Ẹk. Jer 5:15-22
Ẹk. Jer 5:15-22 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ayọ̀ ọkàn wa ti dá; a yi ijo wa pada si ọ̀fọ. Ade ṣubu kuro li ori wa: ègbe ni fun wa, nitori awa ti ṣẹ̀. Nitori eyi li ọkàn wa rẹ̀wẹsi; nitori nkan wọnyi oju wa di baibai. Nitori oke Sioni, ti dahoro, awọn kọ̀lọkọlọ nrin lori rẹ̀. Iwọ, Oluwa, li o wà lailai; itẹ́ rẹ lati iran de iran! Ẽṣe ti iwọ fi gbagbe wa lailai, ti o si kọ̀ wa silẹ li ọjọ pipẹ? Oluwa, yi wa pada sọdọ rẹ, awa o si yipada; sọ ọjọ wa di ọtun gẹgẹ bi ti igbãni. Tabi iwọ ha ti kọ̀ wa silẹ patapata, tobẹ̃ ti iwọ si binu si wa gidigidi?
Ẹk. Jer 5:15-22 Yoruba Bible (YCE)
Inú wa kò dùn mọ́; ijó wa ti yipada, ó ti di ọ̀fọ̀. Adé ti ṣíbọ́ lórí wa! A gbé! Nítorí pé a ti dẹ́ṣẹ̀, nítorí náà, ọkàn wa ti rẹ̀wẹ̀sì; ojú wa sì ti di bàìbàì. Nítorí òkè Sioni tí ó di ahoro; tí àwọn ọ̀fàfà sì ń ké lórí rẹ̀. Ṣugbọn ìwọ OLUWA ni ó jọba títí ayé, ìtẹ́ rẹ sì wà láti ìrandíran. Kí ló dé tí o fi gbàgbé wa patapata? Tí o sì kọ̀ wá sílẹ̀ fún ìgbà pípẹ́? Mú wa pada sọ́dọ̀ ara rẹ, OLUWA, kí á lè pada sí ipò wa. Mú àwọn ọjọ́ àtijọ́ wa pada. Ṣé o ti kọ̀ wá sílẹ̀ patapata ni? Àbí o sì tún ń bínú sí wa, inú rẹ kò tíì rọ̀?
Ẹk. Jer 5:15-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ayọ̀ ti ṣáko ní ọkàn wa; ọ̀fọ̀ sì ti dúró bí ijó fún wa. Adé ti ṣí kúrò ní orí wa ègbé ni fún wa, nítorí a ti ṣẹ̀. Nítorí èyí, àárẹ̀ mú ọkàn wa, nítorí èyí, ojú wa sì ṣú. Fún òkè Sioni tí ó ti di ahoro lórí rẹ̀ àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ sì ń rìn kiri. Ìwọ, OLúWA, jẹ ọba títí láé; ìjọba rẹ dúró láti ìran kan dé ìran mìíràn. Kí ló dé tí o ń gbàgbé wa ní gbogbo ìgbà? Kí ló dé tí o fi kọ̀ wá sílẹ̀ fún ọjọ́ pípẹ́? Mú wa padà sí ọ̀dọ̀ rẹ, OLúWA, kí àwa kí ó le padà; mú ọjọ́ wa di tuntun bí ìgbàanì Àyàfi tí o bá ti kọ̀ wá sílẹ̀ pátápátá tí ìbínú rẹ sí wa sì kọjá ìwọ̀n.