Job 4:1-21
Job 4:1-21 Bibeli Mimọ (YBCV)
NIGBANA ni Elifasi, ara Tema, dahùn wipe, Bi awa ba fi ẹnu le e, lati ba ọ sọrọ, iwọ o ha binujẹ? ṣugbọn tali o le pa ọ̀rọ mọ ẹnu laisọ? Kiyesi i, iwọ sa ti kọ́ ọ̀pọ enia, iwọ sa ti mu ọwọ alailera le. Ọ̀rọ rẹ ti gbe awọn ti nṣubu lọ duro, iwọ si ti mu ẽkun awọn ti nwarirì lera. Ṣugbọn nisisiyi o de ba ọ, o si rẹ̀ ọ, o kọlu ọ, ara rẹ kò lelẹ̀. Ibẹru Ọlọrun rẹ kò ha jẹ igbẹkẹle rẹ? ati iduro ṣinṣin si ìwa ọ̀na rẹ kò ha si jẹ abá rẹ? Emi bẹ̀ ọ ranti, tali o ṣegbe ri laiṣẹ̀, tabi nibo li a gbe ké olododo kuro ri? Ani bi emi ti ri rí pe: awọn ti nṣe itulẹ ẹ̀ṣẹ, ti nwọn si fọ́n irugbin ìwa buburu, nwọn a si ká eso rẹ̀ na. Nipa ifẹsi Ọlọrun nwọn a ṣegbe, nipa ẽmi ibinu rẹ̀ nwọn a parun. Bibu ramuramu kiniun ati ohùn onroró kiniun ati ehin awọn ẹ̀gbọrọ kiniun li a ka. Ogbo kiniun kígbe, nitori airi ohun-ọdẹ, awọn ẹ̀gbọrọ kiniun sisanra li a tukakiri. Njẹ nisisiyi a fi ohun lilumọ́ kan hàn fun mi, eti mi si gbà diẹ ninu rẹ̀. Ni iro inu loju iran oru, nigbati orun ìjika kun enia. Ẹ̀ru bà mi ati iwarirì ti o mu gbogbo egungun mi wá pepé. Nigbana ni iwin kan kọja lọ niwaju mi, irun ara mi dide ró ṣanṣan. On duro jẹ, ṣugbọn emi kò le iwò apẹrẹ irí rẹ̀, àworan kan hàn niwaju mi, idakẹ rọrọ wà, mo si gbohùn kan wipe: Ẹni kikú le jẹ olododo niwaju Ọlọrun, enia ha le mọ́ ju Ẹlẹda rẹ̀ bi? Kiyesi i, on kò gbẹkẹle awọn iranṣẹ rẹ̀, ninu awọn angeli rẹ̀ ni o si ri ẹ̀ṣẹ. Ambọtori awọn ti ngbe inu ile amọ̀, ẹniti ipilẹ wọn jasi erupẹ ti yio di rirun kòkoro. A npa wọn run lati òwurọ di alẹ́, nwọn gbe lailai lairi ẹni kà a si. A kò ha ke okùn iye wọn kuro bi? nwọn ku, ani lailọgbọn.
Job 4:1-21 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà náà ni Elifasi, ará Temani, dá Jobu lóhùn, ó ní: “Bí eniyan bá bá ọ sọ̀rọ̀, ṣé kò ní bí ọ ninu? Àbí eniyan ha lè dákẹ́ bí? O ti kọ́ ọpọlọpọ eniyan, o ti fún aláìlera lókun. O ti fi ọ̀rọ̀ gbé àwọn tí wọn ń ṣubú ró, ọ̀rọ̀ rẹ ti fún orúnkún tí ń yẹ̀ lọ lágbára. Ṣugbọn nisinsinyii tí ọ̀rọ̀ kàn ọ́, o kò ní sùúrù; Ó dé bá ọ, ìdààmú bá ọ. Ṣé ìbẹ̀rù Ọlọrun kò tó ìgboyà fún ọ? Àbí ìwà òdodo rẹ kò fún ọ ní ìrètí? “Ìwọ náà ronú wò, ṣé aláìṣẹ̀ kan ṣègbé rí? Tabi olódodo kan parun rí? Bí èmi ti rí i sí ni pé, ẹni tí ó kọ ẹ̀ṣẹ̀ mọ́ ebè, tí ó sì gbin wahala, yóo kórè ìyọnu. Èémí Ọlọrun níí pa wọ́n run, ninu ibinu rẹ̀, wọ́n a sì ṣègbé. Ọlọrun fi òpin sí igbe kinniun, ati bíbú tí kinniun ń bú ramúramù, ó sì wọ́ àwọn ẹgbọ̀rọ̀ kinniun léyín. Kinniun alágbára a máa kú, nítorí àìrí ẹran pa jẹ, àwọn ọmọ abo kinniun a sì fọ́nká. “Nisinsinyii wọ́n fọ̀rọ̀ kan tó mi létí mo gbọ́ wúyẹ́-wúyẹ́ rẹ̀. Ninu ìran lóru, nígbà tí àwọn eniyan sùn fọnfọn, ìbẹ̀rùbojo mú mi, gbogbo ara mi sì ń gbọ̀n rìrì. Ẹ̀mí kan kọjá fìrí níwájú mi, gbogbo irun ara mi sì dìde. Ó dúró jẹ́ẹ́, ṣugbọn n kò mọ̀ bí ó ti rí. Mo ṣá rí kinní kan tí ó dúró; gbogbo nǹkan parọ́rọ́, nígbà náà ni mo gbọ́ ohùn kan tí ó wí pé, ‘Ǹjẹ́ ẹnikẹ́ni lè jẹ́ olódodo níwájú Ọlọrun? Tabi kí eniyan jẹ́ mímọ́ níwájú Ẹlẹ́dàá rẹ̀? Nígbà tí ó jẹ́ pé, Ọlọrun kò gbẹ́kẹ̀lé àwọn iranṣẹ rẹ̀, a sì máa bá àṣìṣe lọ́wọ́ àwọn angẹli rẹ̀; mélòó mélòó wá ni eniyan tí a fi amọ̀ mọ, tí ìpìlẹ̀ wọn jẹ́ erùpẹ̀, tí a lè pa bíi kòkòrò lásánlàsàn. Eniyan lè wà láàyè ní òwúrọ̀ kí ó kú kí ó tó di ọjọ́ alẹ́, wọn a parun títí lae láìsí ẹni tí yóo bìkítà. Bí a bá gba gbogbo ohun tí wọ́n fẹ̀mí tẹ̀, ṣé wọn kò ní kú bí aláìgbọ́n?’
Job 4:1-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ìgbà náà ni Elifasi, ará Temani dáhùn wí pé: “Bí àwa bá fi ẹnu lé e, láti bá ọ sọ̀rọ̀, ìwọ o ha banújẹ́? Ṣùgbọ́n ta ni ó lè pa ọ̀rọ̀ mọ́ ẹnu láìsọ? Kíyèsi i, ìwọ sá ti kọ́ ọ̀pọ̀ ènìyàn, ìwọ ṣá ti mú ọwọ́ aláìlera le. Ọ̀rọ̀ rẹ ti gbé àwọn tí ń ṣubú lọ dúró, ìwọ sì ti mú eékún àwọn tí ń wárìrì lera. Ṣùgbọ́n nísinsin yìí ó dé bá ọ, ó sì rẹ̀ ọ́, ó kọlù ọ́; ara rẹ kò lélẹ̀. Ìbẹ̀rù Ọlọ́run rẹ kò ha jẹ́ ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ àti ìdúró ọ̀nà rẹ kò ha sì jẹ́ ìrètí rẹ? “Èmi bẹ̀ ọ́ rántí: Ta ni ó ṣègbé rí láìṣẹ̀? Tàbí níbo ni a gbé gé olódodo kúrò rí? Àní bí èmi ti rí i pé, àwọn tí ń ṣe ìtulẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀, tí wọ́n sì fún irúgbìn ìwà búburú, wọn a sì ká èso rẹ̀ náà. Nípa ìfẹ́ sí Ọlọ́run wọn a ṣègbé, nípa èémí ìbínú rẹ̀ wọn a parun. Bíbú ramúramù kìnnìún àti ohùn òǹrorò kìnnìún àti eyín àwọn ẹgbọrọ kìnnìún ní a ká. Kìnnìún kígbe, nítorí àìrí ohun ọdẹ, àwọn ẹgbọrọ kìnnìún sísanra ni a túká kiri. “Ǹjẹ́ nísinsin yìí a fi ohun àṣírí kan hàn fún mi, etí mi sì gbà díẹ̀ nínú rẹ̀. Ní ìrò inú lójú ìran òru, nígbà tí oorun èjìká kùn ènìyàn. Ẹ̀rù bà mí àti ìwárìrì tí ó mú gbogbo egungun mi jí pépé. Nígbà náà ni ẹ̀mí kan kọjá lọ ní iwájú mi, irun ara mi dìde dúró ṣánṣán. Ó dúró jẹ́ẹ́, ṣùgbọ́n èmi kò le wo àpẹẹrẹ ìrí rẹ̀, àwòrán kan hàn níwájú mi, ìdákẹ́rọ́rọ́ wà, mo sì gbóhùn kan wí pé: ‘Ẹni kíkú le jẹ́ olódodo ju Ọlọ́run, ènìyàn ha le mọ́ ju Ẹlẹ́dàá rẹ̀ bí? Kíyèsi i, òun kò gbẹ́kẹ̀lé àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, nínú àwọn angẹli rẹ̀ ní ó sì rí ẹ̀ṣẹ̀. Mélòó mélòó àwọn tí ń gbé inú ilé amọ̀, ẹni tí ìpìlẹ̀ wọ́n jásí erùpẹ̀ tí yóò di rírun kòkòrò. A pa wọ́n run láàrín òwúrọ̀ àti àṣálẹ́ wọ́n sì parun títí láé, láìrí ẹni kà á sí. A kò ha ké okùn iye wọ́n kúrò bí? Wọ́n kú, àní láìlọ́gbọ́n?’