Jon 1:13-16
Jon 1:13-16 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ṣugbọn awọn ọkunrin na wà kikan lati mu ọkọ̀ wá si ilẹ; ṣugbọn nwọn kò le ṣe e: nitori ti okun ru, o si jà ẹfufu lile si wọn. Nitorina nwọn kigbe si Oluwa nwọn si wi pe, Awa bẹ̀ ọ, Oluwa awa bẹ̀ ọ, máṣe jẹ ki awa ṣegbe nitori ẹmi ọkunrin yi, má si ka ẹjẹ alaiṣẹ si wa li ọrùn: nitori iwọ, Oluwa, ti ṣe bi o ti wù ọ. Bẹ̃ni nwọn gbe Jona, ti nwọn si sọ ọ sinu okun: okun si dẹkun riru rẹ̀. Nigbana ni awọn ọkunrin na bẹ̀ru Oluwa gidigidi, nwọn si rubọ si Oluwa, nwọn si jẹ́ ẹ̀jẹ́.
Jon 1:13-16 Yoruba Bible (YCE)
Sibẹsibẹ, àwọn tí wọn ń tu ọkọ̀ náà gbìyànjú láti tu ọkọ̀ wọn pada sórí ilẹ̀, ṣugbọn kò ṣeéṣe, nítorí pé, afẹ́fẹ́ líle dojú kọ wọ́n, ìjì náà sì ń pọ̀ sí i. Wọ́n bá gbadura sí OLUWA, wọ́n ní, “A bẹ̀ ọ́, OLUWA, má jẹ́ kí á ṣègbé nítorí ti ọkunrin yìí, má sì ka ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ yìí sí wa lọ́rùn; nítorí bí o ti fẹ́ ni ò ń ṣe.” Wọ́n bá gbé Jona jù sinu òkun, òkun sì dákẹ́rọ́rọ́. Ẹ̀rù OLUWA ba àwọn tí wọ́n wà ninu ọkọ̀ lọpọlọpọ, wọ́n rúbọ, wọ́n sì jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún OLUWA.
Jon 1:13-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ṣùgbọ́n àwọn ọkùnrin náà gbìyànjú gidigidi láti mú ọkọ̀ wà sí ilẹ̀: ṣùgbọ́n wọn kò lè ṣe é: nítorí tí Òkun túbọ̀ ru sí i, ó sì ja ẹ̀fúùfù líle sí wọn. Nítorí náà wọ́n kígbe sí OLúWA, wọ́n sì wí pé, “OLúWA àwa bẹ̀ ọ́, má ṣe jẹ́ kí àwa ṣègbé nítorí ẹ̀mí ọkùnrin yìí. Má sì ka ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sí wa ní ọrùn, nítorí ìwọ, OLúWA, ti ṣe bí ó ti wù ọ́.” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n gbé Jona, tí wọ́n sì sọ ọ́ sínú Òkun, Òkun sì dẹ́kun ríru rẹ̀. Nígbà náà ni àwọn ọkùnrin náà bẹ̀rù OLúWA gidigidi, wọn si rú ẹbọ sí OLúWA, wọ́n sì jẹ́ ẹ̀jẹ́.