Joh 9:6-11
Joh 9:6-11 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nigbati o ti wi bẹ̃ tan, o tutọ́ silẹ, o si fi itọ́ na ṣe amọ̀, o si fi amọ̀ na pa oju afọju na, O si wi fun u pe, Lọ, wẹ̀ ninu adagun Siloamu, (itumọ̀ eyi ti ijẹ Ránlọ.) Nitorina o gbà ọ̀na rẹ̀ lọ, o wẹ̀, o si de, o nriran. Njẹ awọn aladugbo ati awọn ti o ri i nigba atijọ pe alagbe ni iṣe, wipe, Ẹniti o ti njoko ṣagbe kọ́ yi? Awọn kan wipe, On ni: awọn ẹlomiran wipe, Bẹ̃kọ, o jọ ọ ni: ṣugbọn on wipe, Emi ni. Nitorina ni nwọn wi fun u pe, Njẹ oju rẹ ti ṣe là? O dahùn o si wi fun wọn pe, ọkunrin kan ti a npè ni Jesu li o ṣe amọ̀, o si fi kùn mi loju, o si wi fun mi pe, Lọ si adagun Siloamu, ki o si wẹ̀: emi si lọ, mo wẹ̀, mo si riran.
Joh 9:6-11 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí ó ti sọ báyìí tán, ó tutọ́ sílẹ̀, ó fi po amọ̀, ó bá fi lẹ ojú ọkunrin náà. Ó wí fún un pé, “Lọ bọ́jú ninu adágún tí ó ń jẹ́ Siloamu.” (Ìtumọ̀ Siloamu ni “rán níṣẹ́.”) Ọkunrin náà lọ, ó bọ́jú, ó bá ríran. Nígbà tí àwọn aládùúgbò rẹ̀ ati àwọn tí wọn máa ń rí i tẹ́lẹ̀ tí ó máa ń ṣagbe, rí i, wọ́n ń bi ara wọn pé, “Ǹjẹ́ ọkunrin yìí kọ́ ni ó ti máa ń jókòó, tí ó máa ń ṣagbe rí?” Àwọn kan ń sọ pé, “Òun ni!” Àwọn mìíràn ń sọ pé, “Rárá o, ó jọ ọ́ ni.” Ọkunrin náà ni, “Èmi gan-an ni.” Wọ́n bi í pé, “Báwo ni ojú rẹ́ ti ṣe là?” Ó dá wọn lóhùn pé, “Ọkunrin tí wọn ń pè ní Jesu ni ó po amọ̀, tí ó fi lẹ̀ mí lójú, tí ó sọ fún mi pé kí n lọ bọ́jú ní adágún Siloamu. Mo lọ, mo bọ́jú, mo sì ríran.”
Joh 9:6-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà tí ó ti wí bẹ́ẹ̀ tan, ó tutọ́ sílẹ̀, ó sì fi itọ́ náà ṣe amọ̀, ó sì fi amọ̀ náà ra ojú afọ́jú náà. Ó sì wí fún un pé, “Lọ wẹ̀ nínú adágún Siloamu!” (Ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ yìí ni “rán”). Nítorí náà ó gba ọ̀nà rẹ̀ lọ, ó wẹ̀, ó sì dé, ó ń ríran. Ǹjẹ́ àwọn aládùúgbò àti àwọn tí ó rí i nígbà àtijọ́ pé alágbe ni ó jẹ́, wí pé, “Ẹni tí ó ti ń jókòó ṣagbe kọ́ yìí?” Àwọn kan wí pé òun ni. Àwọn ẹlòmíràn wí pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́, ó jọ ọ́ ni.” Ṣùgbọ́n òun wí pé, “Èmi ni.” Nígbà náà ni wọ́n wí fún un pé, “Bá wo ni ojú rẹ ṣe là?” Ó dáhùn ó sì wí fún un pé, “Ọkùnrin kan tí a ń pè ní Jesu ni ó ṣe amọ̀, ó sì fi kun ojú mí, ó sì wí fún mi pé, ‘Lọ sí adágún Siloamu, kí o sì wẹ̀,’ èmi sì lọ, mo wẹ̀, mo sì ríran.”