Joṣ 15:13-19
Joṣ 15:13-19 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ati fun Kalebu ọmọ Jefunne li o fi ipín fun lãrin awọn ọmọ Juda, gẹgẹ bi aṣẹ OLUWA fun Joṣua, ani Kiriati-arba (ti iṣe Hebroni); Arba si ni baba Anaki. Kalebu si lé awọn ọmọ Anaki mẹta kuro nibẹ̀, Ṣeṣai, ati Ahimani, ati Talmai, awọn ọmọ Anaki. O si gòke lati ibẹ̀ tọ̀ awọn ara Debiri lọ: orukọ Debiri lailai rí ni Kiriati-seferi. Kalebu si wipe, Ẹniti o ba kọlù Kiriati-seferi, ti o sì kó o, on li emi o fi Aksa ọmọbinrin mi fun li aya. Otnieli ọmọ Kenasi, arakunrin Kalebu, si kó o: o si fi Aksa ọmọbinrin rẹ̀ fun u li aya. O si ṣe, bi Aksa ti dé ọdọ rẹ̀, o mu u bère ọ̀rọ kan lọwọ baba rẹ̀: Aksa si sọkalẹ lori kẹtẹkẹtẹ rẹ̀; Kalebu si wi fun u pe, Kini iwọ nfẹ́? On si dahùn pe, Ta mi li ọrẹ kan; nitoriti iwọ ti fun mi ni ilẹ Gusù, fun mi ni isun omi pẹlu. O si fi isun òke ati isun isalẹ fun u.
Joṣ 15:13-19 Yoruba Bible (YCE)
Gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún Joṣua, ó fún Kalebu ọmọ Jefune ní Heburoni gẹ́gẹ́ bí ìpín tirẹ̀ ninu ilẹ̀ ẹ̀yà Juda. Orúkọ Heburoni tẹ́lẹ̀ ni Kiriati Ariba, (tí a tún ń pè ní ìlú Ariba), Ariba yìí ni baba Anaki. Kalebu lé àwọn ìran Anaki mẹtẹẹta jáde níbẹ̀, àwọn ni ìran Ṣeṣai, ìran Ahimani, ati ìran Talimai. Láti ibẹ̀ ó lọ gbógun ti àwọn ará ìlú Debiri. Orúkọ Debiri tẹ́lẹ̀ ni Kiriati Seferi. Kalebu ṣe ìlérí pé, ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣẹgun Kiriati Seferi tí ó sì gba ìlú náà ni òun yóo fún ní Akisa ọmọ òun, láti fi ṣe aya. Otinieli ọmọ Kenasi, arakunrin Kalebu, ni ó ṣẹgun ìlú náà. Kalebu bá fi Akisa ọmọ rẹ̀ fún un láti fi ṣe aya. Nígbà tí Akisa dé ọ̀dọ̀ ọkọ rẹ̀, ó rọ ọkọ rẹ̀ pé kí ó tọrọ ilẹ̀ kan lọ́wọ́ baba òun. Ní ọjọ́ kan, bí Akisa ti sọ̀kalẹ̀ ní orí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀, baba rẹ̀ bi í pé, “Kí ni ò ń fẹ́?” Akisa dá baba rẹ̀ lóhùn pé, “Fún mi ní ẹ̀bùn, níwọ̀n ìgbà tí o ti fún mi ní ilẹ̀ Nẹgẹbu, fún mi ní àwọn orísun omi pẹlu.” Kalebu bá fún un ní àwọn orísun omi tí wọ́n wà lókè ati àwọn tí wọ́n wà ní ìsàlẹ̀.
Joṣ 15:13-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí OLúWA pa fún Joṣua, ó fi ìpín fún Kalebu ọmọ Jefunne, ìpín ní Juda—Kiriati-Arba, tí í ṣe Hebroni. (Arba sì ní baba ńlá Anaki.) Kalebu sì lé àwọn ọmọ Anaki mẹ́ta jáde láti Hebroni; Ṣeṣai, Ahimani, àti Talmai, ìran Anaki. Ó sì wọ́de ogun láti ibẹ̀ lọ bá àwọn ènìyàn tí ń gbé ní Debiri (tí à ń pè ní Kiriati-Seferi nígbà kan rí). Kalebu sì wí pé, “Èmi yóò fi ọmọbìnrin mi Aksa fún ọkùnrin tí ó bá kọlu Kiriati-Seferi, tí ó sì gbà á ní ìgbéyàwó.” Otnieli ọmọ Kenasi, arákùnrin Kalebu, sì gbà á, báyìí ni Kalebu sì fi ọmọbìnrin rẹ̀ Aksa fún un ní ìyàwó. Ní ọjọ́ kan, nígbà tí Aksa lọ sí ọ̀dọ̀ Otnieli, ó rọ̀ ọ́ kí ó béèrè ilẹ̀ oko lọ́wọ́ baba rẹ̀. Nígbà nàà ni Aksa sọ̀kalẹ̀ ní orí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀, Kalebu sì béèrè pé, “Kí ni kí èmi ṣe fún ọ?” Ó sì dáhùn pé, “Mo ń fẹ́ kí o ṣe ojúrere kan fún mi, nígbà ti o ti fún mi ní ilẹ̀ ní gúúsù, fún mi ní ìsun omi náà pẹ̀lú.” Kalebu sì fún un ní ìsun òkè àti ìsun ìsàlẹ̀.