Nígbà náà ní OLúWA dá Jobu lóhùn láti inú ìjì àjàyíká wá, ó sì wí pé: “Ta ni èyí tí ń fi ọ̀rọ̀ àìlóye láti fi ṣókùnkùn bo ìmọ̀ mi? Di ẹ̀gbẹ́ ara rẹ ní àmùrè bí ọkùnrin nísinsin yìí, nítorí pé èmi yóò béèrè lọ́wọ́ rẹ kí o sì dá mi lóhùn. “Níbo ni ìwọ wà nígbà tí mo fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀? Wí bí ìwọ bá mòye. Ta ni ó fi ìwọ̀n rẹ lélẹ̀, dájú bí ìwọ bá mọ̀ ọ́n? Tàbí ta ni ó ta okùn wíwọ̀n sórí rẹ? Lórí ibo ni a gbé kan ìpìlẹ̀ rẹ̀ mọ́, tàbí ta ni ó fi òkúta igun rẹ̀ lélẹ̀, Nígbà náà àwọn ìràwọ̀ òwúrọ̀ jùmọ̀ kọrin pọ̀, tí gbogbo àwọn ọmọ Ọlọ́run hó ìhó ayọ̀?
Kà Jobu 38
Feti si Jobu 38
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Jobu 38:1-7
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò