Luk 10:13-37
Luk 10:13-37 Yoruba Bible (YCE)
“O gbé! Korasini. O gbé! Bẹtisaida. Nítorí bí ó bá jẹ́ pé ní Tire ati ní Sidoni ni a ti ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu tí a ṣe láàrin yín ni, wọn ìbá ti ronupiwada tipẹ́tipẹ́, wọn ìbá jókòó ninu eérú pẹlu aṣọ ọ̀fọ̀. Yóo sàn fún Tire ati fún Sidoni ní ọjọ́ ìdájọ́ jù fún yín lọ. Ìwọ Kapanaumu, o rò pé a óo gbé ọ ga dé ọ̀run ni? Rárá o! Ní ọ̀gbun jíjìn ni a óo sọ ọ́ sí! “Ẹni tí ó bá gbọ́ tiyín, ó gbọ́ tèmi. Ẹni tí ó bá kọ̀ yín èmi ni ó kọ̀. Ẹni tí ó bá sì wá kọ̀ mí, ó kọ ẹni tí ó fi iṣẹ́ rán mi.” Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mejilelaadọrin pada dé pẹlu ayọ̀. Wọ́n ní, “Oluwa, àwọn ẹ̀mí èṣù pàápàá gbọ́ràn sí wa lẹ́nu ní orúkọ rẹ.” Ó bá sọ fún wọn pé, “Mo rí Satani tí ó ti ọ̀run já bọ́ bí ìràwọ̀. Mo fun yín ní àṣẹ láti tẹ ejò ati àkeekèé mọ́lẹ̀. Mo tún fun yín ní àṣẹ lórí gbogbo agbára ọ̀tá. Kò sí ohunkohun tí yóo pa yín lára. Ẹ má yọ̀ ní ti pé àwọn ẹ̀mí èṣù gbọ́ràn si yín lẹ́nu; ṣugbọn ẹ máa yọ̀ nítorí a ti kọ orúkọ yín sí ọ̀run.” Ní àkókò náà Jesu láyọ̀ ninu Ẹ̀mí Mímọ́. Ó ní, “Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ, Baba, Oluwa ọ̀run ati ayé, nítorí o ti pa nǹkan wọnyi mọ́ fún àwọn ọlọ́gbọ́n ati àwọn olóye; ṣugbọn o fi wọ́n han àwọn òpè. Bẹ́ẹ̀ ni, Baba, nítorí bí ó ti tọ́ ní ojú rẹ ni. “Baba mi ti fi ohun gbogbo lé mi lọ́wọ́. Kò sí ẹni tí ó mọ ẹni tí Ọmọ jẹ́, àfi Baba. Kò sí ẹni tí ó mọ ẹni tí Baba jẹ́, àfi Ọmọ; àtúnfi àwọn tí Ọmọ bá fẹ́ fi Baba hàn fún.” Jesu yipada sí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ níkọ̀kọ̀, ó ní, “Ẹ ṣe oríire tí ojú yín rí àwọn ohun tí ẹ rí, nítorí mò ń sọ fun yín pé ọ̀pọ̀ àwọn wolii ati àwọn ọba ni wọ́n fẹ́ rí àwọn nǹkan tí ẹ rí, ṣugbọn tí wọn kò rí i; wọ́n fẹ́ gbọ́ ohun tí ẹ gbọ́ ṣugbọn wọn kò gbọ́ ọ.” Amòfin kan wá, ó fi ìbéèrè yìí wá Jesu lẹ́nu wò. Ó ní, “Olùkọ́ni, kí ni kí n ṣe kí n lè jogún ìyè ainipẹkun?” Jesu bi í pé, “Kí ni ó wà ní àkọsílẹ̀ ninu òfin? Báwo ni o ti túmọ̀ rẹ̀?” Ó dáhùn pé, “Kí ìwọ fẹ́ràn Oluwa Ọlọrun rẹ pẹlu gbogbo ọkàn rẹ, ati pẹlu gbogbo ẹ̀mí rẹ, ati pẹlu gbogbo agbára rẹ ati pẹlu gbogbo òye rẹ; sì fẹ́ràn ọmọnikeji rẹ bí ara rẹ.” Jesu sọ fún un pé, “O wí ire. Máa ṣe bẹ́ẹ̀, ìwọ yóo sì yè.” Ṣugbọn amòfin náà fẹ́ wẹ ara rẹ̀ mọ́. Ó wá bi Jesu pé, “Ta ni ọmọnikeji mi?” Jesu bá dá a lóhùn pé, “Ọkunrin kan ń ti Jerusalẹmu lọ sí Jẹriko, ni ó bá bọ́ sí ọwọ́ àwọn ọlọ́ṣà. Wọ́n gba aṣọ lára rẹ̀, wọ́n lù ú, wọ́n bá fi í sílẹ̀ nígbà tí ó fẹ́rẹ̀ kú tán. Alufaa kan tí ó ń bọ̀ ṣe kòńgẹ́ rẹ̀ ní ọ̀nà, ṣugbọn nígbà tí ó rí i, ó gba òdìkejì kọjá lọ. Bákan náà ni ọmọ Lefi kan. Nígbà tí òun náà dé ibẹ̀, tí ó rí i, ó gba òdìkejì kọjá lọ. Ṣugbọn ará Samaria kan tí ó ń gba ọ̀nà yìí kọjá lọ dé ọ̀dọ̀ ọkunrin náà. Nígbà tí ó rí i, àánú ṣe é. Ó bá lọ sọ́dọ̀ rẹ̀, ó fi òróró ati ọtí waini sí ojú ọgbẹ́ rẹ̀, ó sì fi aṣọ wé e. Ó gbé ọkunrin náà ka orí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ tí ó gùn. Ó gbé e lọ sí ilé èrò níbi tí ó ti ṣe ìtọ́jú rẹ̀. Nígbà tí ó di ọjọ́ keji, ó yọ owó fadaka meji jáde, ó fún olùtọ́jú ilé èrò, ó ní, ‘Ṣe ìtọ́jú ọkunrin yìí. Ohun tí o bá ná lé e lórí, n óo san án fún ọ nígbà tí mo bá pada dé.’ “Ninu àwọn mẹta yìí, ta ni o rò pé ó jẹ́ ọmọnikeji ẹni tí ó bọ́ sọ́wọ́ àwọn ọlọ́ṣà?” Amòfin náà dáhùn pé, “Ẹni tí ó ṣàánú fún un ni.” Jesu sọ fún un pé, “Ìwọ náà lọ ṣe bẹ́ẹ̀ gan-an.”
Luk 10:13-37 Bibeli Mimọ (YBCV)
Egbé ni fun iwọ, Korasini! Egbé ni fun iwọ, Betsaida! nitori ibaṣepe a ti ṣe iṣẹ agbara ti a ṣe ninu nyin, ni Tire on Sidoni, nwọn iba ti ronupiwada lailai, nwọn iba si joko ninu aṣọ ọ̀fọ ati ninu ẽru. Ṣugbọn yio san fun Tire on Sidoni nigba idajọ jù fun ẹnyin lọ. Ati iwọ, Kapernaumu, a o ha gbe ọ ga de oke ọrun? a o rẹ̀ ọ silẹ de ipo-oku. Ẹniti o ba gbọ́ ti nyin, o gbọ́ ti emi: ẹniti o ba si kọ̀ nyin, o kọ̀ mi; ẹniti o ba si kọ̀ mi, o kọ̀ ẹniti o rán mi. Awọn adọrin na si fi ayọ̀ pada, wipe, Oluwa, awọn ẹmi èṣu tilẹ foribalẹ fun wa li orukọ rẹ. O si wi fun wọn pe, Emi ri Satani ṣubu bi manamana lati ọrun wá. Kiyesi i, emi fun nyin li aṣẹ lati tẹ̀ ejò ati akẽkẽ mọlẹ, ati lori gbogbo agbara ọtá: kò si si ohunkan bi o ti wù ki o ṣe, ti yio pa-nyin-lara. Ṣugbọn ki ẹ máṣe yọ̀ si eyi, pe, awọn ẹmi nforibalẹ fun nyin; ṣugbọn ẹ kuku yọ̀, pe, a kọwe orukọ nyin li ọrun. Ni wakati kanna Jesu yọ̀ ninu Ẹmi Mimọ́ o si wipe, Mo dupẹ lọwọ rẹ, Baba, Oluwa ọrun on aiye, pe, iwọ pa nkan wọnyi mọ́ kuro lọdọ awọn ọlọ́gbọn ati amoye, iwọ si fi wọn hàn fun awọn ọmọ-ọwọ: bẹ̃ni, Baba, bẹ̃li o sá yẹ li oju rẹ. Ohun gbogbo li a fifun mi lati ọdọ Baba mi wá: kò si si ẹniti o mọ̀ ẹniti Ọmọ iṣe, bikoṣe Baba; ati ẹniti Baba iṣe, bikoṣe Ọmọ, ati ẹnikẹni ti o ba si wù Ọmọ lati fi i hàn fun. O si yipada si awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ li apakan, o ni, Ibukún ni fun ojú ti nri ohun ti ẹnyin nri: Nitori mo wi fun nyin, Woli ati ọba pipọ li o nfẹ lati ri ohun ti ẹnyin nri, nwọn kò si ri wọn, ati lati gbọ ohun ti ẹnyin ngbọ́, nwọn ko si gbọ́ wọn, Si kiyesi i, amofin kan dide, o ndán a wò, o ni, Olukọni, kili emi o ṣe ki emi ki o le jogún iyè ainipẹkun? O si bi i pe, Kili a kọ sinu iwe ofin? bi iwọ ti kà a? O si dahùn wipe, Ki iwọ ki o fi gbogbo àiya rẹ, ati gbogbo ọkàn rẹ, ati gbogbo agbara rẹ, ati gbogbo inu rẹ fẹ Oluwa Ọlọrun rẹ; ati ẹnikeji rẹ bi ara rẹ. O si wi fun u pe, Iwọ dahùn rere: ṣe eyi, iwọ o si yè. Ṣugbọn o nfẹ lati dá ara rẹ̀ lare, o wi fun Jesu pe, Tani ha si li ẹnikeji mi? Jesu si dahùn o wipe, Ọkunrin kan nti Jerusalemu sọkalẹ lọ si Jeriko, o si bọ si ọwọ́ awọn ọlọṣà, ti nwọn gbà a li aṣọ, nwọn ṣá a lọgbẹ, nwọn si fi i silẹ lọ li aipa li apatan. Ni alabapade, alufa kan si nsọkalẹ lọ lọna na: nigbati o si ri i, o kọja lọ niha keji. Bẹ̃na si ni ọmọ Lefi kan pẹlu, nigbati o de ibẹ̀, ti o si ri i, o kọja lọ niha keji. Ṣugbọn ara Samaria kan, bi o ti nrè àjo, o de ibi ti o gbé wà: nigbati o si ri i, ãnu ṣe e, O si tọ̀ ọ lọ, o si dì i lọgbẹ, o da oróro on ọti-waini si i, o si gbé e le ori ẹranko ti on tikalarẹ̀, o si mu u wá si ile-èro, o si nṣe itọju rẹ̀. Nigbati o si lọ ni ijọ keji, o fi owo idẹ meji fun olori ile-ero, o si wi fun u pe, Mã tọju rẹ̀; ohunkohun ti iwọ ba si ná kun u, nigbati mo ba pada de, emi ó san a fun ọ. Ninu awọn mẹtẹta wọnyi, tani iwọ rò pe iṣe ẹnikeji ẹniti o bọ si ọwọ́ awọn ọlọṣà? O si dahùn wipe, Ẹniti o ṣãnu fun u ni. Jesu si wi fun u pe, Lọ, ki iwọ ki o si ṣe bẹ̃ gẹgẹ.
Luk 10:13-37 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Ègbé ni fún ìwọ, Koraṣini! Ègbé ni fún ìwọ Betisaida! Nítorí ìbá ṣe pé a ti ṣe iṣẹ́ agbára tí a ṣe nínú yín, ní Tire àti Sidoni, wọn ìbá ti ronúpìwàdà lọ́jọ́ pípẹ́ sẹ́yìn, wọn ìbá sì jókòó nínú aṣọ ọ̀fọ̀ àti nínú eérú. Ṣùgbọ́n yóò sàn fún Tire àti Sidoni nígbà ìdájọ́ jù fún yín lọ. Àti ìwọ, Kapernaumu, a ó ha gbé ọ ga dé òkè ọ̀run? A ó rẹ̀ ọ́ sílẹ̀ dé isà òkú. “Ẹni tí ó bá gbọ́ tiyín, ó gbọ́ tèmi. Ẹni tí ó bá sì kọ̀ yín, ó kọ̀ mi. Ẹni tí ó bá sì kọ̀ mi, ó kọ ẹni tí ó rán mi.” Àwọn àádọ́rin náà sì fi ayọ̀ padà, wí pé, “Olúwa, àwọn ẹ̀mí èṣù tilẹ̀ foríbalẹ̀ fún wa ní orúkọ rẹ.” Ó sì wí fún wọn pé, “Èmí rí Satani ṣubú bí mọ̀nàmọ́ná láti ọ̀run wá. Kíyèsi i, èmí fún yín ní àṣẹ láti tẹ ejò àti àkéekèe mọ́lẹ̀, àti lórí gbogbo agbára ọ̀tá: kò sì ṣí ohun kan bí ó ti wù tí ó ṣe, tí yóò pa yín lára. Ṣùgbọ́n kí ẹ má ṣe yọ̀ nítorí èyí pé, àwọn ẹ̀mí ń foríbalẹ̀ fún yín; ṣùgbọ́n ẹ kúkú yọ̀, pé; a kọ̀wé orúkọ yín ní ọ̀run!” Ní wákàtí kan náà Jesu yọ̀ nínú Ẹ̀mí mímọ́ ó sì wí pé, “Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ, Baba, Olúwa ọ̀run àti ayé, pé, ìwọ pa nǹkan wọ̀nyí mọ́ kúrò lọ́dọ̀ àwọn ọlọ́gbọ́n àti amòye, ìwọ sì fi wọ́n hàn fún àwọn ọmọ ọwọ́: bẹ́ẹ̀ ni, Baba, bẹ́ẹ̀ ni ó sá à yẹ ní ojú rẹ. “Ohun gbogbo ni a ti fi fún mi láti ọ̀dọ̀ Baba mi; kò sì ṣí ẹni tí ó mọ ẹni tí ọmọ jẹ́, bí kò ṣe Baba; àti ẹnikẹ́ni tí ó bá sì wu ọmọ láti fi í hàn fún.” Ó sì yípadà sí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ní apá kan. Ó ní, “Ìbùkún ni fún ojú tí ń rí ohun tí ẹ̀yin ń rí. Nítorí mo wí fún yín, ọ̀pọ̀ àwọn wòlíì àti àwọn ọba ni ó ń fẹ́ láti rí ohun tí ẹ̀yin ń rí, wọn kò sì rí wọn, àti láti gbọ́ ohun tí ẹ̀yin ń gbọ́, wọn kò sì gbọ́ wọn.” Sì kíyèsi i amòfin kan dìde, ó ń dán an wò, ó ní, “Olùkọ́, kín ni èmi ó ṣe kí èmi lè jogún ìyè àìnípẹ̀kun?” Ó sì bi í pé, “Kí ni a kọ sínú ìwé òfin? Báwo ni ìwọ sì ti kà á?” Ó sì dáhùn wí pé, “ ‘Kí ìwọ fi gbogbo àyà rẹ, àti gbogbo ọkàn rẹ, àti gbogbo agbára rẹ, àti gbogbo inú rẹ fẹ́ Olúwa Ọlọ́run rẹ’; àti, ‘ẹnìkejì rẹ bí ara rẹ.’ ” Ó sì wí fún un pé, “Ìwọ́ dáhùn rere. Ṣe èyí, ìwọ ó sì yè.” Ṣùgbọ́n ó ń fẹ́ láti da ara rẹ̀ láre, ó wí fún Jesu wí pé, “Ta ha sì ni ẹnìkejì mi?” Jesu sì dáhùn ó wí pé, “Ọkùnrin kan ń ti Jerusalẹmu sọ̀kalẹ̀ lọ sí Jeriko, ó sì bọ́ sí ọwọ́ àwọn ọlọ́ṣà; wọ́n gbà á ní aṣọ, wọ́n sá a lọ́gbẹ́, wọ́n sì fi sílẹ̀ lọ ní àìpatán. Ní kòńgẹ́ àkókò yìí ni àlùfáà kan sì ń sọ̀kalẹ̀ lọ lọ́nà náà. Nígbà tí ó sì rí i ó kọjá lọ níhà kejì. Bẹ́ẹ̀ náà sì ni ọmọ Lefi kan pẹ̀lú, nígbà tí ó dé ibẹ̀, tí ó sì rí i, ó kọjá lọ níhà kejì. Ṣùgbọ́n ará Samaria kan, bí ó ti ń re àjò, ó dé ibi tí ó gbé wà; nígbà tí ó sì rí i, àánú ṣe é. Ó sì tọ̀ ọ́ lọ, ó sì di ọgbẹ́ rẹ̀, ó da òróró àti ọtí wáìnì sí i, ó sì gbé e lé orí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ti òun tìkára rẹ̀, ó sì mú un wá sí ilé èrò, a sì ń ṣe ìtọ́jú rẹ̀. Nígbà tí ó sì lọ ní ọjọ́ kejì, ó fi owó idẹ méjì fún olórí ilé èrò ó sì wí fún un pé, ‘Máa tọ́jú rẹ̀; ohunkóhun tí ìwọ bá sì ná kún un, nígbà tí mo bá padà dé, èmi ó san án fún ọ.’ “Nínú àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta wọ̀nyí, ta ni ìwọ rò pé ó jẹ́ ẹnìkejì ẹni tí ó bọ́ sí ọwọ́ àwọn ọlọ́ṣà?” Ó sì dáhùn wí pé, “Ẹni tí ó ṣàánú fún un ni.” Jesu sì wí fún un pé, “Lọ, kí o ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́!”