Ẹk. Jer 3:1-26

Ẹk. Jer 3:1-26 Bibeli Mimọ (YBCV)

EMI ni ọkunrin na ti o ti ri wàhala nipa ọpa ibinu rẹ̀. O ti fà mi, o si mu mi wá sinu òkunkun, kì si iṣe sinu imọlẹ. Lõtọ, o yi ọwọ rẹ̀ pada si mi siwaju ati siwaju li ọjọ gbogbo. O ti sọ ẹran-ara mi ati àwọ mi di ogbó, o ti fọ́ egungun mi. O ti mọdi tì mi, o fi orõrò ati ãrẹ̀ yi mi ka. O ti fi mi si ibi òkunkun, bi awọn ti o ti kú pẹ. O ti sọgba yi mi ka, ti emi kò le jade; o ti ṣe ẹ̀wọn mi wuwo. Bi emi ti kigbe pẹlu, ti emi si npariwo, o sé adura mi mọ. O ti fi okuta gbigbẹ sọgba yi ọ̀na mi ka, o ti yi ipa ọ̀na mi po. On jẹ bi ẹranko beari ti o ba dè mi, bi kiniun ni ibi ìkọkọ. O ti mu mi ṣina li ọ̀na mi, o si fà mi ya pẹrẹpẹrẹ: o ti sọ mi di ahoro. O ti fà ọrun rẹ̀, o si fi mi ṣe itasi fun ọfa rẹ̀. O ti mu ki ọfà apó rẹ̀ wọ inu-ẹdọ mi lọ. Emi jẹ ẹni ẹsin fun gbogbo enia mi; orin wọn ni gbogbo ọjọ. O ti fi ìkoro mu mi yo, o ti mu mi mu omi wahala. O ti fi ọta ṣẹ́ ehín mi, o tẹ̀ mi mọlẹ ninu ẽru. Iwọ si ti mu ọkàn mi jina réré si alafia; emi gbagbe rere. Emi si wipe, Agbara mi ati ireti mi ṣègbe kuro lọdọ Oluwa. Ranti wahala mi ati inilara mi, ani ìkoro ati orõro. Lõtọ, nigbati ọkàn mi nṣe iranti wọn, o si tẹriba ninu mi. Eyi ni emi o rò li ọkàn mi, nitorina emi o ma reti. Ãnu Oluwa ni, ti awa kò parun tan, nitori irọnu-ãnu rẹ kò li opin. Ọtun ni li orowurọ; titobi ni otitọ rẹ. Oluwa ni ipin mi, bẹ̃li ọkàn mi wi; nitorina ni emi ṣe reti ninu rẹ̀. Oluwa ṣe rere fun gbogbo ẹniti o duro dè e, fun ọkàn ti o ṣafẹri rẹ̀. O dara ti a ba mã reti ni idakẹjẹ fun igbala Oluwa.

Ẹk. Jer 3:1-26 Yoruba Bible (YCE)

Èmi ni mo mọ bí eniyan tií rí ìpọ́njú, tí mo mọ bí Ọlọrun tií fi ibinu na eniyan ní pàṣán. Ó lé mi wọ inú òkùnkùn biribiri. Dájúdájú, ó ti dojú kọ mí, ó sì bá mi jà léraléra tọ̀sán-tòru. Ó ti jẹ́ kí n rù kan egungun, ó sì ti fọ́ egungun mi. Ó dótì mí, ó fi ìbànújẹ́ ati ìṣẹ́ yí mi káàkiri. Ó fi mí sinu òkùnkùn bí òkú tí ó ti kú láti ọjọ́ pípẹ́. Ó mọ odi yí mi ká, ó sì fi ẹ̀wọ̀n wúwo dè mí, kí n má baà lè sálọ. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ké pè é fún ìrànlọ́wọ́, sibẹsibẹ kò gbọ́ adura mi. Ó to òkúta gbígbẹ́ dí ọ̀nà mi, ó mú kí ọ̀nà mí wọ́. Ó ba dè mí bí ẹranko ìjàkùmọ̀, ó lúgọ bíi kinniun, Ó wọ́ mi kúrò lójú ọ̀nà mi, ó fà mí ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ, ó sì ti sọ mí di alailẹnikan. Ó kẹ́ ọfà, ó fa ọrun rẹ̀, ó sì fi mí ṣe ohun ìtafàsí. Ó mú gbogbo ọfà tí ó wà ninu apó rẹ̀ ó ta wọ́n mọ́ mi lọ́kàn. Mo wá di ẹni yẹ̀yẹ́ lọ́dọ̀ gbogbo eniyan, ẹni tí wọ́n fi ń kọrin tọ̀sán-tòru. Ó mú kí ọkàn mi kún fún ìbànújẹ́, ó fún mi ní iwọ mu ní àmuyó. Ó fẹnu mi gbolẹ̀, títí yangí fi ká mi léyín; ó gún mi mọ́lẹ̀ ninu eruku Ọkàn mi kò ní alaafia, mo ti gbàgbé ohun tí ń jẹ́ ayọ̀. Nítorí náà, mo wí pé, “Ògo mi ti tán, ati gbogbo ohun tí mò ń retí lọ́dọ̀ OLUWA.” Ranti ìyà ati ìbànújẹ́ mi, ati ìrora ọkàn mi! Mò ń ranti nígbà gbogbo, ọkàn mi sì ń rẹ̀wẹ̀sì. Ṣugbọn mo tún ń ranti nǹkankan, mo sì ní ìrètí. Nítorí pé Ìfẹ́ OLUWA tí kì í yẹ̀ kò nípẹ̀kun, àánú rẹ̀ kò sì lópin; ọ̀tun ni wọ́n láràárọ̀, òtítọ́ rẹ̀ pọ̀. Ọkàn mi wí pé, “OLUWA ni ìpín mi, nítorí náà lọ́dọ̀ rẹ̀ ni ìrètí mi wà.” OLUWA a máa ṣe oore fún àwọn tí wọn dúró dè é, tí wọn sì ń wá ojurere rẹ̀. Ó dára kí eniyan dúró jẹ́ẹ́, de ìgbàlà OLUWA.

Ẹk. Jer 3:1-26 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Èmi ni ọkùnrin tí ó rí ìpọ́njú pẹ̀lú ọ̀pá ìbínú rẹ. Ó ti lé mi jáde ó sì mú mi rìn nínú òkùnkùn ju ti ìmọ́lẹ̀; Nítòótọ́, ó ti yí ọwọ́ padà sí mi síwájú àti síwájú sí i ní gbogbo ọjọ́. Ó jẹ́ kí àwọ̀ mi àti ẹran-ara mi gbó ó sì tún ṣẹ́ egungun mi. Ó ti fi mí sí ìgbèkùn, ó sì ti yí mi ká pẹ̀lú ìkorò àti làálàá. Ó mú mi gbé nínú òkùnkùn, bí ti àwọn tó ti kú fún ìgbà pípẹ́. Ó ti tì mí mọ́ ilé, nítorí náà n kò le è sálọ; ó ti fi ẹ̀wọ̀n mú mi mọ́lẹ̀. Pàápàá nígbà tí mo ké fún ìrànlọ́wọ́, ó kọ àdúrà mi. Ó fi ògiri òkúta dí ọ̀nà mi; ó sì mú ọ̀nà mi wọ́. Bí i beari tí ó dùbúlẹ̀, bí i kìnnìún tí ó sápamọ́. Ó wọ́ mi kúrò ní ọ̀nà, ó tẹ̀ mí mọ́lẹ̀ ó fi mi sílẹ̀ láìsí ìrànlọ́wọ́. Ó fa ọfà rẹ̀ yọ ó sì fi mí ṣe ohun ìtafàsí. Ó fa ọkàn mí ya pẹ̀lú ọfà nínú àkọ̀ rẹ̀. Mo di ẹni yẹ̀yẹ́ láàrín àwọn ènìyàn mi; wọn yẹ̀yẹ́ mi pẹ̀lú orin ní gbogbo ọjọ́. Ó ti kún mi pẹ̀lú ewé kíkorò àti ìdààmú bí omi. Ó ti fi òkúta kán eyín mi; ó ti tẹ̀ mí mọ́lẹ̀ nínú eruku. Mo ti jìnnà sí àlàáfíà; mo ti gbàgbé ohun tí àṣeyege ń ṣe. Nítorí náà mo wí pé, “Ògo mi ti lọ àti ìrètí mi nínú OLúWA.” Mo ṣe ìrántí ìpọ́njú àti ìdààmú mi, ìkorò àti ìbànújẹ́. Mo ṣèrántí wọn, ọkàn mi sì gbọgbẹ́ nínú mi. Síbẹ̀, èyí ni mo ní ní ọkàn àti nítorí náà ní mo nírètí. Nítorí ìfẹ́ OLúWA tí ó lágbára ni àwa kò fi ṣègbé, nítorí ti àánú rẹ kì í kùnà. Wọ́n jẹ́ ọ̀tún ní àárọ̀; títóbi ni òdodo rẹ̀. Mo wí fún ara mi, ìpín mi ni OLúWA; nítorí náà èmi yóò dúró dè ọ́. Dídára ni OLúWA fún àwọn tí ó ní ìrètí nínú rẹ̀, sí àwọn tí ó ń wá a. Ó dára kí a ní sùúrù fún ìgbàlà OLúWA.