JOBU 26

26
1Jobu bá dáhùn pé,
2“Ìrànlọ́wọ́ wo ni ẹ ti ṣe fún àwọn tí wọn kò lágbára?
Aláìlera wo ni ẹ ti gbàlà?
3Ìmọ̀ràn wo ni ẹ ti fún àwọn aláìgbọ́n?
Irú òye wo ni ẹ fihàn wọ́n?
4Ta ló ń kọ yín ni ohun tí ẹ̀ ń sọ wọnyi?
Irú ẹ̀mí wo sì ní ń gba ẹnu yín sọ̀rọ̀?
5“Àwọn òkú wárìrì nísàlẹ̀.
Omi ati àwọn olùgbé inú rẹ̀ pẹlu ń gbọ̀n rìrì.
6Kedere ni isà òkú rí níwájú Ọlọrun,
bẹ́ẹ̀ ni ìparun kò farasin.
7Ó na ìhà àríwá sórí òfuurufú,
ó sì so ayé rọ̀ sí òfuurufú.
8Ó di omi papọ̀ ninu ìkùukùu rẹ̀ tí ó nípọn,
sibẹ ìkùukùu kò fà ya.
9Ó dí ojú òṣùpá,
ó sì fi ìkùukùu bò ó.
10Ó ṣe òbìrìkítí kan sórí omi,
ó fi ṣe ààlà láàrin òkùnkùn ati ìmọ́lẹ̀.
11Àwọn òpó ọ̀run mì tìtì,
wọ́n sì wárìrì nítorí ìbáwí rẹ̀.
12Nípa agbára rẹ̀, ó mú kí òkun parọ́rọ́,
nípa ìmọ̀ rẹ̀, ó pa Rahabu.
13Ó fi afẹ́fẹ́ ṣe ojú ọ̀run lọ́ṣọ̀ọ́;
ọwọ́ ló fi pa ejò tí ń fò.
14Ṣugbọn kékeré nìyí ninu agbára rẹ̀,
díẹ̀ ni a tíì gbọ́ nípa iṣẹ́ rẹ̀!
Nítorí náà ta ló lè mọ títóbi agbára rẹ̀?”

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

JOBU 26: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀