Job 33:13-29

Job 33:13-29 Bibeli Mimọ (YBCV)

Nitori kini iwọ ṣe mba a jà pe: on kì isọrọ̀kọrọ kan nitori iṣẹ rẹ̀? Nitoripe Ọlọrun sọ̀rọ lẹkan, ani lẹkeji ṣugbọn enia kò roye rẹ̀. Ninu àla, li ojuran oru, nigbati orun ìjika ba kùn enia lọ, ni isunyẹ lori bùsun. Nigbana ni iṣi eti enia, a si fi èdidi di ẹkọ wọn. Ki o lè ifa enia sẹhin kuro ninu ete rẹ̀, ki o si pa igberaga mọ́ kuro lọdọ enia. O si fa ọkàn rẹ̀ pada kuro ninu iho, ati ẹmi rẹ̀ lati ṣègbe lọwọ idà. A si fi irora nà a lori ibùsun rẹ̀, pẹlupẹlu a fi ijà egungun rẹ̀ ti o duro pẹ́, nà a. Bẹ̃li ẹmi rẹ̀ kọ̀ onjẹ, ati ọkàn rẹ̀ kọ̀ onjẹ didùn. Ẹran ara rẹ̀ rùn, titi a kò si fi lè ri i mọ́; egungun rẹ̀ ti a kò ri, si ta jade. Ani ọkàn rẹ̀ sunmọ isa-okú, ati ẹmi rẹ̀ sunmọ ọdọ awọn iranṣẹ ikú. Bi onṣẹ kan ba wà lọdọ rẹ̀, ẹniti nṣe alagbawi, ọkan ninu ẹgbẹrun lati fi ọ̀na pipé han ni: Nigbana ni o ṣore-ọfẹ fun u, o si wipe, Gbà a kuro ninu ilọ sinu ihò, emi ti ri irapada! Ara rẹ̀ yio si já yọ̀yọ̀ jù ti ọmọ kekere, yio si tún pada si ọjọ igba ewe rẹ̀. O gbadura sọdọ Ọlọrun, on o si ṣe oju rere si i, o si mu enia ri oju rẹ̀ pẹlu ayọ̀, on o san ododo rẹ̀ pada fun enia. O bojuwo enia, bi ẹnikan ba si wipe, Emi ṣẹ̀, mo si ti yi eyi ti o tọ́ po, a kò si sẹsan rẹ̀ fun mi; O ti gba ọkàn mi kuro ninu ilọ sinu ihò, ẹmi mi yio si ri imọlẹ! Wò o! nkan wọnyi li Ọlọrun imaṣe fun enia nigba meji, ati nigba mẹta

Job 33:13-29 Yoruba Bible (YCE)

Kí ló dé tí ò ń fi ẹ̀sùn kàn án pé kò ní fèsì kankan sí ọ̀rọ̀ rẹ? Nítorí Ọlọrun sọ̀rọ̀ bákan, ó tún tún un sọ bámìíràn, ṣugbọn kò sí ẹni tí ó yé. Ninu àlá, lójú ìran ní ààrin òru, nígbà tí eniyan bá sun oorun àsùnwọra, lórí ibùsùn wọn, Ọlọrun a máa ṣí wọn létí, a máa kìlọ̀ fún wọn, a sì máa dẹ́rùbà wọ́n, kí ó lè dá wọn lẹ́kun ìṣe wọn, kí ó lè gba ìgbéraga lọ́wọ́ wọn; kí ó lè yọ ọkàn eniyan kúrò ninu ọ̀fìn ìparun, kí ó má baà kú ikú idà. “OLUWA a máa fi ìrora jẹ eniyan níyà lórí ibùsùn rẹ̀; a sì máa kó ìnira bá egungun rẹ̀. Tóbẹ́ẹ̀ tí ẹnu rẹ̀ yóo kọ oúnjẹ, oúnjẹ àdídùn óo sì rùn sí i. Eniyan á rù hangangan, wọn a sì fẹ́rẹ̀ lè máa ka egungun rẹ̀. Ọkàn rẹ̀ á súnmọ́ ibojì, ẹ̀mí rẹ̀ a sì súnmọ́ àwọn iranṣẹ ikú. Bí angẹli kan bá wà pẹlu rẹ̀, tí ó wà fún un bí onídùúró, àní, ọ̀kan láàrin ẹgbẹrun, tí yóo sọ ohun tí ó tọ́ fún un, tí yóo ṣàánú rẹ̀, tí yóo sì wí pé, ‘Ẹ gbà á sílẹ̀, ẹ má jẹ́ kí ó lọ sinu ibojì, mo ti rí ìràpadà kan dípò rẹ̀.’ Jẹ́ kí àwọ̀ rẹ̀ jọ̀lọ̀ bí ara ọmọde, kí agbára rẹ̀ sì pada dàbí ti ìgbà ọ̀dọ́; nígbà náà eniyan óo gbadura sí Ọlọrun, Ọlọrun óo sì gbọ́ adura rẹ̀. Eniyan óo wá fi ayọ̀ wá siwaju Ọlọrun, yóo sì ròyìn ìgbàlà Ọlọrun fún gbogbo aráyé Yóo wá sọ gbangba níwájú àwọn eniyan pé, ‘Mo ti ṣẹ̀, mo sì ti yí ẹ̀tọ́ po, ṣugbọn Ọlọrun kò jẹ mí níyà ẹ̀ṣẹ̀ mi. Ó ti ra ọkàn mi pada kúrò lọ́wọ́ isà òkú, mo sì wà láàyè.’ “Wò ó, Ọlọrun a máa ṣe nǹkan wọnyi léraléra fún eniyan, lẹẹmeji tabi lẹẹmẹta

Job 33:13-29 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Nítorí kí ni ìwọ ṣe ń bá a jà, wí pé, òun kò ní sọ ọ̀rọ̀ kan nítorí iṣẹ́ rẹ̀? Nítorí pe Ọlọ́run sọ̀rọ̀ lẹ́ẹ̀kan, àní, lẹ́ẹ̀kejì, ṣùgbọ́n ènìyàn kò róye rẹ̀. Nínú àlá, ní ojúran òru, nígbà tí orun èjìká bá kùn ènìyàn lọ, ní sísùn lórí ibùsùn, Nígbà náà ni ó lè sọ̀rọ̀ ní etí wọn, yóò sì dẹ́rùbà wọ́n pẹ̀lú ìbáwí, Kí ó lè fa ènìyàn sẹ́yìn kúrò nínú ètè rẹ̀; Kí ó sì pa ìgbéraga mọ́ kúrò lọ́dọ̀ ènìyàn; Ó sì fa ọkàn rẹ̀ padà kúrò nínú isà òkú, àti ẹ̀mí rẹ̀ láti ṣègbé lọ́wọ́ idà. “A sì nà án lórí ibùsùn ìrora rẹ̀; pẹ̀lúpẹ̀lú a fi ìjà egungun rẹ̀ ti ó dúró pẹ́ nà án, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀mí rẹ kọ oúnjẹ, ọkàn rẹ̀ sì kọ oúnjẹ dídùn. Ẹran-ara rẹ̀ run, títí a kò sì fi lè rí i mọ́ egungun rẹ̀ tí a kò tí rí sì ta jáde. Àní, ọkàn rẹ̀ sì súnmọ́ isà òkú, ẹ̀mí rẹ̀ sì súnmọ́ ọ̀dọ̀ àwọn ìránṣẹ́ ikú. Bí angẹli kan ba wà lọ́dọ̀ rẹ̀, ẹni tí ń ṣe alágbàwí, ọ̀kan nínú ẹgbẹ̀rún láti fi ọ̀nà pípé hàn ni, Nígbà náà ni ó ṣe oore-ọ̀fẹ́ fún un ó sì wí pé, gbà á kúrò nínú lílọ sínú isà òkú; èmi ti rà á padà. Ara rẹ̀ yóò sì di ọ̀tun bí i ti ọmọ kékeré, yóò sì tún padà sí ọjọ́ ìgbà èwe rẹ̀; Ó gbàdúrà sọ́dọ̀ Ọlọ́run, òun sì ṣe ojúrere rẹ̀, o sì rí ojú rẹ̀ pẹ̀lú ayọ̀, òhun o san òdodo rẹ̀ padà fún ènìyàn. Ó wá sọ́dọ̀ ènìyàn ó sì wí pé, ‘Èmi ṣẹ̀, kò sì ṣí èyí tí o tọ́, mo sì ti yí èyí tí ó tọ́ po, a kò sì san ẹ̀san rẹ̀ fún mi; Ọlọ́run ti gba ọkàn mi kúrò nínú lílọ sínú ihò, ẹ̀mí mi yóò wà láti jẹ adùn ìmọ́lẹ̀ ayé.’ “Wò ó! Nǹkan wọ̀nyí ni Ọlọ́run máa ń ṣe fún ènìyàn nígbà méjì àti nígbà mẹ́ta