Job 4:7-11
Job 4:7-11 Bibeli Mimọ (YBCV)
Emi bẹ̀ ọ ranti, tali o ṣegbe ri laiṣẹ̀, tabi nibo li a gbe ké olododo kuro ri? Ani bi emi ti ri rí pe: awọn ti nṣe itulẹ ẹ̀ṣẹ, ti nwọn si fọ́n irugbin ìwa buburu, nwọn a si ká eso rẹ̀ na. Nipa ifẹsi Ọlọrun nwọn a ṣegbe, nipa ẽmi ibinu rẹ̀ nwọn a parun. Bibu ramuramu kiniun ati ohùn onroró kiniun ati ehin awọn ẹ̀gbọrọ kiniun li a ka. Ogbo kiniun kígbe, nitori airi ohun-ọdẹ, awọn ẹ̀gbọrọ kiniun sisanra li a tukakiri.
Job 4:7-11 Yoruba Bible (YCE)
“Ìwọ náà ronú wò, ṣé aláìṣẹ̀ kan ṣègbé rí? Tabi olódodo kan parun rí? Bí èmi ti rí i sí ni pé, ẹni tí ó kọ ẹ̀ṣẹ̀ mọ́ ebè, tí ó sì gbin wahala, yóo kórè ìyọnu. Èémí Ọlọrun níí pa wọ́n run, ninu ibinu rẹ̀, wọ́n a sì ṣègbé. Ọlọrun fi òpin sí igbe kinniun, ati bíbú tí kinniun ń bú ramúramù, ó sì wọ́ àwọn ẹgbọ̀rọ̀ kinniun léyín. Kinniun alágbára a máa kú, nítorí àìrí ẹran pa jẹ, àwọn ọmọ abo kinniun a sì fọ́nká.
Job 4:7-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Èmi bẹ̀ ọ́ rántí: Ta ni ó ṣègbé rí láìṣẹ̀? Tàbí níbo ni a gbé gé olódodo kúrò rí? Àní bí èmi ti rí i pé, àwọn tí ń ṣe ìtulẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀, tí wọ́n sì fún irúgbìn ìwà búburú, wọn a sì ká èso rẹ̀ náà. Nípa ìfẹ́ sí Ọlọ́run wọn a ṣègbé, nípa èémí ìbínú rẹ̀ wọn a parun. Bíbú ramúramù kìnnìún àti ohùn òǹrorò kìnnìún àti eyín àwọn ẹgbọrọ kìnnìún ní a ká. Kìnnìún kígbe, nítorí àìrí ohun ọdẹ, àwọn ẹgbọrọ kìnnìún sísanra ni a túká kiri.