Luk 10:1-12

Luk 10:1-12 Bibeli Mimọ (YBCV)

LẸHIN nkan wọnyi, Oluwa si yàn adọrin ọmọ-ẹhin miran pẹlu, o si rán wọn ni mejimeji lọ ṣaju rẹ̀, si gbogbo ilu ati ibi ti on tikararẹ̀ yio gbé de. O si wi fun wọn pe, Ikore pọ̀, ṣugbọn awọn alagbaṣe ko to nkan: nitorina ẹ bẹ̀ Oluwa ikore, ki o le rán awọn alagbaṣe sinu ikore rẹ̀. Ẹ mu ọ̀na nyin pọ̀n: sa wò o, emi rán nyin lọ bi ọdọ-agutan sãrin ikõkò. Ẹ máṣe mu asuwọn, ẹ máṣe mu apò, tabi bàta: ẹ má si ṣe kí ẹnikẹni li ọ̀na. Ni ilekile ti ẹnyin ba wọ̀, ki ẹ kọ́ wipe, Alafia fun ile yi. Bi ọmọ alafia ba si mbẹ nibẹ̀, alafia nyin yio bà le e: ṣugbọn bi kò ba si, yio tún pada sọdọ nyin. Ni ile kanna ni ki ẹnyin ki o si gbé, ki ẹ mã jẹ, ki ẹ si mã mu ohunkohun ti nwọn ba fifun nyin; nitori ọ̀ya alagbaṣe tọ́ si i. Ẹ maṣe ṣi lati ile de ile. Ati ni ilukilu ti ẹnyin ba wọ̀, ti nwọn ba si gbà nyin, ẹ jẹ ohunkohun ti a ba gbé kà iwaju nyin: Ẹ si mu awọn alaisan ti mbẹ ninu rẹ̀ larada, ki ẹ si wi fun wọn pe, Ijọba Ọlọrun kù dẹ̀dẹ si nyin. Ṣugbọn ni ilukilu ti ẹnyin ba si wọ̀, ti nwọn kò ba si gbà nyin, nigbati ẹnyin ba si jade si igboro ilu na, ki ẹnyin ki o si wipe, Ekuru iyekuru ilu nyin ti o kù si wa lara, a gbọn ọ silẹ fun nyin: ṣugbọn ẹ mọ̀ eyi pe, ijọba Ọlọrun kù dẹ̀dẹ si nyin. Ṣugbọn mo wi fun nyin, yio san fun Sodomu ni ijọ na, jù fun ilu na lọ.

Luk 10:1-12 Yoruba Bible (YCE)

Lẹ́yìn èyí, Oluwa yan àwọn mejilelaadọrin mìíràn, ó rán wọn ní meji-meji ṣiwaju rẹ̀ lọ sí gbogbo ìlú ati ibi tí òun náà fẹ́ dé. Ó sọ fún wọn pé, “Àwọn nǹkan tí ó tó kórè pọ̀ ninu oko, ṣugbọn àwọn òṣìṣẹ́ kò pọ̀ tó. Nítorí náà, ẹ bẹ Oluwa ìkórè kí ó rán àwọn alágbàṣe sí ibi ìkórè rẹ̀. Ẹ máa lọ. Mo ran yín lọ bí aguntan sí ààrin ìkookò. Ẹ má mú àpò owó lọ́wọ́, tabi àpò báárà. Ẹ má wọ bàtà. Bẹ́ẹ̀ ní kí ẹ má kí ẹnikẹ́ni ní ọ̀nà. Ilékílé tí ẹ bá wọ̀, ẹ kọ́kọ́ wí pé, ‘Alaafia fún ilé yìí.’ Bí ọmọ alaafia bá wà níbẹ̀, alaafia yín yóo máa wà níbẹ̀. Bí kò bá sí, alaafia yín yóo pada sọ́dọ̀ yín. Ninu ilé kan náà ni kí ẹ máa gbé. Ohun tí wọ́n bá gbé kalẹ̀ fun yín ni kí ẹ máa jẹ, kí ẹ sì máa mu. Owó iṣẹ́ alágbàṣe tọ́ sí i. Ẹ má máa lọ láti ilé dé ilé. Ìlúkílùú tí ẹ bá wọ̀, tí wọn bá gbà yín, ẹ máa jẹ ohun tí wọn bá gbé kalẹ̀ níwájú yín. Ẹ máa wo àwọn aláìsàn sàn. Kí ẹ sọ fún wọn pé, ‘Ìjọba Ọlọrun ti dé àrọ́wọ́tó yín.’ Ṣugbọn ìlúkílùú tí ẹ bá wọ̀ tí wọn kò bá gbà yín, ẹ jáde lọ sí títì ibẹ̀, kí ẹ sọ pé, ‘Erùpẹ̀ tí ó lẹ̀ mọ́ wa lẹ́sẹ̀ ninu ìlú yín, a gbọ̀n ọ́n kúrò kí ojú lè tì yín. Ṣugbọn kí ẹ mọ èyí pé ìjọba Ọlọrun wà ní àrọ́wọ́tó yín.’ Mo sọ fun yín pé yóo sàn fún Sodomu ní ọjọ́ ńlá náà jù fún ìlú náà lọ.

Luk 10:1-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, Olúwa sì yan àádọ́rin ọmọ-ẹ̀yìn mìíràn pẹ̀lú, ó sì rán wọn ní méjì méjì lọ ṣáájú rẹ̀, sí gbogbo ìlú àti ibi tí òun tìkára rẹ̀ yóò sì dé. Ó sì wí fún wọn pé, “Ìkórè pọ̀, ṣùgbọ́n àwọn alágbàṣe kò tó nǹkan, nítorí náà ẹ bẹ Olúwa ìkórè, kí ó lè rán àwọn alágbàṣe sínú ìkórè rẹ̀. Ẹ mú ọ̀nà yín pọ̀n: sá wò ó, èmi rán yín lọ bí ọ̀dọ́-àgùntàn sáàrín ìkookò. Ẹ má ṣe mú àpò, ẹ má ṣe mú àpamọ́wọ́, tàbí bàtà: ẹ má sì ṣe kí ẹnikẹ́ni lọ́nà. “Ní ilékílé tí ẹ̀yin bá wọ̀, kí ẹ kọ́ wí pé, ‘Àlàáfíà fún ilé yìí!’ Bí ọmọ àlàáfíà bá sì wà níbẹ̀, àlàáfíà yín yóò bà lé e: ṣùgbọ́n bí kò bá sí, yóò tún padà sọ́dọ̀ yín. Ẹ dúró sínú ilé náà, kí ẹ máa jẹ, kí ẹ sì máa mu ohunkóhun tí wọ́n bá fi fún yín; nítorí ọ̀yà alágbàṣe tọ́ sí i, Ẹ má ṣe lọ láti ilé dé ilé. “Ìlúkílùú tí ẹ̀yin bá wọ̀, tí wọ́n bá sì gbà yín, ẹ jẹ ohunkóhun tí a bá gbé ka iwájú yín: Ẹ sì mú àwọn aláìsàn tí ń bẹ nínú rẹ̀ láradá, kí ẹ sì wí fún wọn pé, ‘Ìjọba Ọlọ́run kù sí dẹ̀dẹ̀ sí yín!’ Ṣùgbọ́n ní ìlúkílùú tí ẹ̀yin bá sì wọ̀, tí wọn kò bá sì gbà yín, nígbà tí ẹ̀yin bá sì jáde ní ìgboro ìlú náà, kí ẹ̀yin sì wí pé, ‘Eruku ìlú yín tí ó kù sí wa lẹ́sẹ̀, a gbọ̀n ọ́n sílẹ̀ fún yín! Ṣùgbọ́n ẹ mọ èyí pé, ìjọba Ọlọ́run kù sí dẹ̀dẹ̀.’ Ṣùgbọ́n mo wí fún yín, yóò sàn fún Sodomu ní ọjọ́ náà, ju fún ìlú náà lọ.