Job 26:7-14
Job 26:7-14 Bibeli Mimọ (YBCV)
On ni o nà ìha ariwa ọrun ni ibi ofurufu, o si fi aiye rọ̀ li oju ofo. O di omiyomi pọ̀ ninu awọsanma rẹ̀ ti o nipọn; awọsanma kò si ya nisalẹ wọn. O si fa oju itẹ rẹ̀ sẹhin, o si tẹ awọ sanma rẹ̀ si i lori. O fi ìde yi omi-okun ka, titi de ala imọlẹ ati òkunkun. Ọwọn òpo ọrun wáriri, ẹnu si yà wọn si ibawi rẹ̀. O fi ipa rẹ̀ damu omi-okun, nipa oye rẹ̀ o lu agberaga jalẹjalẹ. Nipa ẹmi rẹ li o ti ṣe ọrun li ọ̀ṣọ, ọwọ rẹ̀ li o ti da ejo-wiwọ́ nì. Kiyesi i, eyi ni opin ọ̀na rẹ̀, ohùn eyiti a gbọ́ ti kere tó! ṣugbọn ãra ipá rẹ̀ tali oye rẹ̀ le iye?
Job 26:7-14 Yoruba Bible (YCE)
Ó na ìhà àríwá sórí òfuurufú, ó sì so ayé rọ̀ sí òfuurufú. Ó di omi papọ̀ ninu ìkùukùu rẹ̀ tí ó nípọn, sibẹ ìkùukùu kò fà ya. Ó dí ojú òṣùpá, ó sì fi ìkùukùu bò ó. Ó ṣe òbìrìkítí kan sórí omi, ó fi ṣe ààlà láàrin òkùnkùn ati ìmọ́lẹ̀. Àwọn òpó ọ̀run mì tìtì, wọ́n sì wárìrì nítorí ìbáwí rẹ̀. Nípa agbára rẹ̀, ó mú kí òkun parọ́rọ́, nípa ìmọ̀ rẹ̀, ó pa Rahabu. Ó fi afẹ́fẹ́ ṣe ojú ọ̀run lọ́ṣọ̀ọ́; ọwọ́ ló fi pa ejò tí ń fò. Ṣugbọn kékeré nìyí ninu agbára rẹ̀, díẹ̀ ni a tíì gbọ́ nípa iṣẹ́ rẹ̀! Nítorí náà ta ló lè mọ títóbi agbára rẹ̀?”
Job 26:7-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Òun ní o nà ìhà àríwá ọ̀run ní ibi òfúrufú, ó sì so ayé rọ̀ ní ojú asán. Ó di omi pọ̀ nínú ìkùùkuu àwọsánmọ̀ rẹ̀ tí ó nípọn; àwọsánmọ̀ kò sì ya nísàlẹ̀ wọn. Ó sì fa ojú ìtẹ́ rẹ̀ sẹ́yìn, ó sì tẹ àwọsánmọ̀ rẹ̀ sí i lórí. Ó fi ìdè yí omi Òkun ká, títí dé ààlà ìmọ́lẹ̀ àti òkùnkùn. Ọ̀wọ́n òpó ọ̀run wárìrì, ẹnu sì yà wọ́n sì ìbáwí rẹ̀. Ó fi ipá rẹ̀ dààmú omi Òkun; nípa òye rẹ̀, ó gé agbéraga sí wẹ́wẹ́. Nípa ẹ̀mí rẹ̀ ni ó ti ṣe ọ̀run ní ọ̀ṣọ́; ọwọ́ rẹ̀ ni ó fi dá ejò wíwọ́ nì. Kíyèsi i, èyí ní òpin ọ̀nà rẹ̀; ohùn èyí tí a gbọ́ ti kéré tó! Ta ni ẹni náà tí òye àrá agbára rẹ̀ lè yé?”