Joṣ 6:24-27
Joṣ 6:24-27 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nwọn si fi iná kun ilu na ati ohun gbogbo ti mbẹ ninu rẹ̀; kìki fadakà, ati wurà, ati ohunèlo idẹ ati irin, ni nwọn fi sinu iṣura ile OLUWA. Joṣua si gbà Rahabu panṣaga là, ati ara ile baba rẹ̀, ati ohun gbogbo ti o ní; o si joko lãrin Israeli titi di oni-oloni; nitoriti o pa awọn onṣẹ mọ́ ti Joṣua rán lọ ṣamí Jeriko. Joṣua si gégun li akokò na wipe, Egún ni fun ọkunrin na niwaju OLUWA ti yio dide, ti yio si kọ ilu Jeriko yi: pẹlu ikú akọ́bi rẹ̀ ni yio fi pilẹ rẹ̀, ati pẹlu ikú abikẹhin rẹ̀ ni yio fi gbé ilẹkun ibode rẹ̀ ró. Bẹ̃ni OLUWA wà pẹlu Joṣua; okikí rẹ̀ si kàn ká gbogbo ilẹ na.
Joṣ 6:24-27 Yoruba Bible (YCE)
Wọ́n dáná sun ìlú náà ati gbogbo nǹkan tí ó wà ninu rẹ̀, àfi fadaka ati wúrà, ati àwọn ohun èlò idẹ, ati ti irin, ni wọ́n kó lọ sinu ilé ìṣúra OLUWA. Ṣugbọn Joṣua dá Rahabu aṣẹ́wó sí, ati ilé baba rẹ̀, ati gbogbo àwọn eniyan rẹ̀, wọ́n sì ń gbé ààrin àwọn ọmọ Israẹli títí di òní yìí; nítorí pé, Rahabu ni ó gbé àwọn amí tí Joṣua rán lọ wo ìlú Jẹriko pamọ́. Joṣua bá gégùn-ún nígbà náà pé, “Ẹni ìfibú OLUWA ni ẹnikẹ́ni tí ó bá dìde láti tún ìlú Jẹriko kọ́. Àkọ́bí ẹni tí ó bá fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ lélẹ̀ yóo kú, àbíkẹ́yìn rẹ̀ yóo kú nígbà tí ó bá gbé ìlẹ̀kùn ibodè rẹ̀ ró.” OLUWA wà pẹlu Joṣua, òkìkí rẹ̀ sì kàn ní gbogbo ilẹ̀ náà.
Joṣ 6:24-27 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà náà ni wọ́n sun gbogbo ìlú náà àti gbogbo ohun tí ó wà nínú u rẹ̀, ṣùgbọ́n wọ́n fi fàdákà, wúrà ohun èlò idẹ àti irin sínú ìṣúra ilé OLúWA. Ṣùgbọ́n Joṣua dá Rahabu panṣágà pẹ̀lú gbogbo ìdílé e rẹ̀ àti gbogbo ẹni tí í ṣe tirẹ̀ sí nítorí pé, ó pa àwọn ọkùnrin tí Joṣua rán gẹ́gẹ́ bí ayọ́lẹ̀wò sí Jeriko mọ́. Ó sì ń gbé láàrín ará Israẹli títí di òní yìí. Ní àkókò náà Joṣua sì búra pé; “Ègún ni fún ẹni náà níwájú OLúWA tí yóò dìde, tí yóò sì tún ìlú Jeriko kọ́: “Pẹ̀lú ikú àkọ́bí ọmọ rẹ̀ ni yóò fi pilẹ̀ rẹ̀; ikú àbíkẹ́yìn rẹ̀ ní yóò fi gbé ìlẹ̀kùn bodè rẹ̀ ró.” Bẹ́ẹ̀ ni OLúWA wà pẹ̀lú Joṣua; òkìkí rẹ̀ sì kàn ká gbogbo ilẹ̀ náà.