Job 42:1-5
Job 42:1-5 Bibeli Mimọ (YBCV)
NIGBANA ni Jobu da OLUWA lohùn o si wipe, Emi mọ̀ pe, iwọ le iṣe ohun gbogbo, ati pe, kò si iro-inu ti a le ifasẹhin kuro lọdọ rẹ. Tani ẹniti nfi ìgbimọ pamọ laini ìmọ? nitorina ni emi ṣe nsọ eyi ti emi kò mọ̀, ohun ti o ṣe iyanu jọjọ niwaju mi, ti emi kò moye. Emi bẹ̀ ọ, gbọ́, emi o si sọ, emi o bère lọwọ rẹ, ki iwọ ki o si bùn mi ni oye. Emi ti fi gbigbọ́ eti gburo rẹ, ṣugbọn nisisiyi oju mi ti ri ọ.
Job 42:1-5 Yoruba Bible (YCE)
Jobu bá dá OLUWA lóhùn ó ní: “Mo mọ̀ pé o lè ṣe ohun gbogbo, kò sì sí ohun tí ó lè da ìpinnu rẹ rú. Ta nìyí tí ń fi ìmọ̀ràn pamọ́ láìní òye? Àwọn ohun tí mo sọ kò yé mi, ìyanu ńlá ni wọ́n jẹ́ fún mi, n kò sì mọ̀ wọ́n. O ní kí n tẹ́tí sílẹ̀, nígbà tí o bá ń sọ̀rọ̀, kí n sì dáhùn nígbà tí o bá bèèrè nǹkan lọ́wọ́ mi. Ìró rẹ ni mo gbọ́ tẹ́lẹ̀, ṣugbọn nisinsinyii mo ti rí ọ
Job 42:1-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà náà ní Jobu dá OLúWA lóhùn, ó sì wí pé: “Èmi mọ̀ pé, ìwọ lè e ṣe ohun gbogbo, àti pé, kò si ìrò inú tí a lè fa sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ rẹ. Ìwọ béèrè, ta ni ẹni tí ń fi ìgbìmọ̀ pamọ́ láìní ìmọ̀? Nítorí náà ní èmi ṣe ń sọ èyí tí èmi kò mọ̀, ohun tí ó ṣe ìyanu jọjọ níwájú mi, ti èmi kò mòye. “Ìwọ wí pé, ‘gbọ́ tèmi báyìí, èmi ó sì sọ; èmi ó béèrè lọ́wọ́ rẹ, ìwọ yóò sì dá mi lóhùn.’ Etí mi sì ti gbọ́ nípa rẹ, ṣùgbọ́n nísinsin yìí ojú mi ti rí ọ.