrà tí obinrin kan mú, tí ó pò mọ́ òṣùnwọ̀n ìyẹ̀fun ńláńlá mẹta títí gbogbo rẹ̀ fi wú sókè.” Bí Jesu ti ń bá ìrìn àjò rẹ̀ lọ láti ìlú dé ìlú ati láti abúlé dé abúlé, ó ń kọ́ àwọn eniyan bí ó ti ń lọ sí Jerusalẹmu. Ẹnìkan wá bi í pé, “Alàgbà, ǹjẹ́ àwọn eniyan tí yóo là kò ní kéré báyìí?” Jesu wá sọ fún àwọn eniyan pé, “Ẹ dù láti gba ẹnu ọ̀nà tí ó há wọlé, nítorí mò ń sọ fun yín pé ọpọlọpọ ni ó ń wá ọ̀nà láti wọlé ṣugbọn wọn kò lè wọlé. Nígbà tí baálé ilé bá ti dìde, tí ó bá ti ìlẹ̀kùn, ẹ óo wá dúró lóde, ẹ óo bẹ̀rẹ̀ sí kanlẹ̀kùn, ẹ óo wí pé, ‘Alàgbà, ṣílẹ̀kùn fún wa!’ Ṣugbọn yóo da yín lóhùn pé, ‘Èmi kò mọ̀ yín rí!’ Ẹ óo wá máa sọ pé, ‘A jẹ, a mu níwájú rẹ. O kọ́ àwọn eniyan lẹ́kọ̀ọ́ ní ìgboro wa.’ Ṣugbọn yóo sọ fun yín pé, ‘Èmi kò mọ̀ yín rí. Ẹ kúrò lọ́dọ̀ mi, gbogbo ẹ̀yin oníṣẹ́ ibi.’ Ẹkún ati ìpayínkeke yóo wà nígbà tí ẹ bá rí Abrahamu ati Isaaki ati Jakọbu ati gbogbo àwọn wolii ní ìjọba Ọlọrun, tí wọ́n wá tì yín mọ́ òde. Àwọn eniyan yóo wá láti ìlà oòrùn ati láti ìwọ̀ oòrùn, láti àríwá ati láti gúsù, wọn yóo jókòó níbi àsè ní ìjọba Ọlọrun. Àwọn èrò ẹ̀yìn yóo di ará iwájú; àwọn ará iwájú yóo di èrò ẹ̀yìn.” Ní àkókò náà, àwọn Farisi kan wá sọ́dọ̀ Jesu, wọ́n sọ fún un pé, “Kúrò níhìn-ín nítorí Hẹrọdu fẹ́ pa ọ́.” Ó dá wọn lóhùn pé, “Ẹ lọ sọ fún ọlọ́gbọ́n ẹ̀wẹ́ yẹn pé, ‘Mò ń lé ẹ̀mí èṣù jáde, mo tún ń ṣe ìwòsàn lónìí ati lọ́la. Ní ọ̀tunla n óo parí iṣẹ́ mi.’ Mo níláti kúrò kí n máa bá iṣẹ́ mi lọ lónìí, lọ́la ati lọ́tùn-unla, nítorí bí wolii kan yóo bá kú, ní Jerusalẹmu ni yóo ti kú. “Jerusalẹmu! Jerusalẹmu! Ìwọ tí ò ń pa àwọn wolii, tí ò ń sọ òkúta lu àwọn tí a ti rán sí ọ, nígbà mélòó ni mo ti fẹ́ kó àwọn ọmọ rẹ jọ, bí adìẹ tií kó àwọn ọmọ rẹ̀ sí abẹ́ ìyẹ́ rẹ̀, ṣugbọn ẹ kò gbà fún mi! Ẹ wò ó! Ọlọrun ti fi ìlú yín sílẹ̀ fun yín! Ṣugbọn mo wí fun yín pé ẹ kò ní rí mi títí di ìgbà tí ẹ óo wí pé, ‘Alábùkún ni ẹni tí ó ń bọ̀ wá ní orúkọ Oluwa.’ ”

Luk 13:1-35 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Àwọn kan sì wá ní àkókò náà tí ó sọ ti àwọn ará Galili fún un, ẹ̀jẹ̀ ẹni tí Pilatu dàpọ̀ mọ́ ẹbọ wọn. Jesu sì dáhùn ó wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin ṣe bí àwọn ará Galili wọ̀nyí ṣe ẹlẹ́ṣẹ̀ ju gbogbo àwọn ará Galili lọ, nítorí wọ́n jẹ irú ìyà bá-wọ̀n-ọn-nì? Mo wí fún yín, bẹ́ẹ̀ kọ́: bí kò ṣe pé ẹ̀yin pẹ̀lú ronúpìwàdà, gbogbo yín ni yóò ṣègbé bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́. Tàbí àwọn méjì-dínlógún, tí ilé ìṣọ́ ní Siloamu wó lù, tí ó sì pa wọ́n, ẹ̀yin ṣe bí wọ́n ṣe ẹlẹ́ṣẹ̀ ju gbogbo àwọn ènìyàn tí ń bẹ ní Jerusalẹmu lọ? Mo wí fún yín, bẹ́ẹ̀ kọ́: bí kò ṣe pé ẹ̀yin ronúpìwàdà, gbogbo yín ni yóò ṣègbé bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́.” Ó sì pa òwe yìí fún wọn pé: “Ọkùnrin kan ní igi ọ̀pọ̀tọ́ kan tí a gbìn sí ọgbà àjàrà rẹ̀; ó sì dé, ó ń wá èso lórí rẹ̀, kò sì rí nǹkan. Ó sì wí fún olùṣọ́gbà rẹ̀ pé, ‘Sá à wò ó, láti ọdún mẹ́ta ni èmi ti ń wá í wo èso lórí igi ọ̀pọ̀tọ́ yìí, èmi kò sì rí nǹkan: ké e lulẹ̀; èéṣe tí ó fi ń gbilẹ̀ lásán pẹ̀lú?’ “Ó sì dáhùn ó wí fún un pé, ‘Olúwa, jọ̀wọ́ rẹ̀ ní ọdún yìí pẹ̀lú, títí èmi ó fi tu ilẹ̀ ìdí rẹ̀ yíká, títí èmi ó sì fi bu ìlẹ̀dú sí i: Bí ó bá sì so èso, o dara bẹ́ẹ̀: bí kò bá sì so, ǹjẹ́ lẹ́yìn èyí nì kí ìwọ kí ó ké e lulẹ̀.’ ” Ó sì ń kọ́ni nínú Sinagọgu kan ní ọjọ́ ìsinmi. Sì kíyèsi i, obìnrin kan wà níbẹ̀ tí ó ní ẹ̀mí àìlera, láti ọdún méjì-dínlógún wá, ẹni tí ó tẹ̀ tán, tí kò le gbé ara rẹ̀ sókè bí ó ti wù kí ó ṣe. Nígbà tí Jesu rí i, ó pè é sí ọ̀dọ̀, ó sì wí fún un pé, “Obìnrin yìí, a tú ọ sílẹ̀ lọ́wọ́ àìlera rẹ.” Ó sì fi ọwọ́ rẹ̀ lé e: Lójúkan náà a sì ti sọ ọ́ di títọ́, ó sì ń yin Ọlọ́run lógo. Olórí Sinagọgu sì kún fún ìrunú, nítorí tí Jesu mú ni láradá ní ọjọ́ ìsinmi, ó sì wí fún ìjọ ènìyàn pé, ọjọ́ mẹ́fà ní ń bẹ tí a fi í ṣiṣẹ́: nínú wọn ni kí ẹ̀yin kí ó wá kí á ṣe dídá ara yín, kí ó má ṣe ní ọjọ́ ìsinmi. Nígbà náà ni Olúwa dáhùn, ó sì wí fún un pé, “Ẹ̀yin àgàbàgebè, olúkúlùkù yín kì í tú màlúù tàbí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ kúrò ní ibùso, kì í sì í fà á lọ mu omi ní ọjọ́ ìsinmi. Kò sì yẹ kí a tú obìnrin yìí tí í ṣe ọmọbìnrin Abrahamu sílẹ̀ ní ìdè yìí ní ọjọ́ ìsinmi, ẹni tí Satani ti dè, sá à wò ó láti ọdún méjì-dínlógún yìí wá?” Nígbà tí ó sì wí nǹkan wọ̀nyí, ojú ti gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ̀: gbogbo ìjọ ènìyàn sì yọ̀ fún ohun ìyanu gbogbo tí ó ṣe. Ó sì wí pé, “Kín ni ìjọba Ọlọ́run jọ? Kín ni èmi ó sì fiwé? Ó dàbí hóró musitadi, tí ọkùnrin kan mú, tí ó sì sọ sínú ọgbà rẹ̀; tí ó sì hù, ó sì di igi ńlá; àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run sì ń gbé orí ẹ̀ka rẹ̀.” Ó sì tún wí pé, “Kín ni èmi ìbá fi ìjọba Ọlọ́run wé? Ó dàbí ìwúkàrà, tí obìnrin kan mú, tí ó fi sínú òṣùwọ̀n ìyẹ̀fun mẹ́ta, títí gbogbo rẹ̀ ó fi di wíwú.” Ó sì ń la àárín ìlú àti ìletò lọ, ó ń kọ́ni, ó sì ń rìn lọ sí Jerusalẹmu. Ẹnìkan sì bi í pé, Olúwa, díẹ̀ ha kọ ni àwọn tí a ó gbàlà? Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ làkàkà láti gba ojú ọ̀nà tóóró wọlé: nítorí mo wí fún yín, ènìyàn púpọ̀ ni yóò wá ọ̀nà láti wọ̀ ọ́, wọn kì yóò sì lè wọlé. Nígbà tí baálé ilé bá dìde lẹ́ẹ̀kan fùú, tí ó bá sí ti ìlẹ̀kùn, ẹ̀yin ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í dúró lóde, tí ẹ ó máa kan ìlẹ̀kùn, wí pé, ‘Olúwa, Olúwa, ṣí i fún wa!’ “Òun ó sì dáhùn wí fún yín pé, ‘Èmi kò mọ̀ ibi tí ẹ̀yin ti wá.’ Bẹ́ẹ̀ ni èmi kò mọ̀ yín. “Nígbà náà ni ẹ̀yin ó bẹ̀rẹ̀ sí wí pé, ‘Àwa ti jẹ, àwa sì ti mu níwájú rẹ, ìwọ sì kọ́ni ní ìgboro ìlú wa.’ “Òun ó sì wí pé, ‘Èmi wí fún yín èmi kò mọ̀ ibi tí ẹ̀yin ti wá; ẹ lọ kúrò lọ́dọ̀ mi gbogbo ẹ̀yin tí ń ṣiṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀.’ “Níbẹ̀ ni ẹkún àti ìpahínkeke yóò wà, nígbà tí ẹ̀yin ó rí Abrahamu, àti Isaaki, àti Jakọbu, àti gbogbo àwọn wòlíì, ní ìjọba Ọlọ́run, tí a ó sì ti ẹ̀yin sóde. Wọn ó sì ti ilẹ̀ ìlà-oòrùn, àti ìwọ̀-oòrùn wá, àti láti àríwá, àti gúúsù wá, wọn ó sì jókòó ní ìjọba Ọlọ́run. Sì wò ó, àwọn ẹni ẹ̀yìn ń bẹ tí yóò di ẹni iwájú, àwọn ẹni iwájú ń bẹ tí yóò di ẹni ẹ̀yìn.” Ní wákàtí kan náà, díẹ̀ nínú àwọn Farisi tọ̀ ọ́ wá, wọ́n sì wí fún un pé, “Jáde, kí ìwọ sì lọ kúrò níhìn-ín yìí: nítorí Herodu ń fẹ́ pa ọ́.” Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ lọ, kí ẹ̀yin sì sọ fún kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ náà pé, ‘Kíyèsi i, èmi ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde, èmi ń ṣe ìmúláradá lónìí àti lọ́la, àti ní ọjọ́ mẹ́ta èmi ó ṣe àṣepé.’ Ṣùgbọ́n èmi kò jẹ́ má rìn lónìí, àti lọ́la, àti ní ọ̀túnla: dájúdájú wòlíì kan ki yóò ṣègbé lẹ́yìn odi Jerusalẹmu. “Jerusalẹmu, Jerusalẹmu, ìwọ tí o pa àwọn wòlíì, tí o sì sọ òkúta lu àwọn tí a rán sí ọ pa; nígbà mélòó ni èmi ń fẹ́ ràgà bo àwọn ọmọ rẹ, bí àgbébọ̀ adìyẹ ti í ràgà bo àwọn ọmọ rẹ̀ lábẹ́ apá rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò fẹ́! Sá wò ó, a fi ilé yín sílẹ̀ fún yín ní ahoro. Lóòtítọ́ ni mo sì wí fún yín, ẹ̀yin kì yóò sì rí mi títí yóò fi di àkókò tí ẹ̀yin ó wí pé, ‘Olùbùkún ni ẹni tí ó ń bọ̀ wá ní orúkọ Olúwa.’ ”