Job 22

22
ÌFỌ̀RỌ̀WÉRỌ̀ KẸTA
(Job 22:1—27:23)
1NIGBANA ni Elifasi, ara Tema, dahùn wipe,
2Enia le iṣe rere fun Ọlọrun, bi ọlọgbọ́n ti iṣe rere fun ara rẹ̀.
3Ohun ayọ̀ ha ni fun Olodumare pe, olododo ni iwọ? tabi ere ni fun u, ti iwọ mu ọ̀na rẹ pé?
4Yio ha ba ọ wi bi nitori ìbẹru Ọlọrun rẹ, yio ha ba ọ lọ sinu idajọ bi?
5Iwa-buburu rẹ kò ha tobi, ati ẹ̀ṣẹ rẹ lainiye?
6Nitõtọ iwọ gbà ohun ẹri li ọwọ arakunrin rẹ lainidi, iwọ si tú onihoho li aṣọ wọn.
7Iwọ kò fi omi fun alãrẹ mu, iwọ si hawọ onjẹ fun ẹniti ebi npa.
8Bi o ṣe ti alagbara nì ni, on li o ni aiye, ọlọla si tẹdo sinu rẹ̀.
9Iwọ ti rán awọn opó pada lọ li ọwọ ofo, apa awọn ọmọ alainibaba ti di ṣiṣẹ́.
10Nitorina ni idẹkun ṣe yi ọ kakiri, ati ìbẹru ojiji nyọ ọ lẹnu.
11Tabi iwọ kò ha ri okunkun, ati ọ̀pọlọpọ omi ti o bò ọ mọlẹ?
12Ọlọrun kò ha jẹ Ẹni giga ọrun? sa wò ori awọn ìrawọ̀ bi nwọn ti ga tó!
13Iwọ si wipe, Ọlọrun ti ṣe mọ̀, on ha le iṣe idajọ lati inu awọsanma dudu wá bi?
14Awọsanma ti o nipọn ni ibora fun u, ti kò fi le riran; o si rin ninu ayika ọrun.
15Iwọ fẹ rìn ipa-ọ̀na igbani ti awọn enia buburu ti rìn.
16Ti a ke lulẹ kuro ninu aiye laipé ọjọ wọn, ipilẹ wọn ti de bi odò ṣiṣàn.
17Awọn ẹniti o wi fun Ọlọrun pe, Lọ kuro lọdọ wa! Kini Olodumare yio ṣe fun wọn.
18Sibẹ o fi ohun rere kún ile wọn! ṣugbọn ìmọ enia-buburu jìna si mi!
19Awọn olododo ri i, nwọn si yọ̀, awọn alailẹ̀ṣẹ si fi wọn rẹrin ẹlẹya pe:
20Lotitọ awọn ọta wa ni a ke kuro, iná yio si jó iyokù wọn run.
21Fa ara rẹ sunmọ Ọlọrun, iwọ o si ri alafia; nipa eyinì rere yio wá ba ọ.
22Emi bẹ̀ ọ, gba ofin lati ẹnu rẹ̀ wá, ki o si tò ọ̀rọ rẹ̀ si aiya rẹ.
23Bi iwọ ba yipada sọdọ Olodumare, a si gbe ọ ró, bi iwọ ba si mu ẹ̀ṣẹ jina rére kuro ninu agọ rẹ.
24Ti iwọ ba tẹ wura daradara silẹ lori erupẹ ati wura ófiri labẹ okuta odò.
25Nigbana ni Olodumare yio jẹ iṣura rẹ, ani yio si jẹ fadaka fun ọ ni ọ̀pọlọpọ.
26Lotitọ nigbana ni iwọ o ni inu didùn ninu Olodumare, iwọ o si gbe oju rẹ soke sọdọ Ọlọrun.
27Bi iwọ ba gbadura rẹ sọdọ rẹ̀, yio si gbọ́ tirẹ, iwọ o si san ẹ̀jẹ́ rẹ.
28Iwọ si gbimọ ohun kan pẹlu, yio si fi idi mulẹ fun ọ; imọlẹ yio si mọ́ sipa ọ̀na rẹ.
29Nigbati ipa-ọ̀na rẹ ba lọ sisalẹ, nigbana ni iwọ o wipe, Igbesoke mbẹ! Ọlọrun yio si gba onirẹlẹ là!
30Yio gba ẹniti kì iṣe alaijẹbi là, a o si gbà a nipa mimọ́ ọwọ rẹ.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Job 22: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀