Jobu 16:18-22

Jobu 16:18-22 YCB

“Háà! Ilẹ̀ ayé, ìwọ má ṣe bò ẹ̀jẹ̀ mi, kí ẹkún mi má ṣe wà ní ipò kan. Ǹjẹ́ nísinsin yìí kíyèsi i, ẹlẹ́rìí mi ń bẹ ní ọ̀run, ẹ̀rí mi sì ń bẹ lókè ọ̀run. Àwọn ọ̀rẹ́ mi ń fi mí ṣẹ̀sín, ṣùgbọ́n ojú mi ń da omijé sọ́dọ̀ Ọlọ́run; Ìbá ṣe pé ẹnìkan le è máa ṣe alágbàwí fún ẹnìkejì lọ́dọ̀ Ọlọ́run, bí ènìyàn kan ti í ṣe alágbàwí fún ẹnìkejì rẹ̀. “Nítorí nígbà tí iye ọdún díẹ̀ rékọjá tán, nígbà náà ni èmi ó lọ sí ibi tí èmi kì yóò padà bọ̀.