Joṣ 6:1-21

Joṣ 6:1-21 Bibeli Mimọ (YBCV)

(NJẸ a há Jeriko mọ́ gága nitori awọn ọmọ Israeli: ẹnikẹni kò jade, ẹnikẹni kò si wọle.) OLUWA si wi fun Joṣua pe, Wò o, mo ti fi Jeriko lé ọ lọwọ, ati ọba rẹ̀, ati awọn alagbara akọni. Ẹnyin o si ká ilu na mọ́, gbogbo ẹnyin ologun, ẹnyin o si yi ilu na ká lẹ̃kan. Bayi ni iwọ o ṣe ni ijọ́ mẹfa. Alufa meje yio gbé ipè jubeli meje niwaju apoti na: ni ijọ́ keje ẹnyin o si yi ilu na ká lẹ̃meje, awọn alufa yio si fọn ipè wọnni. Yio si ṣe, nigbati nwọn ba fọn ipè jubeli kikan, nigbati ẹnyin ba si gbọ́ iró ipè na, gbogbo awọn enia yio si hó kũ; odi ilu na yio si wó lulẹ, bẹrẹ, awọn enia yio si gòke lọ tàra, olukuluku niwaju rẹ̀. Joṣua ọmọ Nuni si pè awọn alufa, o si wi fun wọn pe, Ẹ gbé apoti majẹmu na, ki alufa meje ki o gbé ipè jubeli meje nì niwaju apoti OLUWA. O si wi fun awọn enia pe, Ẹ kọja, ki ẹ si yi ilu na ká, ki awọn ti o hamọra ki o si kọja niwaju apoti OLUWA. O si ṣe, nigbati Joṣua wi fun awọn enia tán, awọn alufa meje ti o gbé ipè jubeli meje, kọja niwaju OLUWA nwọn si fọn ipè wọnni: apoti majẹmu OLUWA si tẹle wọn. Awọn ti o hamọra si lọ niwaju awọn alufa, ti nfọn ipè, ogun-ẹhin si ntọ̀ apoti lẹhin, awọn alufa nlọ nwọn si nfọn ipè. Joṣua si paṣẹ fun awọn enia wipe, Ẹ kò gbọdọ hó bẹ̃li ẹ kò gbọdọ pariwo, bẹ̃li ọ̀rọ kan kò gbọdọ jade li ẹnu nyin, titi ọjọ́ ti emi o wi fun nyin pe, ẹ hó; nigbana li ẹnyin o hó. Bẹ̃li o mu ki apoti OLUWA ki o yi ilu na ká, o yi i ká lẹ̃kan: nwọn si lọ si ibudó, nwọn si wọ̀ ni ibudó. Joṣua si dide ni kùtukutu owurọ̀, awọn alufa si gbé apoti OLUWA. Awọn alufa meje ti o gbé ipè jubeli meje niwaju apoti OLUWA nlọ titi, nwọn si nfọn ipè wọnni: awọn ti o hamọra-ogun nlọ niwaju wọn; ogun-ẹhin si ntọ̀ apoti OLUWA lẹhin, awọn alufa si nfọn ipè bi nwọn ti nlọ. Li ọjọ́ keji nwọn yi ilu na ká lẹ̃kan, nwọn si pada si ibudó: bẹ̃ni nwọn ṣe ni ijọ́ mẹfa. O si ṣe ni ijọ́ keje, nwọn dide ni kùtukutu li afẹmọjumọ́, nwọn si yi ilu na ká gẹgẹ bi ti iṣaju lẹ̃meje: li ọjọ́ na nikanṣoṣo ni nwọn yi ilu na ká lẹ̃meje. O si ṣe ni ìgba keje, nigbati awọn alufa fọn ipè, ni Joṣua wi fun awọn enia pe, Ẹ hó; nitoriti OLUWA ti fun nyin ni ilu na. Ilu na yio si jẹ́ ìyasọtọ si OLUWA, on ati gbogbo ohun ti mbẹ ninu rẹ̀: kìki Rahabu panṣaga ni yio là, on ati gbogbo awọn ti mbẹ ni ile pẹlu rẹ̀, nitoriti o pa awọn onṣẹ ti a rán mọ́. Ati ẹnyin, bi o ti wù ki o ri, ẹ pa ara nyin mọ́ kuro ninu ohun ìyasọtọ, ki ẹ má ba yà a sọ̀tọ tán ki ẹ si mú ninu ohun ìyasọtọ na; ẹnyin a si sọ ibudó Israeli di ifibu, ẹnyin a si mu iyọnu bá a. Ṣugbọn gbogbo fadakà, ati wurà, ati ohunèlo idẹ ati ti irin, mimọ́ ni fun OLUWA: nwọn o wá sinu iṣura OLUWA. Bẹ̃li awọn enia na hó, nigbati awọn alufa fọn ipè: o si ṣe, nigbati awọn enia gbọ́ iró ipè, ti awọn enia si hó kũ, odi na wólulẹ bẹrẹ, bẹ̃li awọn enia wọ̀ inu ilu na lọ, olukuluku tàra niwaju rẹ̀, nwọn si kó ilu na. Nwọn si fi oju idà pa gbogbo ohun ti o wà ni ilu na run, ati ọkunrin ati obinrin, ati ewe ati àgba, ati akọ-mãlu, ati agutan, ati kẹtẹkẹtẹ.

Joṣ 6:1-21 Yoruba Bible (YCE)

Wọ́n ti ìlẹ̀kùn odi Jẹriko ninu ati lóde, nítorí àwọn ọmọ Israẹli. Ẹnikẹ́ni kò lè jáde, bẹ́ẹ̀ ni ẹnikẹ́ni kò lè wọlé. OLUWA sọ fún Joṣua pé, “Wò ó! Mo ti fi Jẹriko lé ọ lọ́wọ́ ati ọba wọn ati àwọn akikanju wọn. Ìwọ ati gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ yóo rìn yípo ìlú náà lẹ́ẹ̀kan lojumọ fún ọjọ́ mẹfa. Kí àwọn alufaa meje mú fèrè ogun kọ̀ọ̀kan tí wọ́n fi ìwo àgbò ṣe lọ́wọ́ níwájú Àpótí Majẹmu. Ní ọjọ́ keje ẹ óo yípo ìlú náà nígbà meje, àwọn alufaa yóo máa fọn fèrè ogun wọn. Nígbà tí wọ́n bá fọn fèrè ogun náà gidigidi, tí ẹ sì gbọ́ ìró rẹ̀, kí gbogbo àwọn eniyan hó yèè! Ògiri ìlú náà yóo sì wó. Kí olukuluku àwọn ọmọ ogun wọ inú ìlú náà lọ tààrà.” Joṣua, ọmọ Nuni, bá pe àwọn alufaa, ó sọ fún wọn pé, “Ẹ gbé Àpótí Majẹmu, kí meje ninu yín sì mú fèrè ogun tí wọ́n fi ìwo àgbò ṣe lọ́wọ́ níwájú Àpótí Majẹmu OLUWA.” Ó sọ fún àwọn eniyan náà pé, “Ẹ máa tẹ̀síwájú, ẹ rìn yípo ìlú náà kí àwọn ọmọ ogun ṣáájú Àpótí Majẹmu OLUWA.” Gẹ́gẹ́ bí Joṣua ti pàṣẹ fún àwọn eniyan náà, àwọn alufaa meje mú fèrè ogun tí wọ́n fi ìwo àgbò ṣe lọ́wọ́ níwájú OLUWA, wọ́n ṣáájú, wọ́n ń fọn fèrè ogun wọn; àwọn tí wọ́n gbé Àpótí Majẹmu OLUWA sì tẹ̀lé wọn. Àwọn kan ninu àwọn ọmọ ogun ṣáájú àwọn alufaa tí wọn ń fọn fèrè ogun, àwọn kan sì tẹ̀lé Àpótí Majẹmu. Àwọn tí wọn ń fọn fèrè ogun sì ń fọn ọ́n lemọ́lemọ́. Joṣua pàṣẹ fún àwọn eniyan náà pé, “Ẹ kò gbọdọ̀ pariwo, bẹ́ẹ̀ ni ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ gbọ́ ohùn yín. Ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ sọ̀rọ̀ rárá títí di ọjọ́ tí n óo sọ pé kí ẹ hó, nígbà náà ni ẹ óo tó hó.” Bẹ́ẹ̀ ni ó mú kí wọn gbé Àpótí Majẹmu OLUWA yí ìlú náà po lẹ́ẹ̀kan, nígbà tí ó di alẹ́, wọ́n pada sinu àgọ́ wọn, wọ́n sì sùn sibẹ. Joṣua dìde ní òwúrọ̀ kutukutu, àwọn alufaa gbé Àpótí Majẹmu OLUWA. Àwọn alufaa meje tí wọ́n mú fèrè ogun tí wọ́n fi ìwo àgbò ṣe lọ́wọ́ níwájú Àpótí Majẹmu OLUWA kọjá siwaju, wọ́n sì ń fọn fèrè ogun wọn lemọ́lemọ́. Àwọn kan ninu àwọn ọmọ ogun wà níwájú wọn, àwọn kan sì tẹ̀lé Àpótí Majẹmu OLUWA. Àwọn tí ń fọn fèrè ogun ń fọn ọ́n lemọ́lemọ́. Ní ọjọ́ keji, wọ́n yípo ìlú náà lẹ́ẹ̀kan, wọn sì pada sinu àgọ́ wọn. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe fún ọjọ́ mẹfa. Ní ọjọ́ keje, wọ́n gbéra ní òwúrọ̀ kutukutu, wọ́n yípo ìlú náà bí wọ́n ti máa ń ṣe, nígbà meje. Ọjọ́ keje yìí nìkan ṣoṣo ni wọ́n yípo rẹ̀ lẹẹmeje. Nígbà tí ó di ẹẹkeje, lẹ́yìn tí àwọn alufaa fọn fèrè wọn, Joṣua pàṣẹ fún àwọn eniyan náà pé, “Ẹ hó yèè! Nítorí OLUWA ti fi ìlú yìí le yín lọ́wọ́. OLUWA ti yà á sọ́tọ̀ fún ìparun, ati gbogbo ohun tí ó wà ninu rẹ̀, àfi Rahabu, aṣẹ́wó, ati àwọn tí wọ́n wà ninu ilé pẹlu rẹ̀, ni yóo wà láàyè; nítorí òun ni ó gbé àwọn amí tí a rán pamọ́. Ẹ yẹra fún ohunkohun tí OLUWA ti yà sọ́tọ̀ fún ìparun, kí ẹ má baà di ẹni ègún nípa mímú ohun tí OLUWA ti yà sọ́tọ̀, kí ẹ má baà sọ àgọ́ Israẹli di ohun ìparun, kí ẹ sì kó ìyọnu bá a. Ṣugbọn gbogbo fadaka ati wúrà ati àwọn ohun èlò idẹ ati ti irin jẹ́ ohun ìyàsọ́tọ̀ fún OLUWA, inú ilé ìṣúra OLUWA ni a óo kó wọn sí.” Àwọn alufaa fọn fèrè ogun, bí àwọn eniyan ti gbọ́ ìró fèrè, gbogbo wọn hó yèè! Odi ìlú náà sì wó lulẹ̀. Gbogbo àwọn ọmọ ogun bá rọ́ wọ ààrin ìlú, wọ́n sì gba ìlú náà. Wọ́n run gbogbo àwọn ará ìlú náà patapata: atọkunrin, atobinrin, àtọmọdé, àtàgbà, àtakọ mààlúù, ataguntan, ati kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́; gbogbo wọn ni wọ́n fi idà parun.

Joṣ 6:1-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Wàyí o, a ti há Jeriko mọ́lé gágá nítorí àwọn ọmọ Israẹli, ẹnikẹ́ni kò jáde, ẹnikẹ́ni kò sì wọlé. Nígbà náà ni OLúWA wí fún Joṣua pé, “Wò ó, mo ti fi Jeriko lé ọ lọ́wọ́ pẹ̀lú ọba rẹ̀ àti àwọn jagunjagun rẹ̀. Ẹ wọ́de ogun yí ìlú náà ká lẹ́ẹ̀kan pẹ̀lú gbogbo àwọn jagunjagun. Ẹ ṣe èyí fún ọjọ́ mẹ́fà. Jẹ́ kí àwọn àlùfáà méje gbé fèrè ìwo àgbò ní iwájú àpótí ẹ̀rí. Ní ọjọ́ keje, Ẹ wọ́de ogun yí ìlú náà ká ní ìgbà méje, pẹ̀lú àwọn àlùfáà tí ń fọn fèrè. Nígbà tí ẹ bá gbọ́ ohùn fèrè náà, kí àwọn ènìyàn hó yèè ní igbe ńlá, nígbà náà ni odi ìlú náà yóò sì wó lulẹ̀, àwọn ènìyàn yóò sì lọ sí òkè, olúkúlùkù yóò sì wọ inú rẹ̀ lọ tààrà.” Bẹ́ẹ̀ ni Joṣua ọmọ Nuni pe àwọn àlùfáà ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ gbé àpótí ẹ̀rí OLúWA náà kí àwọn àlùfáà méje tí ó ru fèrè ìwo wà ní iwájú u rẹ̀.” Ó sì pàṣẹ fún àwọn ènìyàn náà pé, “Ẹ lọ, kí ẹ sì yí ìlú náà ká pẹ̀lú àwọn olùṣọ́ tí ó hámọ́ra kọjá ní iwájú àpótí ẹ̀rí OLúWA.” Nígbà tí Joṣua ti bá àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀ tán, àwọn àlùfáà méje tí wọ́n gbé fèrè méje ní iwájú OLúWA kọjá sí iwájú, wọ́n sì fọn fèrè wọn, àpótí ẹ̀rí OLúWA sì tẹ̀lé wọn. Àwọn olùṣọ tí ó hámọ́ra sì lọ níwájú àwọn àlùfáà tí ń fọn fèrè, olùṣọ́ ẹ̀yìn sì tẹ̀lé àpótí ẹ̀rí náà. Ní gbogbo àsìkò yìí fèrè sì ń dún. Ṣùgbọ́n Joṣua tí pàṣẹ fún àwọn ènìyàn pé, “Ẹ kò gbọdọ̀ kígbe ogun, ẹ kò gbọdọ̀ gbé ohùn yín sókè, ẹ má ṣe sọ ọ̀rọ̀ kan títí ọjọ́ tí èmi yóò sọ fún un yín pé kí ẹ hó. Nígbà náà ni ẹ̀yin yóò sì hó!” Bẹ́ẹ̀ ni ó mú kí àpótí ẹ̀rí OLúWA yí ìlú náà ká, ó sì yí i ká lẹ́ẹ̀kan. Nígbà náà ni àwọn ènìyàn náà padà sí ibùdó, wọ́n sì gbé ibẹ̀ fún alẹ́ náà. Joṣua sì dìde ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, àwọn àlùfáà sì gbé àpótí ẹ̀rí OLúWA. Àwọn àlùfáà méje tí ó gbé ìpè ìwo àgbò méje ń lọ níwájú àpótí ẹ̀rí OLúWA, wọ́n sì ń fọ́n àwọn ìpè: àwọn tí ó hámọ́ra ogun ń lọ níwájú u wọn; àwọn ọmọ tó wà lẹ́yìn sì ń tọ àpótí ẹ̀rí OLúWA lẹ́yìn, àwọn àlùfáà sì ń fọn ìpè bí wọ́n ti ń lọ. Ní ọjọ́ kejì, wọ́n yí ìlú náà ká lẹ́ẹ̀kan wọ́n sì padà sí ibùdó. Wọ́n sì ṣe èyí fún ọjọ́ mẹ́fà. Ní ọjọ́ keje, wọ́n dìde ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ní àfẹ̀mọ́júmọ́, wọ́n sì wọ́de ogun yí ìlú náà ká ní ìgbà méje, gẹ́gẹ́ bí i ti ìṣáájú, ní ọjọ́ keje nìkan ṣoṣo ni wọ́n wọ́de ogun yí ìlú náà ká nígbà méje. Ní ìgbà keje, nígbà tí àwọn àlùfáà fọn fèrè, Joṣua pàṣẹ fún àwọn ènìyàn pé, “Ẹ hó! Nítorí pé OLúWA ti fún un yín ní ìlú náà. Ìlú náà àti gbogbo ohun tí ó wà níbẹ̀ ni yóò jẹ́ ìyàsọ́tọ̀ fún OLúWA. Rahabu tí ó jẹ́ panṣágà nìkan àti gbogbo àwọn tí ó wà pẹ̀lú u rẹ̀ ni a ó dá sí; nítorí tí ó pa àwọn ayọ́lẹ̀wò tí á rán mọ́. Ẹ pa ara yín mọ́ kúrò nínú ohun ìyàsọ́tọ̀ fún ìparun, kí ẹ̀yin kí ó má ba à ṣojú kòkòrò nípa mímú nínú àwọn ohun ìyàsọ́tọ̀. Bí kò ṣe bẹ́ẹ̀ ẹ ó sọ ibùdó Israẹli di ìparun. Kí ẹ sì mú wàhálà wá sórí i rẹ̀. Gbogbo fàdákà àti wúrà àti ohun èlò idẹ àti irin jẹ́ mímọ́ fún OLúWA, wọ́n yóò wá sínú ìṣúra OLúWA.” Nígbà tí àwọn àlùfáà fọn ìpè, àwọn ènìyàn náà sì hó. Ó sì ṣe, bí àwọn ènìyàn ti gbọ́ ìró ìpè, tí àwọn ènìyàn sì hó ìhó ńlá, odi ìlú náà wó lulẹ̀ bẹẹrẹ; bẹ́ẹ̀ ni olúkúlùkù ya wọ inú ìlú náà lọ tààrà, wọ́n sì kó ìlú náà. Wọ́n ya ìlú náà sọ́tọ̀ fún OLúWA àti fún ìparun, wọ́n sì fi idà run gbogbo ohun alààyè ní ìlú náà—ọkùnrin àti obìnrin, ọ́mọdé, àti àgbà, màlúù, àgùntàn àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.