Job 13:20-28
Job 13:20-28 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ṣugbọn ọkan ni, máṣe ṣe ohun meji yi si mi, nigbana ni emi kì yio si fi ara mi pamọ, kuro fun ọ, Fa ọwọ rẹ sẹhin kuro lara mi; má si jẹ ki ẹ̀ru rẹ ki o pá mi laiya. Nigbana ni ki iwọ ki o pè, emi o si dahùn, tabi jẹ ki nma sọ̀rọ, ki iwọ ki o si da mi lohùn. Melo li aiṣedede ati ẹ̀ṣẹ mi, mu mi mọ̀ irekọja ati ẹ̀ṣẹ mi! Nitori kini iwọ ṣe pa oju rẹ mọ́, ti o si yàn mi li ọta rẹ? Iwọ o fa ewe ya ti afẹfẹ nfẹ sihin sọhun: iwọ a si ma lepa akemọlẹ poroporo gbigbẹ! Nitoripe iwọ kọwe ohun kikoro si mi, o si mu mi ni aiṣedede ewe mi. Iwọ kàn àba mọ mi lẹsẹ pẹlu, iwọ si nwò ipa ọ̀na irin mi li awofin, iwọ si nfi ãlà yi gigisẹ mi ka. Ani, yi ẹniti a ti run ka, bi ohun ti o bu, bi aṣọ ti kòkoro jẹ bajẹ.
Job 13:20-28 Yoruba Bible (YCE)
Nǹkan meji péré ni mo fẹ́ kí o ṣe fún mi, n kò sì ní farapamọ́ fún ọ: ká ọwọ́ ibinu rẹ kúrò lára mi, má sì ṣe jẹ́ kí jìnnìjìnnì rẹ dà bò mí. Lẹ́yìn náà, sọ̀rọ̀, n óo sì fèsì; tabi kí o jẹ́ kí èmi sọ̀rọ̀, kí o sì fún mi lésì. Báwo ni àìdára ati ẹ̀ṣẹ̀ mi ti pọ̀ tó? Jẹ́ kí n mọ ẹ̀ṣẹ̀ mi, ati ibi tí mo ti kọjá ààyè mi. Kí ló dé tí o fi fi ara pamọ́ fún mi tí o kà mí kún ọ̀tá rẹ? Ṣé o óo máa dẹ́rùba ewé lásán tí afẹ́fẹ́ ń fẹ́ kiri, tabi o óo máa lépa ìyàngbò gbígbẹ? O ti kọ àkọsílẹ̀ burúkú nípa mi, o mú mi jìyà ẹ̀ṣẹ̀ ìgbà èwe mi. O kó ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ sí mi lẹ́sẹ̀, ò ń ṣọ́ ìrìn ẹsẹ̀ mi, o sì pa ààlà tí n kò gbọdọ̀ rékọjá. Eniyan ń ṣègbé lọ bí ohun tí ó ń jẹrà, bí aṣọ tí ikán ti mu.
Job 13:20-28 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Ṣùgbọ́n, má ṣe ṣe ohun méjì yìí sí mi, Nígbà náà ni èmi kì yóò sì fi ara mi pamọ́ kúrò fún ọ: Fa ọwọ́ rẹ sẹ́yìn kúrò lára mi, má sì jẹ́ kí ẹ̀rù rẹ kí ó pá mi láyà. Nígbà náà ni kí ìwọ kí ó pè, èmi o sì dáhùn; Ta ni jẹ́ kí ń máa sọ̀rọ̀, ki ìwọ kí ó sì dá mi lóhùn. Mélòó ní àìṣedéédéé àti ẹ̀ṣẹ̀ mi? Mú mi mọ̀ ìrékọjá àti ẹ̀ṣẹ̀ mi. Nítorí kí ni ìwọ ṣe pa ojú rẹ mọ́, tí o sì yàn mí ní ọ̀tá rẹ? Ìwọ ó fa ewé ti afẹ́fẹ́ ń fẹ́ síhìn-ín sọ́hùn-ún ya bi? Ìwọ a sì máa lépa ìyàngbò? Nítorí pé ìwọ kọ̀wé ohun kíkorò sí mi, o sì mú mi jogún àìṣedéédéé èwe mi. Ìwọ kàn àbà mọ́ mi lẹ́sẹ̀ pẹ̀lú, ìwọ sì ń wò ipa ọ̀nà ìrìn mi ní àwòfín; nípa fífi ìlà yí gígísẹ̀ mi ká. “Bẹ́ẹ̀ ni ènìyàn ń ṣègbé bí ohun ìdíbàjẹ́, Bi aṣọ tí kòkòrò jẹ.