Joṣ 6:6-14

Joṣ 6:6-14 Yoruba Bible (YCE)

Joṣua, ọmọ Nuni, bá pe àwọn alufaa, ó sọ fún wọn pé, “Ẹ gbé Àpótí Majẹmu, kí meje ninu yín sì mú fèrè ogun tí wọ́n fi ìwo àgbò ṣe lọ́wọ́ níwájú Àpótí Majẹmu OLUWA.” Ó sọ fún àwọn eniyan náà pé, “Ẹ máa tẹ̀síwájú, ẹ rìn yípo ìlú náà kí àwọn ọmọ ogun ṣáájú Àpótí Majẹmu OLUWA.” Gẹ́gẹ́ bí Joṣua ti pàṣẹ fún àwọn eniyan náà, àwọn alufaa meje mú fèrè ogun tí wọ́n fi ìwo àgbò ṣe lọ́wọ́ níwájú OLUWA, wọ́n ṣáájú, wọ́n ń fọn fèrè ogun wọn; àwọn tí wọ́n gbé Àpótí Majẹmu OLUWA sì tẹ̀lé wọn. Àwọn kan ninu àwọn ọmọ ogun ṣáájú àwọn alufaa tí wọn ń fọn fèrè ogun, àwọn kan sì tẹ̀lé Àpótí Majẹmu. Àwọn tí wọn ń fọn fèrè ogun sì ń fọn ọ́n lemọ́lemọ́. Joṣua pàṣẹ fún àwọn eniyan náà pé, “Ẹ kò gbọdọ̀ pariwo, bẹ́ẹ̀ ni ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ gbọ́ ohùn yín. Ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ sọ̀rọ̀ rárá títí di ọjọ́ tí n óo sọ pé kí ẹ hó, nígbà náà ni ẹ óo tó hó.” Bẹ́ẹ̀ ni ó mú kí wọn gbé Àpótí Majẹmu OLUWA yí ìlú náà po lẹ́ẹ̀kan, nígbà tí ó di alẹ́, wọ́n pada sinu àgọ́ wọn, wọ́n sì sùn sibẹ. Joṣua dìde ní òwúrọ̀ kutukutu, àwọn alufaa gbé Àpótí Majẹmu OLUWA. Àwọn alufaa meje tí wọ́n mú fèrè ogun tí wọ́n fi ìwo àgbò ṣe lọ́wọ́ níwájú Àpótí Majẹmu OLUWA kọjá siwaju, wọ́n sì ń fọn fèrè ogun wọn lemọ́lemọ́. Àwọn kan ninu àwọn ọmọ ogun wà níwájú wọn, àwọn kan sì tẹ̀lé Àpótí Majẹmu OLUWA. Àwọn tí ń fọn fèrè ogun ń fọn ọ́n lemọ́lemọ́. Ní ọjọ́ keji, wọ́n yípo ìlú náà lẹ́ẹ̀kan, wọn sì pada sinu àgọ́ wọn. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe fún ọjọ́ mẹfa.

Joṣ 6:6-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Bẹ́ẹ̀ ni Joṣua ọmọ Nuni pe àwọn àlùfáà ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ gbé àpótí ẹ̀rí OLúWA náà kí àwọn àlùfáà méje tí ó ru fèrè ìwo wà ní iwájú u rẹ̀.” Ó sì pàṣẹ fún àwọn ènìyàn náà pé, “Ẹ lọ, kí ẹ sì yí ìlú náà ká pẹ̀lú àwọn olùṣọ́ tí ó hámọ́ra kọjá ní iwájú àpótí ẹ̀rí OLúWA.” Nígbà tí Joṣua ti bá àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀ tán, àwọn àlùfáà méje tí wọ́n gbé fèrè méje ní iwájú OLúWA kọjá sí iwájú, wọ́n sì fọn fèrè wọn, àpótí ẹ̀rí OLúWA sì tẹ̀lé wọn. Àwọn olùṣọ tí ó hámọ́ra sì lọ níwájú àwọn àlùfáà tí ń fọn fèrè, olùṣọ́ ẹ̀yìn sì tẹ̀lé àpótí ẹ̀rí náà. Ní gbogbo àsìkò yìí fèrè sì ń dún. Ṣùgbọ́n Joṣua tí pàṣẹ fún àwọn ènìyàn pé, “Ẹ kò gbọdọ̀ kígbe ogun, ẹ kò gbọdọ̀ gbé ohùn yín sókè, ẹ má ṣe sọ ọ̀rọ̀ kan títí ọjọ́ tí èmi yóò sọ fún un yín pé kí ẹ hó. Nígbà náà ni ẹ̀yin yóò sì hó!” Bẹ́ẹ̀ ni ó mú kí àpótí ẹ̀rí OLúWA yí ìlú náà ká, ó sì yí i ká lẹ́ẹ̀kan. Nígbà náà ni àwọn ènìyàn náà padà sí ibùdó, wọ́n sì gbé ibẹ̀ fún alẹ́ náà. Joṣua sì dìde ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, àwọn àlùfáà sì gbé àpótí ẹ̀rí OLúWA. Àwọn àlùfáà méje tí ó gbé ìpè ìwo àgbò méje ń lọ níwájú àpótí ẹ̀rí OLúWA, wọ́n sì ń fọ́n àwọn ìpè: àwọn tí ó hámọ́ra ogun ń lọ níwájú u wọn; àwọn ọmọ tó wà lẹ́yìn sì ń tọ àpótí ẹ̀rí OLúWA lẹ́yìn, àwọn àlùfáà sì ń fọn ìpè bí wọ́n ti ń lọ. Ní ọjọ́ kejì, wọ́n yí ìlú náà ká lẹ́ẹ̀kan wọ́n sì padà sí ibùdó. Wọ́n sì ṣe èyí fún ọjọ́ mẹ́fà.

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa