Luk 10:38-41
Luk 10:38-41 Bibeli Mimọ (YBCV)
O si ṣe, bi nwọn ti nlọ, o wọ̀ iletò kan: obinrin kan ti a npè ni Marta si gbà a si ile rẹ̀. O si ni arabinrin kan ti a npè ni Maria, ti o si joko lẹba ẹsẹ Jesu, ti o ngbọ́ ọ̀rọ rẹ̀. Ṣugbọn Marta nṣe iyọnu ohun pupọ, o si tọ̀ ọ wá, o ni, Oluwa, iwọ kò kuku ṣu si i ti arabinrin mi fi mi silẹ lati mã nikan ṣe aisimi? Wi fun u ki o ràn mi lọwọ. Ṣugbọn Jesu si dahùn, o si wi fun u pe, Marta, Marta, iwọ nṣe aniyan ati lãlã nitori ohun pipọ
Luk 10:38-41 Yoruba Bible (YCE)
Bí wọ́n ti ń lọ ninu ìrìn àjò wọn, Jesu wọ inú abúlé kan. Obinrin kan tí ń jẹ́ Mata bá gbà á lálejò. Mata ní arabinrin kan tí ó ń jẹ́ Maria. Maria yìí jókòó lẹ́bàá ẹsẹ̀ Jesu, ó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀. Ṣugbọn Mata kò rójú nítorí aájò tí ó ń ṣe nípa oúnjẹ. Ni Mata bá wá, ó ní, “Alàgbà, arabinrin mi fi èmi nìkan sílẹ̀ láti máa tọ́jú oúnjẹ, o sì dákẹ́ ò ń wò ó níran! Sọ fún un kí ó wá ràn mí lọ́wọ́.” Ṣugbọn Oluwa dá a lóhùn pé, “Mata! Mata! Ò ń ṣe aájò, o sì ń dààmú nípa ohun pupọ.
Luk 10:38-41 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ó sì ṣe, bí wọ́n ti ń lọ, o wọ ìletò kan, obìnrin kan tí a ń pè ní Marta sì gbà á sí ilé rẹ̀. Ó sì ní arábìnrin kan tí a ń pè ní Maria tí ó sì jókòó lẹ́bàá ẹsẹ̀ Olúwa, tí ó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀. Ṣùgbọ́n Marta ń ṣe ìyọnu ohun púpọ̀, ó sì tọ̀ ọ́ wá, ó wí pé, “Olúwa, ìwọ kò sì bìkítà sí ti arábìnrin mi pé ó fi mí sílẹ̀ láti máa nìkan ṣe ìránṣẹ́? Wí fún un kí ó ràn mí lọ́wọ́.” Ṣùgbọ́n Olúwa sì dáhùn, ó sì wí fún un pé, “Marta, Marta, ìwọ ń ṣe àníyàn àti làálàá nítorí ohun púpọ̀.