Ẹk. Jer 3:22-25
Ẹk. Jer 3:22-25 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ãnu Oluwa ni, ti awa kò parun tan, nitori irọnu-ãnu rẹ kò li opin. Ọtun ni li orowurọ; titobi ni otitọ rẹ. Oluwa ni ipin mi, bẹ̃li ọkàn mi wi; nitorina ni emi ṣe reti ninu rẹ̀. Oluwa ṣe rere fun gbogbo ẹniti o duro dè e, fun ọkàn ti o ṣafẹri rẹ̀.
Ẹk. Jer 3:22-25 Yoruba Bible (YCE)
Nítorí pé Ìfẹ́ OLUWA tí kì í yẹ̀ kò nípẹ̀kun, àánú rẹ̀ kò sì lópin; ọ̀tun ni wọ́n láràárọ̀, òtítọ́ rẹ̀ pọ̀. Ọkàn mi wí pé, “OLUWA ni ìpín mi, nítorí náà lọ́dọ̀ rẹ̀ ni ìrètí mi wà.” OLUWA a máa ṣe oore fún àwọn tí wọn dúró dè é, tí wọn sì ń wá ojurere rẹ̀.
Ẹk. Jer 3:22-25 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nítorí ìfẹ́ OLúWA tí ó lágbára ni àwa kò fi ṣègbé, nítorí ti àánú rẹ kì í kùnà. Wọ́n jẹ́ ọ̀tún ní àárọ̀; títóbi ni òdodo rẹ̀. Mo wí fún ara mi, ìpín mi ni OLúWA; nítorí náà èmi yóò dúró dè ọ́. Dídára ni OLúWA fún àwọn tí ó ní ìrètí nínú rẹ̀, sí àwọn tí ó ń wá a.