JOBU 4

4
Ìfọ̀rọ̀wérọ̀ Kinni
(4:1–14:22)
1Nígbà náà ni Elifasi, ará Temani, dá Jobu lóhùn, ó ní:
2“Bí eniyan bá bá ọ sọ̀rọ̀,
ṣé kò ní bí ọ ninu?
Àbí eniyan ha lè dákẹ́ bí?
3O ti kọ́ ọpọlọpọ eniyan,
o ti fún aláìlera lókun.
4O ti fi ọ̀rọ̀ gbé àwọn tí wọn ń ṣubú ró,
ọ̀rọ̀ rẹ ti fún orúnkún tí ń yẹ̀ lọ lágbára.
5Ṣugbọn nisinsinyii tí ọ̀rọ̀ kàn ọ́,
o kò ní sùúrù;
Ó dé bá ọ, ìdààmú bá ọ.
6Ṣé ìbẹ̀rù Ọlọrun kò tó ìgboyà fún ọ?
Àbí ìwà òdodo rẹ kò fún ọ ní ìrètí?
7“Ìwọ náà ronú wò,
ṣé aláìṣẹ̀ kan ṣègbé rí?
Tabi olódodo kan parun rí?
8Bí èmi ti rí i sí ni pé,
ẹni tí ó kọ ẹ̀ṣẹ̀ mọ́ ebè,
tí ó sì gbin wahala,
yóo kórè ìyọnu.
9Èémí Ọlọrun níí pa wọ́n run,
ninu ibinu rẹ̀, wọ́n a sì ṣègbé.
10Ọlọrun fi òpin sí igbe kinniun,
ati bíbú tí kinniun ń bú ramúramù,
ó sì wọ́ àwọn ẹgbọ̀rọ̀ kinniun léyín.
11Kinniun alágbára a máa kú,
nítorí àìrí ẹran pa jẹ,
àwọn ọmọ abo kinniun a sì fọ́nká.
12“Nisinsinyii wọ́n fọ̀rọ̀ kan tó mi létí
mo gbọ́ wúyẹ́-wúyẹ́ rẹ̀.
13Ninu ìran lóru,
nígbà tí àwọn eniyan sùn fọnfọn,
14ìbẹ̀rùbojo mú mi,
gbogbo ara mi sì ń gbọ̀n rìrì.
15Ẹ̀mí kan kọjá fìrí níwájú mi,
gbogbo irun ara mi sì dìde.
16Ó dúró jẹ́ẹ́,
ṣugbọn n kò mọ̀ bí ó ti rí.
Mo ṣá rí kinní kan tí ó dúró;
gbogbo nǹkan parọ́rọ́,
nígbà náà ni mo gbọ́ ohùn kan tí ó wí pé,
17‘Ǹjẹ́ ẹnikẹ́ni lè jẹ́ olódodo níwájú Ọlọrun?
Tabi kí eniyan jẹ́ mímọ́ níwájú Ẹlẹ́dàá rẹ̀?
18Nígbà tí ó jẹ́ pé,
Ọlọrun kò gbẹ́kẹ̀lé àwọn iranṣẹ rẹ̀,
a sì máa bá àṣìṣe lọ́wọ́ àwọn angẹli rẹ̀;
19mélòó mélòó wá ni eniyan tí a fi amọ̀ mọ,
tí ìpìlẹ̀ wọn jẹ́ erùpẹ̀,
tí a lè pa bíi kòkòrò lásánlàsàn.
20Eniyan lè wà láàyè ní òwúrọ̀
kí ó kú kí ó tó di ọjọ́ alẹ́,
wọn a parun títí lae
láìsí ẹni tí yóo bìkítà.
21Bí a bá gba gbogbo ohun tí wọ́n fẹ̀mí tẹ̀,
ṣé wọn kò ní kú bí aláìgbọ́n?’#Job 33:15

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

JOBU 4: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀