Job 38:1-7
Job 38:1-7 Bibeli Mimọ (YBCV)
NIGBANA ni OLUWA da Jobu lohùn lati inu ìji ajayika wá o si wipe, Tani eyi ti nfi ọ̀rọ aini igbiro ṣú ìmọ li òkunkun. Di ẹgbẹ ara rẹ li amure bi ọkunrin nisisiyi, nitoripe emi o bère lọwọ rẹ ki o si da mi lohùn. Nibo ni iwọ wà nigbati mo fi ipilẹ aiye sọlẹ? wi bi iwọ ba moye! Tali o fi ìwọn rẹ̀ lelẹ, bi iwọ ba mọ̀, tabi tani o ta okun wiwọn sori rẹ̀. Lori ibo ni a gbe kan ipilẹ rẹ̀ mọ́, tabi tali o fi okuta igun rẹ̀ le ilẹ? Nigbati awọn irawọ owurọ jumọ kọrin pọ̀, ti gbogbo awọn ọmọ Ọlọrun nhó iho ayọ̀?
Job 38:1-7 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà náà ni OLUWA dá Jobu lóhùn láti inú ìjì líle. Ó bi í pé, “Ta ni ẹni tí ń bu ẹnu àtẹ́ lu ìmọ̀ràn, tí ń sọ̀rọ̀ tí kò ní ìmọ̀? Nisinsinyii, múra gírí bí ọkunrin, mo ní ìbéèrè kan láti bí ọ, o óo sì dá mi lóhùn. Níbo lo wà, nígbà tí mo fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀? Bí o bá mọ ìgbà náà, sọ fún mi. Ta ló ṣe ìdíwọ̀n rẹ̀– ṣebí o mọ̀ ọ́n, dá mi lóhùn! Àbí ta ló ta okùn ìwọ̀n sórí rẹ̀? Orí kí ni a gbé ìpìlẹ̀ rẹ̀ lé, àbí ta ló fi òkúta igun rẹ̀ sọlẹ̀; tí àwọn ìràwọ̀ òwúrọ̀ ń jùmọ̀ kọrin, tí gbogbo àwọn ọmọ Ọlọrun sì búsáyọ̀?
Job 38:1-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà náà ní OLúWA dá Jobu lóhùn láti inú ìjì àjàyíká wá, ó sì wí pé: “Ta ni èyí tí ń fi ọ̀rọ̀ àìlóye láti fi ṣókùnkùn bo ìmọ̀ mi? Di ẹ̀gbẹ́ ara rẹ ní àmùrè bí ọkùnrin nísinsin yìí, nítorí pé èmi yóò béèrè lọ́wọ́ rẹ kí o sì dá mi lóhùn. “Níbo ni ìwọ wà nígbà tí mo fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀? Wí bí ìwọ bá mòye. Ta ni ó fi ìwọ̀n rẹ lélẹ̀, dájú bí ìwọ bá mọ̀ ọ́n? Tàbí ta ni ó ta okùn wíwọ̀n sórí rẹ? Lórí ibo ni a gbé kan ìpìlẹ̀ rẹ̀ mọ́, tàbí ta ni ó fi òkúta igun rẹ̀ lélẹ̀, Nígbà náà àwọn ìràwọ̀ òwúrọ̀ jùmọ̀ kọrin pọ̀, tí gbogbo àwọn ọmọ Ọlọ́run hó ìhó ayọ̀?