Ẹk. Jer 5:1-22

Ẹk. Jer 5:1-22 Bibeli Mimọ (YBCV)

RANTI, Oluwa, ohun ti o de sori wa; rò ki o si wò ẹ̀gan wa! A fi ogún wa le awọn alejo lọwọ, ile wa fun awọn ajeji. Awa jẹ alaini obi, baba kò si, awọn iyá wa dabi opó. Awa ti fi owo mu omi wa; a nta igi wa fun wa. Awọn ti nlepa wa sunmọ ọrùn wa: ãrẹ̀ mu wa, awa kò si ni isimi. Awa ti fi ọwọ wa fun awọn ara Egipti, ati fun ara Assiria, lati fi onjẹ tẹ́ wa lọrùn. Awọn baba wa ti ṣẹ̀, nwọn kò si sí; awa si nrù aiṣedede wọn. Awọn ẹrú ti jọba lori wa: ẹnikan kò si gbà wa kuro li ọwọ wọn. Ninu ewu ẹmi wa li awa nlọ mu onjẹ wa, nitori idà ti aginju. Àwọ wa pọ́n gẹgẹ bi àro nitori gbigbona ìyan na. Nwọn tẹ́ awọn obinrin li ogo ni Sioni, awọn wundia ni ilu Juda. A so awọn ijoye rọ̀ nipa ọwọ wọn: a kò buyin fun oju awọn àgbagba. Awọn ọdọmọkunrin ru ọlọ, ãrẹ̀ mu awọn ọmọde labẹ ẹrù-igi. Awọn àgbagba dasẹ kuro li ẹnu-bode, awọn ọdọmọkunrin kuro ninu orin wọn. Ayọ̀ ọkàn wa ti dá; a yi ijo wa pada si ọ̀fọ. Ade ṣubu kuro li ori wa: ègbe ni fun wa, nitori awa ti ṣẹ̀. Nitori eyi li ọkàn wa rẹ̀wẹsi; nitori nkan wọnyi oju wa di baibai. Nitori oke Sioni, ti dahoro, awọn kọ̀lọkọlọ nrin lori rẹ̀. Iwọ, Oluwa, li o wà lailai; itẹ́ rẹ lati iran de iran! Ẽṣe ti iwọ fi gbagbe wa lailai, ti o si kọ̀ wa silẹ li ọjọ pipẹ? Oluwa, yi wa pada sọdọ rẹ, awa o si yipada; sọ ọjọ wa di ọtun gẹgẹ bi ti igbãni. Tabi iwọ ha ti kọ̀ wa silẹ patapata, tobẹ̃ ti iwọ si binu si wa gidigidi?

Ẹk. Jer 5:1-22 Yoruba Bible (YCE)

OLUWA, ranti ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí wa, Ṣe akiyesi ẹ̀sín wa. Àwọn ilẹ̀ àjogúnbá ẹni ẹlẹ́ni, ilé wa sì ti di ti àwọn àjèjì. A ti di aláìníbaba, ọmọ òrukàn àwọn ìyá wa kò yàtọ̀ sí opó. Owó ni a fi ń ra omi tí à ń mu, rírà ni a sì ń ra igi tí a fi ń dáná. Àwọn tí wọn ń lépa wa ti bá wa, ó ti rẹ̀ wá, a kò sì ní ìsinmi. A ti fa ara wa kalẹ̀ fún àwọn ará Ijipti ati àwọn ará Asiria nítorí oúnjẹ tí a óo jẹ. Àwọn baba wa ni wọ́n dẹ́ṣẹ̀, àwọn sì ti kú, ṣugbọn àwa ni à ń jìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Àwọn ẹrú ní ń jọba lé wa lórí, kò sì sí ẹni tí yóo gbà wá lọ́wọ́ wọn. Ẹ̀mí wa ni à ń fi wéwu, kí á tó rí oúnjẹ, nítorí ogun tí ó wà ninu aṣálẹ̀. Awọ ara wa gbóná bí iná ààrò, nítorí ìyàn tí ó mú lọpọlọpọ. Tipátipá ni wọ́n fi ń bá àwọn obinrin lòpọ̀ ní Sioni, ati àwọn ọmọbinrin tí wọn kò tíì mọ ọkunrin ní Juda. Wọ́n fi okùn so ọwọ́ àwọn olórí rọ̀, wọn kò sì bọ̀wọ̀ fún àwọn àgbààgbà. Wọ́n fi ipá mú àwọn ọdọmọkunrin pé kí wọn máa lọ ọlọ, àwọn ọmọde ru igi títí àárẹ̀ mú wọn! Àwọn àgbààgbà ti sá kúrò ní ẹnubodè; àwọn ọdọmọkunrin sì ti dákẹ́ orin kíkọ. Inú wa kò dùn mọ́; ijó wa ti yipada, ó ti di ọ̀fọ̀. Adé ti ṣíbọ́ lórí wa! A gbé! Nítorí pé a ti dẹ́ṣẹ̀, nítorí náà, ọkàn wa ti rẹ̀wẹ̀sì; ojú wa sì ti di bàìbàì. Nítorí òkè Sioni tí ó di ahoro; tí àwọn ọ̀fàfà sì ń ké lórí rẹ̀. Ṣugbọn ìwọ OLUWA ni ó jọba títí ayé, ìtẹ́ rẹ sì wà láti ìrandíran. Kí ló dé tí o fi gbàgbé wa patapata? Tí o sì kọ̀ wá sílẹ̀ fún ìgbà pípẹ́? Mú wa pada sọ́dọ̀ ara rẹ, OLUWA, kí á lè pada sí ipò wa. Mú àwọn ọjọ́ àtijọ́ wa pada. Ṣé o ti kọ̀ wá sílẹ̀ patapata ni? Àbí o sì tún ń bínú sí wa, inú rẹ kò tíì rọ̀?

Ẹk. Jer 5:1-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Rántí, OLúWA, ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí wa; wò ó, kí o sì rí ìtìjú wa. Àwọn ohun ìní wa ti di ti àlejò, ilé wa ti di ti àjèjì. Àwa ti di aláìní òbí àti aláìní baba, àwọn ìyá wa ti di opó. A gbọdọ̀ ra omi tí à ń mu; igi wa di títà fún wa. Àwọn tí ó ń lé wa súnmọ́ wa; àárẹ̀ mú wa àwa kò sì rí ìsinmi. Àwa jọ̀wọ́ ara wa fún Ejibiti àti Asiria láti rí oúnjẹ tó tó jẹ. Àwọn baba wa ti ṣẹ̀, wọn kò sì ṣí mọ́, àwa sì ń ru ìjìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Àwọn ẹrú ń jẹ ọba lórí wa, kò sì ṣí ẹni tí yóò gbà wá lọ́wọ́ wọn. Àwa ń rí oúnjẹ wa nínú ewu ẹ̀mí wa nítorí idà tí ó wà ní aginjù. Ẹran-ara wa gbóná bí ààrò, ebi sì yó wa bí àárẹ̀. Wọ́n ti fipá bá àwọn obìnrin wa lòpọ̀ ní Sioni, àti àwọn wúńdíá ti o wa ní ìlú Juda. Àwọn ọmọ ọbakùnrin ti di síso sókè ní ọwọ́ wọn; kò sí ìbọ̀wọ̀ fún àgbàgbà mọ́. Àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin wa ru òkúta; àwọn ọmọkùnrin sì ń ṣàárẹ̀ lábẹ́ ẹrù igi. Àwọn àgbàgbà ti lọ kúrò ní ẹnu-bodè ìlú; àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin sì dákẹ́ orin wọn Ayọ̀ ti ṣáko ní ọkàn wa; ọ̀fọ̀ sì ti dúró bí ijó fún wa. Adé ti ṣí kúrò ní orí wa ègbé ni fún wa, nítorí a ti ṣẹ̀. Nítorí èyí, àárẹ̀ mú ọkàn wa, nítorí èyí, ojú wa sì ṣú. Fún òkè Sioni tí ó ti di ahoro lórí rẹ̀ àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ sì ń rìn kiri. Ìwọ, OLúWA, jẹ ọba títí láé; ìjọba rẹ dúró láti ìran kan dé ìran mìíràn. Kí ló dé tí o ń gbàgbé wa ní gbogbo ìgbà? Kí ló dé tí o fi kọ̀ wá sílẹ̀ fún ọjọ́ pípẹ́? Mú wa padà sí ọ̀dọ̀ rẹ, OLúWA, kí àwa kí ó le padà; mú ọjọ́ wa di tuntun bí ìgbàanì Àyàfi tí o bá ti kọ̀ wá sílẹ̀ pátápátá tí ìbínú rẹ sí wa sì kọjá ìwọ̀n.