Job 16:18-22
Job 16:18-22 Bibeli Mimọ (YBCV)
A! ilẹ aiye, iwọ máṣe bò ẹ̀jẹ mi, ki ẹkún mi máṣe ni ipò kan. Njẹ nisisiyi kiyesi i! ẹlẹri mi mbẹ li ọrun, ẹri mi si mbẹ loke ọrun. Awọn ọre mi nfi mi ṣẹ̀sin, ṣugbọn oju mi ndà omije sọdọ Ọlọrun. Ibaṣepe ẹnikan le ma ṣe alagbawi fun ẹnikeji lọdọ Ọlọrun, bi enia kan ti iṣe alagbawi fun ẹnikeji rẹ̀. Nitori nigbati iye ọdun diẹ rekọja tan, nigbana ni emi o lọ si ibi ti emi kì yio pada bọ̀.
Job 16:18-22 Yoruba Bible (YCE)
“Ìwọ ilẹ̀, má ṣe bo ẹ̀jẹ̀ mi mọ́lẹ̀, má sì jẹ́ kí igbe mi já sí òfo. Nisinsinyii, ẹlẹ́rìí mi ń bẹ lọ́run, alágbàwí mi sì ń bẹ lókè. Àwọn ọ̀rẹ́ mi ń fi mí ṣe ẹlẹ́yà, mo sì ń sọkún sí Ọlọrun, ìbá ṣe pé ẹnìkan lè ṣe alágbàwí fún ẹnìkejì lọ́dọ̀ Ọlọrun, bí eniyan ti lè ṣe alágbàwí fún ẹnìkejì rẹ̀ níwájú eniyan. Lẹ́yìn ọdún díẹ̀ sí i, n óo lọ àjò àrèmabọ̀.
Job 16:18-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Háà! Ilẹ̀ ayé, ìwọ má ṣe bò ẹ̀jẹ̀ mi, kí ẹkún mi má ṣe wà ní ipò kan. Ǹjẹ́ nísinsin yìí kíyèsi i, ẹlẹ́rìí mi ń bẹ ní ọ̀run, ẹ̀rí mi sì ń bẹ lókè ọ̀run. Àwọn ọ̀rẹ́ mi ń fi mí ṣẹ̀sín, ṣùgbọ́n ojú mi ń da omijé sọ́dọ̀ Ọlọ́run; Ìbá ṣe pé ẹnìkan le è máa ṣe alágbàwí fún ẹnìkejì lọ́dọ̀ Ọlọ́run, bí ènìyàn kan ti í ṣe alágbàwí fún ẹnìkejì rẹ̀. “Nítorí nígbà tí iye ọdún díẹ̀ rékọjá tán, nígbà náà ni èmi ó lọ sí ibi tí èmi kì yóò padà bọ̀.