Luk 10:17-19
Luk 10:17-19 Bibeli Mimọ (YBCV)
Awọn adọrin na si fi ayọ̀ pada, wipe, Oluwa, awọn ẹmi èṣu tilẹ foribalẹ fun wa li orukọ rẹ. O si wi fun wọn pe, Emi ri Satani ṣubu bi manamana lati ọrun wá. Kiyesi i, emi fun nyin li aṣẹ lati tẹ̀ ejò ati akẽkẽ mọlẹ, ati lori gbogbo agbara ọtá: kò si si ohunkan bi o ti wù ki o ṣe, ti yio pa-nyin-lara.
Luk 10:17-19 Yoruba Bible (YCE)
Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mejilelaadọrin pada dé pẹlu ayọ̀. Wọ́n ní, “Oluwa, àwọn ẹ̀mí èṣù pàápàá gbọ́ràn sí wa lẹ́nu ní orúkọ rẹ.” Ó bá sọ fún wọn pé, “Mo rí Satani tí ó ti ọ̀run já bọ́ bí ìràwọ̀. Mo fun yín ní àṣẹ láti tẹ ejò ati àkeekèé mọ́lẹ̀. Mo tún fun yín ní àṣẹ lórí gbogbo agbára ọ̀tá. Kò sí ohunkohun tí yóo pa yín lára.
Luk 10:17-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Àwọn àádọ́rin náà sì fi ayọ̀ padà, wí pé, “Olúwa, àwọn ẹ̀mí èṣù tilẹ̀ foríbalẹ̀ fún wa ní orúkọ rẹ.” Ó sì wí fún wọn pé, “Èmí rí Satani ṣubú bí mọ̀nàmọ́ná láti ọ̀run wá. Kíyèsi i, èmí fún yín ní àṣẹ láti tẹ ejò àti àkéekèe mọ́lẹ̀, àti lórí gbogbo agbára ọ̀tá: kò sì ṣí ohun kan bí ó ti wù tí ó ṣe, tí yóò pa yín lára.