Job 22:1-11
Job 22:1-11 Bibeli Mimọ (YBCV)
NIGBANA ni Elifasi, ara Tema, dahùn wipe, Enia le iṣe rere fun Ọlọrun, bi ọlọgbọ́n ti iṣe rere fun ara rẹ̀. Ohun ayọ̀ ha ni fun Olodumare pe, olododo ni iwọ? tabi ere ni fun u, ti iwọ mu ọ̀na rẹ pé? Yio ha ba ọ wi bi nitori ìbẹru Ọlọrun rẹ, yio ha ba ọ lọ sinu idajọ bi? Iwa-buburu rẹ kò ha tobi, ati ẹ̀ṣẹ rẹ lainiye? Nitõtọ iwọ gbà ohun ẹri li ọwọ arakunrin rẹ lainidi, iwọ si tú onihoho li aṣọ wọn. Iwọ kò fi omi fun alãrẹ mu, iwọ si hawọ onjẹ fun ẹniti ebi npa. Bi o ṣe ti alagbara nì ni, on li o ni aiye, ọlọla si tẹdo sinu rẹ̀. Iwọ ti rán awọn opó pada lọ li ọwọ ofo, apa awọn ọmọ alainibaba ti di ṣiṣẹ́. Nitorina ni idẹkun ṣe yi ọ kakiri, ati ìbẹru ojiji nyọ ọ lẹnu. Tabi iwọ kò ha ri okunkun, ati ọ̀pọlọpọ omi ti o bò ọ mọlẹ?
Job 22:1-11 Yoruba Bible (YCE)
Elifasi ará Temani bá dáhùn pé, “Ǹjẹ́ eniyan lè wúlò fún Ọlọrun? Nítòótọ́, bí eniyan tilẹ̀ jẹ́ ọlọ́gbọ́n, ara rẹ̀ ni ó wúlò fún. Ǹjẹ́ jíjẹ́ olódodo rẹ̀ ṣe ohun rere kan fún Olodumare, tabi kí ni èrè rẹ̀ bí ó bá jẹ́ ẹni pípé? Ṣé nítorí pé o bẹ̀rù rẹ̀ ni ó ṣe bá ọ wí, tí ó sì ń dá ọ lẹ́jọ́? Ṣebí ìwà ibi rẹ ló pọ̀; tí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ kò sì lópin? O gba nǹkan ìdógò lọ́wọ́ àwọn arakunrin rẹ láìnídìí, O bọ́ wọn sí ìhòòhò goloto. O kò fún aláàárẹ̀ ní omi mu, o kọ̀ láti fún ẹni tí ebi ń pa ní oúnjẹ. Ẹni tí ó lágbára gba ilẹ̀, ẹni tí ó lọ́lá sì ń gbé inú rẹ̀. O lé àwọn opó jáde lọ́wọ́ òfo, o sì ṣẹ́ aláìní baba lápá. Nítorí náà ni okùn dídẹ fi yí ọ ká, tí jìnnìjìnnì sì bò ọ́ lójijì. Ìmọ́lẹ̀ rẹ ti di òkùnkùn, o kò ríran, ìgbì omi sì bò ọ́ mọ́lẹ̀.
Job 22:1-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ìgbà náà ni Elifasi, ará Temani, dáhùn wí pé: “Ènìyàn lè è ṣe rere fún Ọlọ́run? Bí ọlọ́gbọ́n ti í ṣe rere fún ara rẹ̀? Ohun ayọ̀ ha ni fún Olódùmarè pé olódodo ni ìwọ? Tàbí èrè kí ni fún un ti ìwọ mú ọ̀nà rẹ̀ pé? “Yóò ha bá ọ wí bí, nítorí ìbẹ̀rù Ọlọ́run rẹ? Yóò ha bá ọ lọ sínú ìdájọ́ bí? Ìwà búburú rẹ kò ha tóbi, àti ẹ̀ṣẹ̀ rẹ láìníye? Nítòótọ́ ìwọ béèrè fún ààbò ni ọwọ́ arákùnrin rẹ láìnídìí, ìwọ sì tú oníhòhò ní aṣọ wọn. Ìwọ kò fi omi fún aláàárẹ̀ mu, ìwọ sì háwọ́ oúnjẹ fún ẹni tí ebi ń pa. Bí ó ṣe ti alágbára nì, òun ni ó ní ilẹ̀, ọlọ́lá sì tẹ̀dó sínú rẹ̀. Ìwọ ti rán àwọn opó padà lọ ní ọwọ́ òfo; Apá àwọn ọmọ aláìní baba ti di ṣiṣẹ́. Nítorí náà ni ìdẹ̀kùn ṣe yí ọ káàkiri, àti ìbẹ̀rù òjijì ń yọ ọ́ lẹ́nu, Èéṣe tí òkùnkùn fi pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ tí ìwọ kò fi lè ríran; Èéṣe tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ omi sì bò ọ́ mọ́lẹ̀.