Lef 4:32-35
Lef 4:32-35 Bibeli Mimọ (YBCV)
Bi o ba si mú ọdọ-agutan kan wá fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ, ki o si mú u wá, abo alailabùku. Ki o si fi ọwọ́ rẹ̀ lé ori ẹbọ ẹ̀ṣẹ na, ki o si pa a fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ ni ibi ti nwọn gbé npa ẹbọ sisun. Ki alufa ki o si fi iká rẹ̀ mú ninu ẹ̀jẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ na, ki o si fi i sara iwo pẹpẹ ẹbọsisun, ki o si dà gbogbo ẹ̀jẹ rẹ̀ si isalẹ pẹpẹ: Ki o si mú gbogbo ọrá rẹ̀ kuro, bi a ti imú ọrá ọdọ-agutan kuro ninu ẹbọ ọrẹ-ẹbọ alafia; ki alufa ki o si sun wọn lori pẹpẹ, gẹgẹ bi ẹbọ ti a fi iná ṣe si OLUWA: ki alufa ki o si ṣètutu fun ẹ̀ṣẹ rẹ̀ ti o ti ṣẹ̀, a o si dari rẹ̀ jì i.
Lef 4:32-35 Yoruba Bible (YCE)
“Bí ó bá jẹ́ pé, aguntan ni ó mú wá fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, ó níláti jẹ́ abo aguntan tí kò ní àbààwọ́n. Kí ó gbé ọwọ́ lórí ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ yìí, kí ó sì pa á fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ níbi tí wọ́n ti ń pa ẹran tí wọ́n bá fẹ́ fi rú ẹbọ sísun. Lẹ́yìn náà alufaa yóo yán ẹ̀jẹ̀ ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ náà sí ara ìwo pẹpẹ ẹbọ sísun, yóo wá da ẹ̀jẹ̀ yòókù sídìí pẹpẹ. Yóo yọ́ gbogbo ọ̀rá rẹ̀, bí wọ́n ti ń yọ́ ọ̀rá ẹran tí wọ́n bá fi rú ẹbọ alaafia. Alufaa yóo kó o lé orí ẹbọ náà, yóo sì fi iná sun ún lórí pẹpẹ fún OLUWA. Alufaa yóo ṣe ètùtù fún un nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ti dá, OLUWA yóo sì dáríjì í.
Lef 4:32-35 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“ ‘Bí ó bá mú ọ̀dọ́-àgùntàn wá gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, kí ó mú abo tí kò lábùkù. Kí ó gbé ọwọ́ rẹ̀ lé e lórí, kí ó sì pa á fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ níbi tí wọ́n ti ń pa ẹran ẹbọ sísun. Àlùfáà yóò sì ti ìka rẹ̀ bọ inú ẹ̀jẹ̀ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ náà, yóò sì fi sí orí ìwo pẹpẹ ẹbọ sísun, yóò sì da ìyókù ẹ̀jẹ̀ náà sí ìsàlẹ̀ pẹpẹ. Kí ó yọ gbogbo ọ̀rá rẹ̀ bó ti yọ ọ̀rá lára ọ̀dọ́-àgùntàn ọrẹ àlàáfíà, àlùfáà yóò sì sun ún ní orí pẹpẹ, lórí ọrẹ tí a fi iná sun sí OLúWA. Báyìí ni àlùfáà yóò ṣe ètùtù fún ẹni náà, nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tí ó sẹ̀, a ó sì dáríjì í.