Ẹk. Jer 5

5
Adura fún Àánú
1RANTI, Oluwa, ohun ti o de sori wa; rò ki o si wò ẹ̀gan wa!
2A fi ogún wa le awọn alejo lọwọ, ile wa fun awọn ajeji.
3Awa jẹ alaini obi, baba kò si, awọn iyá wa dabi opó.
4Awa ti fi owo mu omi wa; a nta igi wa fun wa.
5Awọn ti nlepa wa sunmọ ọrùn wa: ãrẹ̀ mu wa, awa kò si ni isimi.
6Awa ti fi ọwọ wa fun awọn ara Egipti, ati fun ara Assiria, lati fi onjẹ tẹ́ wa lọrùn.
7Awọn baba wa ti ṣẹ̀, nwọn kò si sí; awa si nrù aiṣedede wọn.
8Awọn ẹrú ti jọba lori wa: ẹnikan kò si gbà wa kuro li ọwọ wọn.
9Ninu ewu ẹmi wa li awa nlọ mu onjẹ wa, nitori idà ti aginju.
10Àwọ wa pọ́n gẹgẹ bi àro nitori gbigbona ìyan na.
11Nwọn tẹ́ awọn obinrin li ogo ni Sioni, awọn wundia ni ilu Juda.
12A so awọn ijoye rọ̀ nipa ọwọ wọn: a kò buyin fun oju awọn àgbagba.
13Awọn ọdọmọkunrin ru ọlọ, ãrẹ̀ mu awọn ọmọde labẹ ẹrù-igi.
14Awọn àgbagba dasẹ kuro li ẹnu-bode, awọn ọdọmọkunrin kuro ninu orin wọn.
15Ayọ̀ ọkàn wa ti dá; a yi ijo wa pada si ọ̀fọ.
16Ade ṣubu kuro li ori wa: ègbe ni fun wa, nitori awa ti ṣẹ̀.
17Nitori eyi li ọkàn wa rẹ̀wẹsi; nitori nkan wọnyi oju wa di baibai.
18Nitori oke Sioni, ti dahoro, awọn kọ̀lọkọlọ nrin lori rẹ̀.
19Iwọ, Oluwa, li o wà lailai; itẹ́ rẹ lati iran de iran!
20Ẽṣe ti iwọ fi gbagbe wa lailai, ti o si kọ̀ wa silẹ li ọjọ pipẹ?
21Oluwa, yi wa pada sọdọ rẹ, awa o si yipada; sọ ọjọ wa di ọtun gẹgẹ bi ti igbãni.
22Tabi iwọ ha ti kọ̀ wa silẹ patapata, tobẹ̃ ti iwọ si binu si wa gidigidi?

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Ẹk. Jer 5: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa