Jon 2:5-10
Jon 2:5-10 Bibeli Mimọ (YBCV)
Omi yi mi kakiri, ani titi de ọkàn; ibu yi mi kakiri, a fi koriko-odò wé mi lori. Emi sọkalẹ lọ si isalẹ awọn oke nla; ilẹ aiye pẹlu idenà rẹ̀ wà yi mi ka titi: ṣugbọn iwọ ti mu ẹmi mi wá soke lati inu ibú wá, Oluwa Ọlọrun mi. Nigbati o rẹ ọkàn mi ninu mi, emi ranti Oluwa: adura mi si wá sọdọ rẹ sinu tempili mimọ́ rẹ. Awọn ti nkiyesi eke asan kọ̀ ãnu ara wọn silẹ. Ṣugbọn emi o fi ohùn idupẹ rubọ si ọ; emi o san ẹjẹ́ ti mo ti jẹ. Ti Oluwa ni igbala. Oluwa si sọ fun ẹja na, o si pọ̀ Jona sori ilẹ gbigbẹ.
Jon 2:5-10 Yoruba Bible (YCE)
Omi bò mí mọ́lẹ̀, ibú omi yí mi ká, koríko inú omi sì wé mọ́ mi lórí. Mo já sí ibi tí ó jìn jùlọ ninu òkun, àní ibi tí ẹnikẹ́ni kò lọ ní àlọ-bọ̀ rí. Ṣugbọn ìwọ, OLUWA Ọlọrun mi, o mú ẹ̀mí mi jáde láti inú ibú náà. Nígbà tí ẹ̀mí mi ń bọ́ lọ, mo gbadura sí ìwọ OLUWA, o sì gbọ́ adura mi ninu tẹmpili mímọ́ rẹ. Àwọn tí wọn ń sin àwọn oriṣa lásánlàsàn kọ̀, wọn kò pa ìlérí wọn sí ọ mọ́. Ṣugbọn n óo rúbọ sí ọ pẹlu ohùn ọpẹ́, n óo sì san ẹ̀jẹ́ mi. Ti OLUWA ni ìgbàlà!” OLUWA bá pàṣẹ fún ẹja tí ó gbé Jona mì, ó sì lọ pọ̀ ọ́ sí èbúté, lórí ilẹ̀ gbígbẹ.
Jon 2:5-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Omi yí mi káàkiri, àní títí dé ọkàn; ibú yí mi káàkiri, a fi koríko odò wé mi lórí. Èmi sọ̀kalẹ̀ lọ sí ìsàlẹ̀ àwọn òkè ńlá; ilẹ̀ ayé pẹ̀lú ìdènà rẹ̀ yí mi ká títí: ṣùgbọ́n ìwọ ti mú ẹ̀mí mi wá sókè láti inú ibú wá, OLúWA Ọlọ́run mi. “Nígbà tí ó rẹ ọkàn mi nínú mi, èmi rántí rẹ, OLúWA, àdúrà mi sì wá sí ọ̀dọ̀ rẹ, nínú tẹmpili mímọ́ rẹ. “Àwọn tí ń fàmọ́ òrìṣà èké kọ àánú ara wọn sílẹ̀. Ṣùgbọ́n èmi yóò fi orin ọpẹ́, rú ẹbọ sí ọ. Èmi yóò san ẹ̀jẹ́ tí mo ti jẹ́. ‘Ìgbàlà wá láti ọ̀dọ̀ OLúWA.’ ” OLúWA sì pàṣẹ fún ẹja náà, ó sì pọ Jona sí orí ilẹ̀ gbígbẹ.