Joṣ 12:1-24

Joṣ 12:1-24 Bibeli Mimọ (YBCV)

NJẸ wọnyi ni awọn ọba ilẹ na, ti awọn ọmọ Israeli pa, ti nwọn si gbà ilẹ wọn li apa keji Jordani, ni ìha ìla-õrùn, lati odò Arnoni lọ titi dé òke Hermoni, ati gbogbo pẹtẹlẹ̀ ni ìha ìla-õrun: Sihoni ọba Amori, ti ngbé Heṣboni, ti o si jọba lati Aroeri, ti mbẹ leti odò Arnoni, ati ilu ti o wà lãrin afonifoji na, ati àbọ Gileadi, ani titi dé odò Jaboku, àgbegbe awọn ọmọ Ammoni; Ati ni pẹtẹlẹ̀ lọ dé okun Kinnerotu ni ìha ìla-õrùn, ati titi dé okun pẹtẹlẹ̀, ani Okun Iyọ̀ ni ìha ìla-õrun, li ọ̀na Beti-jeṣimotu; ati lati gusù lọ nisalẹ ẹsẹ̀-òke Pisga: Ati àgbegbe Ogu ọba Baṣani, ọkan ninu awọn ti o kù ninu awọn Refaimu, èniti ngbé Aṣtarotu ati Edrei, O si jọba li òke Hermoni, ati ni Saleka, ati ni gbogbo Baṣani, titi o fi dé àgbegbe awọn Geṣuri ati awọn Maakati, ati àbọ Gileadi, àla Sihoni ọba Heṣboni. Mose iranṣẹ OLUWA ati awọn ọmọ Israeli kọlù wọn: Mose iranṣẹ OLUWA si fi i fun awọn ọmọ Reubeni ni ilẹ-iní, ati fun awọn ọmọ Gadi, ati fun àbọ ẹ̀ya Manasse. Wọnyi li awọn ọba ilẹ na, ti Joṣua ati awọn ọmọ Israeli pa li apa ihin Jordani, ni ìwọ-õrùn, lati Baali-gadi li afonifoji Lebanoni ani titidé òke Halaki, li ọ̀na òke Seiri; ti Joṣua fi fun awọn ẹ̀ya Israeli ni ilẹ-iní gẹgẹ bi ipín wọn. Ni ilẹ òke, ati ni ilẹ titẹju, ati ni pẹtẹlẹ̀, ati li ẹsẹ̀-òke, ati li aginjù, ati ni Gusù; awọn Hitti, awọn Amori, ati awọn ara Kenaani, awọn Perissi, awọn Hifi, ati awọn Jebusi: Ọba Jeriko, ọkan; ọba Ai, ti o wà lẹba Beti-eli, ọkan. Ọba Jerusalemu, ọkan; ọba Hebroni, ọkan; Ọba Jarmutu, ọkan; ọba Lakiṣi, ọkan; Ọba Egloni, ọkan; ọba Geseri, ọkan; Ọba Debiri, ọkan; ọba Gederi, ọkan; Ọba Horma, ọkan; ọba Aradi, ọkan; Ọba Libna, ọkan; ọba Adullamu, ọkan; Ọba Makkeda, ọkan; ọba Betieli, ọkan; Ọba Tappua, ọkan; ọba Heferi, ọkan; Ọba Afeki, ọkan; ọba Laṣaroni, ọkan; Ọba Madoni, ọkan; ọba Hasoru, ọkan; Ọba Ṣimroni-meroni, ọkan; ọba Akṣafu, ọkan; Ọba Taanaki, ọkan; ọba Megiddo, ọkan; Ọba Kedeṣi, ọkan; ọba Jokneamu ti Karmeli, ọkan; Ọba Doru, li òke Doru, ọkan; ọba awọn orilẹ-ède Gilgali, ọkan; Ọba Tirsa, ọkan; gbogbo awọn ọba na jẹ́ mọkanlelọgbọ̀n.

Joṣ 12:1-24 Yoruba Bible (YCE)

Àwọn ọmọ Israẹli ṣẹgun àwọn ọba wọnyi, wọ́n sì gba gbogbo ilẹ̀ wọn tí ó wà ní apá ìlà oòrùn, ní òdìkejì odò Jọdani, láti àfonífojì Arinoni títí dé òkè Herimoni, pẹlu gbogbo agbègbè Araba ní apá ìlà oòrùn. Wọ́n ṣẹgun Sihoni, ọba àwọn ará Amori, tí ń gbé ìlú Heṣiboni. Ilẹ̀ ìjọba rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ láti Aroeri, tí ó wà ní etí àfonífojì Arinoni, ati láti agbede meji àfonífojì náà, títí dé odò Jaboku, tí í ṣe ààlà ilẹ̀ àwọn ará Amoni, ó jẹ́ ìdajì ilẹ̀ Gileadi; ati Araba, títí dé òkun Ṣinerotu ní apá ìlà oòrùn, ní ọ̀nà ìlú Beti Jeṣimotu, títí dé òkun Araba, (tí wọ́n tún ń pè ní Òkun Iyọ̀), títí lọ sí apá ìhà gúsù, títí dé ẹsẹ̀ òkè Pisiga. Wọ́n ṣẹgun Ogu, ọba Baṣani náà. Ogu yìí jẹ́ ọ̀kan ninu àwọn tí ó kù ninu ìran Refaimu tí ń gbé Aṣitarotu ati Edirei. Lára ilẹ̀ ìjọba rẹ̀ ni òkè Herimoni wà, ati ìlú Saleka, ati gbogbo Baṣani, títí dé ààlà ilẹ̀ àwọn ará Geṣuri, ati ti àwọn ará Maakati ati ìdajì Gileadi títí dé ààlà ọba Sihoni ti ìlú Heṣiboni. Mose, iranṣẹ OLUWA ati àwọn ọmọ Israẹli ṣẹgun àwọn ọba mejeeji yìí, ó sì pín ilẹ̀ wọn fún ẹ̀yà Reubẹni, ẹ̀yà Gadi ati ìdajì ẹ̀yà Manase, ilẹ̀ náà sì di tiwọn. Joṣua ati àwọn ọmọ Israẹli ṣẹgun àwọn ọba wọnyi, ní apá ìwọ̀ oòrùn odò Jọdani, wọ́n sì gba ilẹ̀ wọn, láti Baaligadi ní àfonífojì Lẹbanoni títí dé òkè Halaki, ní apá Seiri. Joṣua pín ilẹ̀ wọn fún àwọn ọmọ Israẹli gẹ́gẹ́ bí ìpín ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan. Ninu ilẹ̀ náà ni àwọn ìlú tí wọ́n wà lórí òkè wà, ati àwọn tí wọ́n wà ní ẹsẹ̀ òkè, ati àwọn tí wọ́n wà ní Araba, ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè, ní aṣálẹ̀, ati ní Nẹgẹbu. Àwọn tí wọ́n ni ilẹ̀ yìí tẹ́lẹ̀ rí ni àwọn ará Hiti ati àwọn ará Amori, àwọn ará Kenaani ati àwọn ará Perisi, àwọn ará Hifi, ati àwọn ará Jebusi. Àwọn ọmọ Israẹli ṣẹgun gbogbo ọba àwọn ìlú wọnyi: Jẹriko ati Ai, lẹ́bàá Bẹtẹli; Jerusalẹmu ati Heburoni, Jarimutu ati Lakiṣi; Egiloni ati Geseri, Debiri ati Gederi; Horima ati Aradi, Libina ati Adulamu; Makeda ati Bẹtẹli, Tapua ati Heferi; Afeki ati Laṣaroni, Madoni ati Hasori; Ṣimironi Meroni ati Akiṣafu, Taanaki ati Megido; Kedeṣi ati Jokineamu, ní Kamẹli; Dori, tí ó wà ní etí òkun; Goiimu, tí ó wà ní Galili, ati Tirisa. Gbogbo wọn jẹ́ ọba mọkanlelọgbọn.

Joṣ 12:1-24 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ìwọ̀nyí ní àwọn ọba ilẹ̀ náà tí àwọn ará Israẹli ṣẹ́gun, tí wọ́n sì gba ilẹ̀ wọn ní ìlà-oòrùn Jordani, láti odò Arnoni dé Òkè Hermoni, pẹ̀lú gbogbo ìhà ìlà-oòrùn aginjù: Sihoni ọba àwọn Amori, tí ó jẹ ọba ní Heṣboni. Ó ṣe àkóso láti Aroeri tí ń bẹ ní etí odò Arnoni, láti ìlú tó wà ní àárín Àfonífojì náà dé Odò Jabbok, èyí tí ó jẹ́ ààlà àwọn ọmọ Ammoni. Pẹ̀lú ìdajì àwọn ará Gileadi. Ó sì ṣe àkóso ní orí ìlà-oòrùn aginjù láti Òkun Kinnereti sí ìhà Òkun ti aginjù (Òkun Iyọ̀), sí Beti-Jeṣimoti, àti láti gúúsù lọ dé ìsàlẹ̀ ẹsẹ̀ òkè Pisga. Àti agbègbè Ogu ọba Baṣani, ọ̀kan nínú àwọn tí ó kù nínú àwọn ará Refaimu, ẹni tí ó jẹ ọba ní Aṣtarotu àti Edrei. Ó ṣe àkóso ní orí Òkè Hermoni, Saleka, Baṣani títí dé ààlà àwọn ènìyàn Geṣuri àti Maakati, àti ìdajì Gileadi dé ààlà Sihoni ọba Heṣboni. Mose ìránṣẹ́ OLúWA àti àwọn ọmọ Israẹli sì borí wọn. Mose ìránṣẹ́ OLúWA sì fi ilẹ̀ wọn fún àwọn ẹ̀yà Reubeni, àwọn ẹ̀yà Gadi àti ìdajì ẹ̀yà Manase kí ó jẹ́ ohun ìní wọn. Ìwọ̀nyí ní àwọn ọba ilẹ̀ náà tí Joṣua àti àwọn ọmọ Israẹli ṣẹ́gun ní ìhà ìwọ̀-oòrùn Jordani, láti Baali-Gadi ní Àfonífojì Lebanoni sí Òkè Halaki, èyí tí O lọ sí ọ̀nà Seiri (Joṣua sì fi ilẹ̀ wọn fún àwọn ẹ̀yà Israẹli ní ilẹ̀ ìní gẹ́gẹ́ bí ìpín ẹ̀yà wọn: ilẹ̀ òkè, ní ẹsẹ̀ òkè ní ìhà ìwọ̀-oòrùn òkè aginjù, ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè, ní aginjù àti nì gúúsù ilẹ̀ àwọn ará: Hiti, Amori, Kenaani, Peresi, Hifi àti àwọn ará Jebusi): Ọba Jeriko ọ̀kan Ọba Ai (tí ó wà nítòsí Beteli) ọ̀kan Ọba Jerusalẹmu ọ̀kan ọba Hebroni ọ̀kan Ọba Jarmatu ọ̀kan ọba Lakiṣi ọ̀kan Ọba Egloni ọ̀kan ọba Geseri ọ̀kan Ọba Debiri ọ̀kan ọba Gederi ọ̀kan Ọba Horma ọ̀kan ọba Aradi ọ̀kan Ọba Libina ọ̀kan ọba Adullamu ọ̀kan Ọba Makkeda ọ̀kan ọba Beteli ọ̀kan Ọba Tapua ọ̀kan ọba Heferi ọ̀kan Ọba Afeki ọ̀kan ọba Laṣaroni ọ̀kan Ọba Madoni ọ̀kan ọba Hasori ọ̀kan Ọba Ṣimroni-Meroni ọ̀kan ọba Akṣafu ọ̀kan Ọba Taanaki ọ̀kan ọba Megido ọ̀kan Ọba Kedeṣi ọ̀kan ọba Jokneamu ni Karmeli ọ̀kan Ọba Dori (ní Nafoti Dori) ọ̀kan ọba Goyimu ní Gilgali ọ̀kan Ọba Tirsa ọ̀kan