JOBU 42

42
1Jobu bá dá OLUWA lóhùn ó ní:
2“Mo mọ̀ pé o lè ṣe ohun gbogbo,
kò sì sí ohun tí ó lè da ìpinnu rẹ rú.
3Ta nìyí tí ń fi ìmọ̀ràn pamọ́ láìní òye?
Àwọn ohun tí mo sọ kò yé mi,
ìyanu ńlá ni wọ́n jẹ́ fún mi,
n kò sì mọ̀ wọ́n.
4O ní kí n tẹ́tí sílẹ̀,
nígbà tí o bá ń sọ̀rọ̀,
kí n sì dáhùn nígbà tí o bá bèèrè nǹkan lọ́wọ́ mi.
5Ìró rẹ ni mo gbọ́ tẹ́lẹ̀,
ṣugbọn nisinsinyii mo ti rí ọ;
6nítorí náà, ojú ara mi tì mí,
fún ohun tí mo ti sọ,
mo sì ronupiwada ninu erùpẹ̀ ati eérú.”
Ìparí
7Lẹ́yìn ìgbà tí OLUWA ti bá Jobu sọ̀rọ̀ tán, ó sọ fún Elifasi ará Temani pé, “Inú ń bí mi sí ìwọ ati àwọn ọ̀rẹ́ rẹ mejeeji. Nítorí ẹ kò sọ ohun tí ó tọ́ nípa mi, bí Jobu iranṣẹ mi ti ṣe. 8Nítorí náà, mú akọ mààlúù meje ati àgbò meje lọ sí ọ̀dọ̀ Jobu kí o rú ẹbọ sísun fún ara rẹ; Jobu iranṣẹ mi yóo sì gbadura fún ọ, n óo gbọ́ adura rẹ̀, n kò sì ní ṣe sí ọ gẹ́gẹ́ bí ìwà òmùgọ̀ rẹ. Nítorí o kò sọ ohun tí ó tọ́ nípa mi gẹ́gẹ́ bí Jobu iranṣẹ mi ti ṣe.”
9Nítorí náà, Elifasi ará Temani, Bilidadi ará Ṣuha, ati Sofari ará Naama lọ ṣe ohun tí OLUWA sọ fún wọn, OLUWA sì gbọ́ adura Jobu.
10Lẹ́yìn ìgbà tí Jobu gbadura fún àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ mẹtẹẹta tán, OLUWA dá ọrọ̀ Jobu pada, ó sì jẹ́ kí ó ní ìlọ́po meji àwọn ohun tí ó ti ní tẹ́lẹ̀. 11Àwọn arakunrin ati arabinrin Jobu ati àwọn ojúlùmọ̀ rẹ̀ tẹ́lẹ̀ pada wá bẹ̀ ẹ́ wò. Wọ́n jẹ àsè ní ilé rẹ̀, wọ́n káàánú rẹ̀, wọ́n sì tù ú ninu, nítorí ohun burúkú tí OLUWA ti mú wá sórí rẹ̀, olukuluku wọn fún un ní owó ati òrùka wúrà kọ̀ọ̀kan.
12OLUWA bukun ìgbẹ̀yìn Jobu ju ti iṣaaju rẹ̀ lọ, ó ní ẹgbaaje (14,000) aguntan, ẹgbaata (6,000) ràkúnmí, ẹgbẹrun (1,000) àjàgà mààlúù ati ẹgbẹrun (1,000) abo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́. 13Ó tún bí ọmọkunrin meje ati ọmọbinrin mẹta. 14Ó pe àkọ́bí obinrin ni Jemima, ekeji ni Kesaya, ẹkẹta ni Kereni Hapuki. 15Kò sì sí ọmọbinrin tí ó lẹ́wà bí àwọn ọmọbinrin Jobu ní gbogbo ayé. Baba wọn sì fún wọn ní ogún láàrin àwọn arakunrin wọn.
16Lẹ́yìn náà Jobu tún gbé ogoje (140) ọdún sí i láyé, ó rí àwọn ọmọ ati àwọn ọmọ-ọmọ rẹ̀ títí dé ìran kẹrin. 17Ó di arúgbó kùjọ́kùjọ́ kí ó tó kú.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

JOBU 42: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀