Lef 16:20-34
Lef 16:20-34 Yoruba Bible (YCE)
“Lẹ́yìn ìgbà tí ó bá ti parí ṣíṣe ètùtù fún ibi mímọ́ náà, ati fún Àgọ́ Àjọ náà, ati pẹpẹ náà, yóo fa ààyè ewúrẹ́ náà kalẹ̀. Yóo gbé ọwọ́ rẹ̀ mejeeji lé e lórí, yóo jẹ́wọ́ gbogbo àìṣedéédé ati ìrékọjá ati ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ọmọ Israẹli lórí rẹ̀, yóo sì kó wọn lé e lórí, yóo fà á lé ẹnìkan tí ó ti múra sílẹ̀ lọ́wọ́, láti fà á lọ sinu aṣálẹ̀. Òbúkọ náà yóo sì fi orí rẹ̀ ru gbogbo àìṣedéédé wọn, títí tí ẹni náà yóo fi fà á dé ibi tí eniyan kì í gbé, ibẹ̀ ni yóo ti sọ ọ́ sílẹ̀ kí ó lè wọ inú aṣálẹ̀ lọ. “Aaroni yóo pada wá sinu Àgọ́ Àjọ, yóo bọ́ àwọn aṣọ funfun tí ó wọ̀ kí ó tó wọ inú ibi mímọ́ lọ, yóo sì fi wọ́n sílẹ̀ níbẹ̀. Yóo wẹ̀ ní ibi mímọ́, yóo kó àwọn aṣọ tirẹ̀ wọ̀, yóo sì jáde. Lẹ́yìn náà yóo rú ẹbọ sísun tirẹ̀ ati ẹbọ sísun ti àwọn eniyan náà, yóo sì ṣe ètùtù fún ara rẹ̀ ati fún àwọn eniyan náà. Yóo sun ọ̀rá ẹran ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ lórí pẹpẹ náà. Ẹni tí ó fa ewúrẹ́ náà tọ Asaseli lọ ninu aṣálẹ̀ yóo fọ aṣọ rẹ̀, yóo sì wẹ̀, lẹ́yìn náà, ó lè wọ ibùdó. Lẹ́yìn náà, wọn yóo gbé òkú akọ mààlúù ati ti òbúkọ tí wọ́n fi rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, ati ẹ̀jẹ̀ wọn tí wọ́n gbé wọ ibi mímọ́ lọ láti fi ṣe ètùtù, wọn yóo rù wọ́n jáde kúrò ní ibùdó, wọn yóo sì dáná sun ati awọ, ati ara ẹran ati nǹkan inú wọn. Ẹni tí ó bá lọ sun wọ́n, yóo fọ aṣọ rẹ̀, yóo sì wẹ̀, lẹ́yìn náà, ó lè wọ ibùdó wá. “Kí ó jẹ́ ìlànà fun yín títí lae pé, ní ọjọ́ kẹwaa oṣù keje, ati onílé ati àlejò yín, ẹ gbọdọ̀ gbààwẹ̀, ẹ kò sì gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ kankan. Nítorí pé, ní ọjọ́ náà ni wọn yóo máa ṣe ètùtù fun yín, tí yóo sọ yín di mímọ́ kúrò ninu gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ yín, kí ẹ lè jẹ́ mímọ́ níwájú OLUWA. Ọjọ́ ìsinmi tí ó lọ́wọ̀ ni ó jẹ́ fun yín, ẹ sì gbọdọ̀ gbààwẹ̀; ìlànà ni èyí jẹ́ fun yín títí lae. Alufaa tí wọ́n bá ta òróró sí lórí, tí wọ́n sì yà sí mímọ́ gẹ́gẹ́ bí alufaa àgbà ní ipò baba rẹ̀ ni kí ó máa ṣe ètùtù, kí ó sì máa wọ aṣọ mímọ́ náà. Yóo ṣe ètùtù fún Àgọ́ mímọ́ náà, ati Àgọ́ Àjọ, ati pẹpẹ náà, kí ó sì ṣe ètùtù fún àwọn alufaa pẹlu ati ìjọ eniyan náà. Èyí yóo jẹ́ ìlànà ayérayé fun yín, kí wọ́n lè máa ṣe ètùtù fún àwọn ọmọ Israẹli ní ẹ̀ẹ̀kan lọ́dún, nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn.” Mose sì ṣe gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí OLUWA pa fún un.
Lef 16:20-34 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Lẹ́yìn ti Aaroni ti parí ṣíṣe ètùtù ti ibi mímọ́ jùlọ, ti àgọ́ ìpàdé àti ti pẹpẹ: òun yóò sì mú ààyè ewúrẹ́ wá. Aaroni yóò sì gbé ọwọ́ rẹ̀ méjèèjì lé orí ààyè ewúrẹ́ náà, yóò sì jẹ́wọ́ gbogbo ìwà búburú àti ìṣọ̀tẹ̀ àwọn ara Israẹli lé e lórí: gbogbo ìrékọjá wọn àti ẹ̀ṣẹ̀ wọn ni yóò sì gbé ka orí ewúrẹ́ náà. Yóò sì rán an lọ sí ijù láti ọwọ́ ẹni tí a yàn fún iṣẹ́ náà. Ewúrẹ́ náà yóò sì ru gbogbo àìṣedéédéé wọn lọ sí ilẹ̀ tí ènìyàn kò gbé. Òun yóò sì jọ̀wọ́ ewúrẹ́ náà lọ́wọ́ lọ sínú ijù. Aaroni yóò sì padà wá sí ibi àgọ́ ìpàdé, yóò sì bọ́ aṣọ ọ̀gbọ̀ wọ̀n-ọn-nì sílẹ̀, tí ó wọ̀ nígbà tí ó lọ sí ibi mímọ́ jùlọ, yóò sì fi wọ́n sílẹ̀ níbẹ̀ Yóò sì fi omi wẹ ara rẹ̀ ní ibi mímọ́ kan: yóò sì wọ aṣọ rẹ̀ yóò sì wá ṣí iwájú: yóò sì rú ẹbọ sísun ti ara rẹ̀ àti ẹbọ sísun ti àwọn ènìyàn láti ṣe ètùtù fún ara rẹ̀ àti fún àwọn ènìyàn: Òun yóò sì sun ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ náà lórí pẹpẹ. Ẹni tí ó tú ewúrẹ́ ìpààrọ̀ náà sílẹ̀ yóò sì fọ aṣọ rẹ̀: yóò sì wẹ ara rẹ̀ nínú omi: lẹ́yìn èyí ó lè wá sí ibùdó. Ọ̀dọ́ akọ màlúù àti ewúrẹ́ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ tí a ti mú ẹ̀jẹ̀ wọn wá sí ibi mímọ́ jùlọ ni kí a gbe jáde kúrò ní ibùdó. Awọ wọn ni a ó fi iná sun bákan náà. Ẹni tí ó sun wọ́n yóò sì fọ aṣọ rẹ̀: yóò sì wẹ ara rẹ̀: lẹ́yìn èyí ni ó tó le wọ ibùdó. Èyí ni yóò jẹ́ ìlànà títí láé fún un yín: pé ní ọjọ́ kẹwàá oṣù keje ni ẹ gbọdọ̀ ṣẹ́ ara yín: kí ẹ má ṣe ṣe iṣẹ́ kankan, yálà onílé tàbí àlejò tí ó ń gbé pẹ̀lú yín. Torí pé ní ọjọ́ yìí ni àlùfáà yóò ṣe ètùtù fún yín láti sọ yín di mímọ́: kí ẹ̀yin bá à le mọ́ níwájú OLúWA yín kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ yín gbogbo. Ọjọ́ yìí yóò jẹ́ ọjọ́ ìsinmi pátápátá fún un yín: ẹ̀yin yóò sì ṣẹ́ ara yín: Èyí yóò sì jẹ́ ìlànà títí láé. Àlùfáà náà tí a ti fi òróró yàn tí a sì ti sọ di mímọ́ láti máa ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ ní ilé ìsìn ní ipò baba rẹ̀: òun ni kí ó ṣe ètùtù: yóò sì wọ aṣọ funfun gbòò àní aṣọ mímọ́ náà: òun yóò sì ṣe ètùtù. Yóò sì ṣe ètùtù fún àgọ́ ìpàdé àti fún pẹpẹ: yóò sì ṣe ètùtù fún àlùfáà àti fún gbogbo àgbájọpọ̀ àwọn ènìyàn náà. “Èyí ni yóò jẹ́ ìlànà ayérayé fún yín: láti máa ṣe ètùtù fún àwọn ará Israẹli fún gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wọn lẹ́ẹ̀kan lọ́dún.” Ó sì ṣe gẹ́gẹ́ bí OLúWA ti pàṣẹ fún Mose.
Lef 16:20-34 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nigbati o ba si pari ati ṣètutu si ibi mimọ́, ati si agọ́ ajọ, ati pẹpẹ, ki o mú ewurẹ alãye nì wá: Ki Aaroni ki o si fi ọwọ́ rẹ̀ mejeji lé ori ewurẹ alãye na, ki o si jẹwọ gbogbo aiṣedede awọn ọmọ Israeli sori rẹ̀, ati gbogbo irekọja wọn, ani gbogbo ẹ̀ṣẹ wọn; ki o si fi wọn lé ori ewurẹ na, ki o si ti ọwọ́ ẹniti o yẹ rán a lọ si ijù: Ki ewurẹ na ki o si rù gbogbo aiṣedede wọn lori rẹ̀ lọ si ilẹ ti a kò tẹ̀dó: ki o si jọwọ ewurẹ na lọwọ lọ sinu ijù. Ki Aaroni ki o si wá sinu agọ́ ajọ, ki o si bọ́ aṣọ ọ̀gbọ wọnni silẹ, ti o múwọ̀ nigbati o wọ̀ ibi mimọ́ lọ, ki o si fi wọn sibẹ̀: Ki o si fi omi wẹ̀ ara rẹ̀ ni ibi mimọ́ kan, ki o si mú aṣọ rẹ̀ wọ̀, ki o si jade wá, ki o si ru ẹbọ sisun rẹ̀, ati ẹbọ sisun awọn enia, ki o si ṣètutu fun ara rẹ̀ ati fun awọn enia. Ọrá ẹbọ ẹ̀ṣẹ nì ni ki o si sun lori pẹpẹ. Ati ẹniti o jọwọ ewurẹ nì lọwọ lọ fun Asaseli, ki o fọ̀ aṣọ rẹ̀, ki o si wẹ̀ ara rẹ̀ ninu omi, lẹhin eyinì ni ki o wá si ibudó. Ati akọmalu nì fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ, ati ewurẹ nì fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ, ẹ̀jẹ eyiti a múwa lati fi ṣètutu ni ibi mimọ́, ni ki ẹnikan ki o mú jade lọ sẹhin ode ibudó; ki nwọn ki o si sun awọ wọn, ati ẹran wọn, ati igbẹ́ wọn ninu iná. Ati ẹniti o sun wọn ni ki o fọ̀ aṣọ rẹ̀, ki o si wẹ̀ ara rẹ̀ ninu omi, lẹhin eyinì ni ki o wá si ibudó. Eyi ni ki o si ma ṣe ìlana lailai fun nyin: pe li oṣù keje, li ọjọ́ kẹwa oṣù, ni ki ẹnyin ki o pọ́n ọkàn nyin loju, ki ẹnyin má si ṣe iṣẹ kan rára, iba ṣe ibilẹ, tabi alejò ti nṣe atipo lãrin nyin: Nitoripe li ọjọ́ na li a o ṣètutu fun nyin, lati wẹ̀ nyin mọ́; ki ẹnyin ki o le mọ́ kuro ninu gbogbo ẹ̀ṣẹ nyin niwaju OLUWA. On o jẹ́ ọjọ́ isimi fun nyin, ki ẹnyin ki o si pọ́n ọkàn nyin loju, nipa ìlana titilai. Ati alufa na, ẹniti a o ta oróro si li ori, ati ẹniti a o yàsimimọ́ si iṣẹ-alufa dipò baba rẹ̀, on ni ki o ṣètutu na, ki o si mú aṣọ ọ̀gbọ wọnni wọ̀, ani aṣọ mimọ́ wọnni: Ki o si ṣètutu si ibi mimọ́, ki o si ṣètutu si agọ́ ajọ, ati si pẹpẹ; ki o si ṣètutu fun awọn alufa, ati fun gbogbo ijọ enia. Ki eyi ki o si jẹ́ ìlana titilai fun nyin, lati ṣètutu fun awọn ọmọ Israeli nitori ẹ̀ṣẹ wọn gbogbo lẹ̃kan li ọdún. O si ṣe bi OLUWA ti fi aṣẹ fun Mose.