Joṣ 6:12-14
Joṣ 6:12-14 Bibeli Mimọ (YBCV)
Joṣua si dide ni kùtukutu owurọ̀, awọn alufa si gbé apoti OLUWA. Awọn alufa meje ti o gbé ipè jubeli meje niwaju apoti OLUWA nlọ titi, nwọn si nfọn ipè wọnni: awọn ti o hamọra-ogun nlọ niwaju wọn; ogun-ẹhin si ntọ̀ apoti OLUWA lẹhin, awọn alufa si nfọn ipè bi nwọn ti nlọ. Li ọjọ́ keji nwọn yi ilu na ká lẹ̃kan, nwọn si pada si ibudó: bẹ̃ni nwọn ṣe ni ijọ́ mẹfa.
Joṣ 6:12-14 Yoruba Bible (YCE)
Joṣua dìde ní òwúrọ̀ kutukutu, àwọn alufaa gbé Àpótí Majẹmu OLUWA. Àwọn alufaa meje tí wọ́n mú fèrè ogun tí wọ́n fi ìwo àgbò ṣe lọ́wọ́ níwájú Àpótí Majẹmu OLUWA kọjá siwaju, wọ́n sì ń fọn fèrè ogun wọn lemọ́lemọ́. Àwọn kan ninu àwọn ọmọ ogun wà níwájú wọn, àwọn kan sì tẹ̀lé Àpótí Majẹmu OLUWA. Àwọn tí ń fọn fèrè ogun ń fọn ọ́n lemọ́lemọ́. Ní ọjọ́ keji, wọ́n yípo ìlú náà lẹ́ẹ̀kan, wọn sì pada sinu àgọ́ wọn. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe fún ọjọ́ mẹfa.
Joṣ 6:12-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Joṣua sì dìde ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, àwọn àlùfáà sì gbé àpótí ẹ̀rí OLúWA. Àwọn àlùfáà méje tí ó gbé ìpè ìwo àgbò méje ń lọ níwájú àpótí ẹ̀rí OLúWA, wọ́n sì ń fọ́n àwọn ìpè: àwọn tí ó hámọ́ra ogun ń lọ níwájú u wọn; àwọn ọmọ tó wà lẹ́yìn sì ń tọ àpótí ẹ̀rí OLúWA lẹ́yìn, àwọn àlùfáà sì ń fọn ìpè bí wọ́n ti ń lọ. Ní ọjọ́ kejì, wọ́n yí ìlú náà ká lẹ́ẹ̀kan wọ́n sì padà sí ibùdó. Wọ́n sì ṣe èyí fún ọjọ́ mẹ́fà.