Joṣ 15

15
Ilẹ̀ Tí Wọ́n Pín fún Ẹ̀yà Juda
1ILẸ ẹ̀ya awọn ọmọ Juda gẹgẹ bi idile wọn si dé àgbegbe Edomu, ni aginjù Sini, ni ìha gusù, ni apa ipẹkun gusù.
2Ati àla gusù wọn ni lati eti Okun Iyọ̀ lọ, lati ibi kọ̀rọ omi nì lọ ti o dojukọ ìha gusù:
3O si lọ si apa gusù òke Akrabbimu, o si lọ si Sini, o si gòke lọ ni ìha gusù Kadeṣi-barnea, o si lọ ni ìha Hesroni, o si gòke lọ si Adari, o si yiká lọ dé Karka:
4Lati ibẹ̀ o lọ dé Asmoni, o si nà lọ si odò Egipti; opín ilẹ na si yọ si okun: eyi ni yio jẹ́ àla ni gusù nyin.
5Ati àla ìha ìla-õrùn ni Okun Iyọ̀, ani titi dé ipẹkun Jordani. Ati àla apa ariwa ni lati kọ̀rọ okun nì wá dé ipẹkun Jordani:
6Àla na si gòke lọ si Beti-hogla, o si kọja lọ ni ìha ariwa Beti-araba; àla na si gòke lọ si okuta Bohani ọmọ Reubeni:
7Àla na si gòke lọ si Debiri lati afonifoji Akoru, ati bẹ̃ lọ si ìha ariwa, ti o dojukọ Gilgali, ti mbẹ niwaju òke Adummimu, ti mbẹ ni ìha gusù odò na: àla si kọja si apa omi Eni-ṣemeṣi, o si yọ si Eni-rogeli:
8Àla na si gòke lọ si ìha afonifoji ọmọ Hinnomu si ìha gusù ti Jebusi (ti iṣe Jerusalemu): àla na si gòke lọ si ori òke nla ti mbẹ niwaju afonifoji Hinnomu ni ìha ìwọ-õrùn, ti mbẹ ni ipẹkun afonifoji Refaimu ni ìha ariwa:
9A si fà àla na lati ori òke lọ si isun omi Neftoa, o si nà lọ si ilu òke Efroni; a si fà àla na lọ si Baala, (ti iṣe Kirjati-jearimu:)
10Àla na yi lati Baala lọ si ìha ìwọ-õrùn si òke Seiri, o si kọja lọ si ẹba òke Jearimu (ti ṣe Kesaloni), ni ìha ariwa, o si sọkalẹ lọ si Beti-ṣemeṣi, o si kọja lọ si Timna:
11Àla na si kọja lọ si ẹba Ekroni si ìha ariwa: a si fà àla na lọ dé Ṣikroni, o si kọja lọ si òke Baala, o si yọ si Jabneeli; àla na si yọ si okun.
12Àla ìwọ-õrùn si dé okun nla, ati àgbegbe rẹ̀. Eyi ni àla awọn ọmọ Juda yiká kiri gẹgẹ bi idile wọn.
Kalebu Ṣẹgun Heburoni ati Debiri
(A. Oni 1:11-15)
13Ati fun Kalebu ọmọ Jefunne li o fi ipín fun lãrin awọn ọmọ Juda, gẹgẹ bi aṣẹ OLUWA fun Joṣua, ani Kiriati-arba (ti iṣe Hebroni); Arba si ni baba Anaki.
14Kalebu si lé awọn ọmọ Anaki mẹta kuro nibẹ̀, Ṣeṣai, ati Ahimani, ati Talmai, awọn ọmọ Anaki.
15O si gòke lati ibẹ̀ tọ̀ awọn ara Debiri lọ: orukọ Debiri lailai rí ni Kiriati-seferi.
16Kalebu si wipe, Ẹniti o ba kọlù Kiriati-seferi, ti o sì kó o, on li emi o fi Aksa ọmọbinrin mi fun li aya.
17Otnieli ọmọ Kenasi, arakunrin Kalebu, si kó o: o si fi Aksa ọmọbinrin rẹ̀ fun u li aya.
18O si ṣe, bi Aksa ti dé ọdọ rẹ̀, o mu u bère ọ̀rọ kan lọwọ baba rẹ̀: Aksa si sọkalẹ lori kẹtẹkẹtẹ rẹ̀; Kalebu si wi fun u pe, Kini iwọ nfẹ́?
19On si dahùn pe, Ta mi li ọrẹ kan; nitoriti iwọ ti fun mi ni ilẹ Gusù, fun mi ni isun omi pẹlu. O si fi isun òke ati isun isalẹ fun u.
Àwọn Ìlú Ńláńlá Tí Wọ́n Wà ní Juda
20Eyi ni ilẹ-iní ẹ̀ya awọn ọmọ Juda gẹgẹ bi idile wọn.
21Ilu ipẹkun ẹ̀ya awọn ọmọ Juda li àgbegbe Edomu ni Gusù ni Kabseeli, ati Ederi, ati Jaguri;
22Ati Kina, ati Dimona, ati Adada;
23Ati Kedeṣi, ati Hasori, ati Itnani;
24Sifu, ati Telemu, ati Bealotu;
25Ati Haṣori-hadatta, ati Keriotu-hesroni (ti iṣe Hasori);
26Amamu, ati Ṣema, ati Molada;
27Ati Hasari-gada, ati Heṣmoni, ati Beti-peleti;
28Ati Hasari-ṣuali, ati Beeri-ṣeba, ati Bisi-otia;
29Baala, ati Iimu, ati Esemu;
30Ati Eltoladi, ati Kesili, ati Horma;
31Ati Siklagi, ati Madmanna, ati Sansanna;
32Ati Lebaotu, ati Ṣilhimu, ati Aini, ati Rimmoni: gbogbo ilu na jasi mọkandilọgbọ̀n, pẹlu ileto wọn.
33Ni pẹtẹlẹ̀, Eṣtaoli, ati Sora, ati Aṣna;
34Ati Sanoa, ati Eni-gannimu Tappua, ati Enamu;
35Jarmutu, ati Adullamu, Soko, ati Aseka;
36Ati Ṣaaraimu, ati Aditaimu, ati Gedera, ati Gederotaimu; ilu mẹrinla pẹlu ileto wọn.
37Senani, ati Hadaṣa, ati Migdali-gadi;
38Ati Dilani, ati Mispe, ati Jokteeli;
39Lakiṣi, ati Boskati, ati Egloni;
40Ati Kabboni, ati Lamamu, ati Kitliṣi;
41Ati Gederotu, Beti-dagoni, ati Naama, ati Makkeda; ilu mẹrindilogun pẹlu ileto wọn.
42Libna, ati Eteri, ati Aṣani;
43Ati Ifta, ati Aṣna, ati Nesibu;
44Ati Keila, ati Aksibu, ati Mareṣa; ilu mẹsan pẹlu ileto wọn.
45Ekroni, pẹlu awọn ilu rẹ̀ ati awọn ileto rẹ̀:
46Lati Ekroni lọ ani titi dé okun, gbogbo eyiti mbẹ leti Aṣdodu, pẹlu ileto wọn.
47Aṣdodu, pẹlu ilu rẹ̀ ati ileto rẹ̀; Gasa, pẹlu ilu rẹ̀ ati ileto rẹ̀; dé odò Egipti, ati okun nla, ati àgbegbe rẹ̀.
48Ati ni ilẹ òke, Ṣamiri, ati Jattiri, ati Soko;
49Ati Dana, ati Kiriati-sana (ti ṣe Debiri);
50Ati Anabu, ati Eṣtemo, ati Animu;
51Ati Goṣeni, ati Holoni, ati Gilo; ilu mọkanla pẹlu ileto wọn.
52Arabu, ati Duma, ati Eṣani;
53Ati Janimu, ati Beti-tappua, ati Afeka;
54Ati Humta, ati Kiriati-arba (ti iṣe Hebroni), ati Siori; ilu meṣan pẹlu ileto wọn.
55Maoni, Karmeli, ati Sifu, ati Juta;
56Ati Jesreeli, ati Jokdeamu, ati Sanoa;
57Kaini, Gibea, ati Timna; ilu mẹwa pẹlu ileto wọn.
58Halhulu, Beti-suru, ati Gedori;
59Ati Maarati, ati Beti-anotu, ati Eltekoni; ilu mẹfa pẹlu ileto wọn.
60Kiriati-baali (ti iṣe Kiriati-jearimu), ati Rabba; ilu meji pẹlu ileto wọn.
61Li aginjù, Beti-araba, Middini, ati Sekaka;
62Ati Nibṣani, ati Ilu Iyọ̀, ati Eni-gedi; ilu mẹfa pẹlu ileto wọn.
63Bi o si ṣe ti awọn Jebusi nì, awọn ara Jerusalemu, awọn ọmọ Juda kò le lé wọn jade: ṣugbọn awọn Jebusi mbá awọn ọmọ Juda gbé ni Jerusalemu, titi di oni-oloni.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Joṣ 15: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀