Joṣ 5:14-15
Joṣ 5:14-15 Bibeli Mimọ (YBCV)
O si wipe, Bẹ̃kọ; ṣugbọn bi olori ogun OLUWA ni mo wá si nisisiyi. Joṣua si wolẹ niwaju rẹ̀, o si foribalẹ, o si wi fun pe, Kili oluwa mi ni isọ fun iranṣẹ rẹ̀? Olori-ogun OLUWA si wi fun Joṣua pe, Bọ́ salubata rẹ kuro li ẹsẹ̀ rẹ; nitoripe ibi ti iwọ gbé duro nì ibi mimọ́ ni. Joṣua si ṣe bẹ̃.
Joṣ 5:14-15 Yoruba Bible (YCE)
Ọkunrin náà dáhùn pé, “Rárá, mo wá gẹ́gẹ́ bíi balogun àwọn ọmọ ogun OLUWA ni.” Joṣua bá dojúbolẹ̀, ó sin OLUWA, ó sì bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Kí ni o fẹ́ kí n ṣe, OLUWA mi?” Balogun àwọn ọmọ ogun OLUWA dá Joṣua lóhùn pé, “Bọ́ bàtà ẹsẹ̀ rẹ, nítorí ibi tí o dúró sí yìí, ilẹ̀ mímọ́ ni.” Joṣua sì bọ́ bàtà ẹsẹ̀ rẹ̀.
Joṣ 5:14-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Kì í ṣe fún èyíkéyìí ó fèsì, ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí olórí ogun OLúWA ni mo wá nísinsin yìí.” Nígbà náà ni Joṣua sì wólẹ̀ ní iwájú u rẹ̀ ní ìbẹ̀rù, ó sì bi í léèrè, “Kí ni Olúwa ní í sọ fún ìránṣẹ́ rẹ̀?” Olórí ogun OLúWA sì dá a lóhùn pé, “Bọ́ sálúbàtà rẹ kúrò ní ẹsẹ̀ rẹ, nítorí pé ibi tí ìwọ dúró sí yìí, ilẹ̀ mímọ́ ni.” Joṣua sì ṣe bẹ́ẹ̀.