JOBU 13

13
1“Gbogbo ìwọ̀nyí ni ojú mi ti rí rí,
tí etí mi ti gbọ́, tí ó sì yé mi.
2Ohun tí ẹ mọ̀ wọnyi, èmi náà mọ̀ ọ́n,
ẹ kò sàn jù mí lọ.
3Ṣugbọn n óo bá Olodumare sọ̀rọ̀,
Ọlọrun ni mo sì fẹ́ bá rojọ́.
4Ẹ̀yin òpùrọ́ ati ẹlẹ́tàn wọnyi,
ẹ̀yin oníṣègùn tí ẹ kò lè wonisàn.
5Ẹ̀ bá jẹ́ pa ẹnu yín mọ́ ni,
à bá pè yín ní ọlọ́gbọ́n!
6Nisinsinyii ẹ gbọ́ èrò ọkàn mi,
kí ẹ sì fetísí àròyé mi.
7Ṣé ẹ óo máa parọ́ ní orúkọ Ọlọrun ni,
kí ẹ sì máa sọ̀rọ̀ ẹ̀tàn ní orúkọ rẹ̀?
8Ṣé ẹ fẹ́ máa ṣe ojuṣaaju fún Ọlọrun ni?
Tabi ẹ fẹ́ jẹ́ agbẹjọ́rò rẹ̀?
9Ṣé ẹ óo yege bí ó bá dán yín wò?
Tabi ẹ lè tan Ọlọrun bí ẹni tan eniyan?
10Dájúdájú, yóo ba yín wí,
bí ẹ bá ń ṣe ojuṣaaju níkọ̀kọ̀.
11Ògo rẹ̀ yóo dẹ́rùbà yín,
jìnnìjìnnì rẹ̀ yóo dà bò yín.
12Àwọn òwe yín kò wúlò,
àwíjàre yín kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀.
13Ẹ dákẹ́, kí n ráyè sọ tèmi,
kí ohun tí yóo bá dé bá mi dé bá mi.
14N óo dijú, n óo fi ẹ̀mí ara mi wéwu.
15Wò ó, yóo pa mí; n kò ní ìrètí;
sibẹ n óo wí àwíjàre tèmi níwájú rẹ̀.
16Èyí ni yóo jẹ́ ìgbàlà mi,
nítorí pé ẹni tí kò mọ Ọlọrun,
kò ní lè dúró níwájú rẹ̀.
17Fetí sílẹ̀ dáradára sí ọ̀rọ̀ mi,
kí o sì gbọ́ mi ní àgbọ́yé.
18Wò ó, mo ti múra ẹjọ́ mi sílẹ̀;
mo sì mọ̀ pé n óo gba ìdáláre.
19Ta ni yóo wá bá mi rojọ́?
Bí ó bá wá, n óo dákẹ́, n óo sì kú.
20Nǹkan meji péré ni mo fẹ́ kí o ṣe fún mi,
n kò sì ní farapamọ́ fún ọ:
21ká ọwọ́ ibinu rẹ kúrò lára mi,
má sì ṣe jẹ́ kí jìnnìjìnnì rẹ dà bò mí.
22Lẹ́yìn náà, sọ̀rọ̀, n óo sì fèsì;
tabi kí o jẹ́ kí èmi sọ̀rọ̀, kí o sì fún mi lésì.
23Báwo ni àìdára ati ẹ̀ṣẹ̀ mi ti pọ̀ tó?
Jẹ́ kí n mọ ẹ̀ṣẹ̀ mi, ati ibi tí mo ti kọjá ààyè mi.
24Kí ló dé tí o fi fi ara pamọ́ fún mi
tí o kà mí kún ọ̀tá rẹ?
25Ṣé o óo máa dẹ́rùba ewé lásán tí afẹ́fẹ́ ń fẹ́ kiri,
tabi o óo máa lépa ìyàngbò gbígbẹ?
26O ti kọ àkọsílẹ̀ burúkú nípa mi,
o mú mi jìyà ẹ̀ṣẹ̀ ìgbà èwe mi.
27O kó ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ sí mi lẹ́sẹ̀,
ò ń ṣọ́ ìrìn ẹsẹ̀ mi,
o sì pa ààlà tí n kò gbọdọ̀ rékọjá.
28Eniyan ń ṣègbé lọ bí ohun tí ó ń jẹrà,
bí aṣọ tí ikán ti mu.#Job 33:11

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

JOBU 13: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀