Jona si jade kuro ni ilu na, o si joko niha ila-õrun ilu na, o si pa agọ kan nibẹ fun ara rẹ̀, o si joko ni iboji labẹ rẹ̀, titi yio fi ri ohun ti yio ṣe ilu na. Oluwa Ọlọrun si pese itakùn kan, o si ṣe e ki o goke wá sori Jona; ki o le ṣiji bò o lori; lati gbà a kuro ninu ibinujẹ rẹ̀. Jona si yọ ayọ̀ nla nitori itakùn na. Ṣugbọn Ọlọrun pese kokorò kan nigbati ilẹ mọ́ ni ijọ keji, o si jẹ itakùn na, o si rọ. O si ṣe, nigbati õrun là, Ọlọrun si pese ẹfufu gbigbona ti ila-õrùn; õrùn si pa Jona lori, tobẹ̃ ti o rẹ̀ ẹ, o si fẹ́ ninu ara rẹ̀ lati kú, o si wipe, O sàn fun mi lati kú jù ati wà lãyè lọ. Ọlọrun si wi fun Jona pe, O ha tọ́ fun ọ lati binu nitori itakùn na? on si wipe, O tọ́ fun mi lati binu titi de ikú. Nigbana ni Oluwa wipe, Iwọ kẹdùn itakùn na nitori eyiti iwọ kò ṣiṣẹ, bẹ̃li iwọ kò mu u dagbà; ti o hù jade li oru kan ti o si kú li oru kan. Ki emi ki o má si da Ninefe si, ilu nla nì, ninu eyiti jù ọ̀kẹ-mẹfa enia wà ti kò le mọ̀ ọtun mọ̀ osì ninu ọwọ́ wọn, ati ọ̀pọlọpọ ohun-ọsìn?
Kà Jon 4
Feti si Jon 4
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Jon 4:5-11
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò