Lefitiku 4:32-35

Lefitiku 4:32-35 YCB

“ ‘Bí ó bá mú ọ̀dọ́-àgùntàn wá gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, kí ó mú abo tí kò lábùkù. Kí ó gbé ọwọ́ rẹ̀ lé e lórí, kí ó sì pa á fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ níbi tí wọ́n ti ń pa ẹran ẹbọ sísun. Àlùfáà yóò sì ti ìka rẹ̀ bọ inú ẹ̀jẹ̀ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ náà, yóò sì fi sí orí ìwo pẹpẹ ẹbọ sísun, yóò sì da ìyókù ẹ̀jẹ̀ náà sí ìsàlẹ̀ pẹpẹ. Kí ó yọ gbogbo ọ̀rá rẹ̀ bó ti yọ ọ̀rá lára ọ̀dọ́-àgùntàn ọrẹ àlàáfíà, àlùfáà yóò sì sun ún ní orí pẹpẹ, lórí ọrẹ tí a fi iná sun sí OLúWA. Báyìí ni àlùfáà yóò ṣe ètùtù fún ẹni náà, nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tí ó sẹ̀, a ó sì dáríjì í.