Jon 4:5-11

Jon 4:5-11 Yoruba Bible (YCE)

Jona bá jáde kúrò láàrin ìlú náà, ó sì lọ jókòó sí ìhà ìlà oòrùn ìlú náà. Ó pa àtíbàbà kan sibẹ, ó jókòó ní ìbòòji lábẹ́ rẹ̀, ó ń retí ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ sí ìlú náà. OLUWA bá rán ìtàkùn kan, ó fà á bo ibẹ̀, o sì ṣíji bo orí ibi tí Jona wà kí ó lè fún un ní ìtura ninu ìnira rẹ̀. Inú Jona dùn gidigidi nítorí ìtàkùn yìí. Ṣugbọn Ọlọrun rán kòkòrò kan ní àárọ̀ ọjọ́ keji, ó jẹ ìtàkùn náà, ó sì rọ. Nígbà tí oòrùn yọ, Ọlọrun mú kí afẹ́fẹ́ ìhà ìlà oòrùn fẹ́, oòrùn sì pa Jona tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi fẹ́rẹ̀ dákú. Ó sọ fún Ọlọrun pé kí ó gba ẹ̀mí òun. Ó ní, “Ó sàn kí n kú ju pé kí n wà láàyè lọ.” Ọlọrun bá bi Jona pé, “Ǹjẹ́ o lẹ́tọ̀ọ́ láti bínú nítorí ìtàkùn yìí?” Jona dáhùn, ó ní: “Ó tọ́ kí n bínú títí dé ojú ikú.” Nígbà náà ni OLUWA dá a lóhùn pé, “ìwọ ń káàánú ìtàkùn lásánlàsàn, tí o kò ṣiṣẹ́ fún, tí kì í sìí ṣe ìwọ ni o mú un dàgbà, àní ìtàkùn tí ó hù ní òru ọjọ́ kan, tí ó sì gbẹ ní ọjọ́ keji. Ṣé kò yẹ kí èmi foríji Ninefe, ìlú ńlá nì, tí àwọn ọmọde inú rẹ̀ ju ọ̀kẹ́ mẹfa (120,000) lọ, tí wọn kò mọ ọwọ́ ọ̀tún yàtọ̀ sí tòsì, pẹlu ọpọlọpọ ẹran ọ̀sìn tí ó wà ninu ìlú náà?”

Jon 4:5-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Jona sì jáde kúrò ní ìlú náà, ó sì jókòó níhà ìlà-oòrùn ìlú náà. Ó sì pa àgọ́ kan níbẹ̀ fún ara rẹ̀, ó sì jókòó ni òjìji ní abẹ́ rẹ̀ títí yóò fi rí ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ sí ìlú náà. OLúWA Ọlọ́run sì pèsè ìtàkùn kan, ó ṣe é kí ó gòkè wá sórí Jona; kí ó lè ṣe ìji bò ó lórí; láti gbà á kúrò nínú ìbànújẹ́ rẹ̀. Jona sì yọ ayọ̀ ńlá nítorí ìtàkùn náà. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run pèsè kòkòrò kan nígbà tí ilẹ̀ mọ́ ní ọjọ́ kejì, ó sì jẹ ìtàkùn náà ó sì rọ. Ó sì ṣe, nígbà tí oòrùn yọ, Ọlọ́run pèsè ẹ̀fúùfù gbígbóná tí ìlà-oòrùn; oòrùn sì pa Jona lórí tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi rẹ̀ ẹ́. Ó sì fẹ́ nínú ara rẹ̀ láti kú, ó sì wí pé, “Ó sàn fún mi láti kú ju àti wà láààyè lọ.” Ọlọ́run sì wí fún Jona pé, “O ha tọ́ fún ọ láti bínú nítorí ìtàkùn náà?” Òun sì wí pé, “Mo ni ẹ̀tọ́, o tọ́ fún mi láti bínú títí dé ikú.” Nígbà náà ni OLúWA wí pé, “Ìwọ kẹ́dùn ìtàkùn náà, nítorí èyí tí ìwọ kò ṣiṣẹ́ fun, tí ìwọ kò mu dàgbà; tí ó hù jáde ní òru kan tí ó sì kú ni òru kan. Ṣùgbọ́n Ninefe ní jù ọ̀kẹ́ mẹ́fà (12,000) ènìyàn nínú rẹ̀, tí wọn kò mọ ọwọ́ ọ̀tún wọn yàtọ̀ sí ti òsì, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun ọ̀sìn pẹ̀lú. Ṣé èmí kò ha ní kẹ́dùn nípa ìlú ńlá náà?”

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa