Luk 10:13-16
Luk 10:13-16 Bibeli Mimọ (YBCV)
Egbé ni fun iwọ, Korasini! Egbé ni fun iwọ, Betsaida! nitori ibaṣepe a ti ṣe iṣẹ agbara ti a ṣe ninu nyin, ni Tire on Sidoni, nwọn iba ti ronupiwada lailai, nwọn iba si joko ninu aṣọ ọ̀fọ ati ninu ẽru. Ṣugbọn yio san fun Tire on Sidoni nigba idajọ jù fun ẹnyin lọ. Ati iwọ, Kapernaumu, a o ha gbe ọ ga de oke ọrun? a o rẹ̀ ọ silẹ de ipo-oku. Ẹniti o ba gbọ́ ti nyin, o gbọ́ ti emi: ẹniti o ba si kọ̀ nyin, o kọ̀ mi; ẹniti o ba si kọ̀ mi, o kọ̀ ẹniti o rán mi.
Luk 10:13-16 Yoruba Bible (YCE)
“O gbé! Korasini. O gbé! Bẹtisaida. Nítorí bí ó bá jẹ́ pé ní Tire ati ní Sidoni ni a ti ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu tí a ṣe láàrin yín ni, wọn ìbá ti ronupiwada tipẹ́tipẹ́, wọn ìbá jókòó ninu eérú pẹlu aṣọ ọ̀fọ̀. Yóo sàn fún Tire ati fún Sidoni ní ọjọ́ ìdájọ́ jù fún yín lọ. Ìwọ Kapanaumu, o rò pé a óo gbé ọ ga dé ọ̀run ni? Rárá o! Ní ọ̀gbun jíjìn ni a óo sọ ọ́ sí! “Ẹni tí ó bá gbọ́ tiyín, ó gbọ́ tèmi. Ẹni tí ó bá kọ̀ yín èmi ni ó kọ̀. Ẹni tí ó bá sì wá kọ̀ mí, ó kọ ẹni tí ó fi iṣẹ́ rán mi.”
Luk 10:13-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Ègbé ni fún ìwọ, Koraṣini! Ègbé ni fún ìwọ Betisaida! Nítorí ìbá ṣe pé a ti ṣe iṣẹ́ agbára tí a ṣe nínú yín, ní Tire àti Sidoni, wọn ìbá ti ronúpìwàdà lọ́jọ́ pípẹ́ sẹ́yìn, wọn ìbá sì jókòó nínú aṣọ ọ̀fọ̀ àti nínú eérú. Ṣùgbọ́n yóò sàn fún Tire àti Sidoni nígbà ìdájọ́ jù fún yín lọ. Àti ìwọ, Kapernaumu, a ó ha gbé ọ ga dé òkè ọ̀run? A ó rẹ̀ ọ́ sílẹ̀ dé isà òkú. “Ẹni tí ó bá gbọ́ tiyín, ó gbọ́ tèmi. Ẹni tí ó bá sì kọ̀ yín, ó kọ̀ mi. Ẹni tí ó bá sì kọ̀ mi, ó kọ ẹni tí ó rán mi.”