Luk 10:25-27
Luk 10:25-27 Bibeli Mimọ (YBCV)
Si kiyesi i, amofin kan dide, o ndán a wò, o ni, Olukọni, kili emi o ṣe ki emi ki o le jogún iyè ainipẹkun? O si bi i pe, Kili a kọ sinu iwe ofin? bi iwọ ti kà a? O si dahùn wipe, Ki iwọ ki o fi gbogbo àiya rẹ, ati gbogbo ọkàn rẹ, ati gbogbo agbara rẹ, ati gbogbo inu rẹ fẹ Oluwa Ọlọrun rẹ; ati ẹnikeji rẹ bi ara rẹ.
Luk 10:25-27 Yoruba Bible (YCE)
Amòfin kan wá, ó fi ìbéèrè yìí wá Jesu lẹ́nu wò. Ó ní, “Olùkọ́ni, kí ni kí n ṣe kí n lè jogún ìyè ainipẹkun?” Jesu bi í pé, “Kí ni ó wà ní àkọsílẹ̀ ninu òfin? Báwo ni o ti túmọ̀ rẹ̀?” Ó dáhùn pé, “Kí ìwọ fẹ́ràn Oluwa Ọlọrun rẹ pẹlu gbogbo ọkàn rẹ, ati pẹlu gbogbo ẹ̀mí rẹ, ati pẹlu gbogbo agbára rẹ ati pẹlu gbogbo òye rẹ; sì fẹ́ràn ọmọnikeji rẹ bí ara rẹ.”
Luk 10:25-27 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Sì kíyèsi i amòfin kan dìde, ó ń dán an wò, ó ní, “Olùkọ́, kín ni èmi ó ṣe kí èmi lè jogún ìyè àìnípẹ̀kun?” Ó sì bi í pé, “Kí ni a kọ sínú ìwé òfin? Báwo ni ìwọ sì ti kà á?” Ó sì dáhùn wí pé, “ ‘Kí ìwọ fi gbogbo àyà rẹ, àti gbogbo ọkàn rẹ, àti gbogbo agbára rẹ, àti gbogbo inú rẹ fẹ́ Olúwa Ọlọ́run rẹ’; àti, ‘ẹnìkejì rẹ bí ara rẹ.’ ”