Nígbà tí ó ti wí bẹ́ẹ̀ tan, ó tutọ́ sílẹ̀, ó sì fi itọ́ náà ṣe amọ̀, ó sì fi amọ̀ náà ra ojú afọ́jú náà. Ó sì wí fún un pé, “Lọ wẹ̀ nínú adágún Siloamu!” (Ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ yìí ni “rán”). Nítorí náà ó gba ọ̀nà rẹ̀ lọ, ó wẹ̀, ó sì dé, ó ń ríran. Ǹjẹ́ àwọn aládùúgbò àti àwọn tí ó rí i nígbà àtijọ́ pé alágbe ni ó jẹ́, wí pé, “Ẹni tí ó ti ń jókòó ṣagbe kọ́ yìí?” Àwọn kan wí pé òun ni. Àwọn ẹlòmíràn wí pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́, ó jọ ọ́ ni.” Ṣùgbọ́n òun wí pé, “Èmi ni.” Nígbà náà ni wọ́n wí fún un pé, “Bá wo ni ojú rẹ ṣe là?” Ó dáhùn ó sì wí fún un pé, “Ọkùnrin kan tí a ń pè ní Jesu ni ó ṣe amọ̀, ó sì fi kun ojú mí, ó sì wí fún mi pé, ‘Lọ sí adágún Siloamu, kí o sì wẹ̀,’ èmi sì lọ, mo wẹ̀, mo sì ríran.”
Kà Johanu 9
Feti si Johanu 9
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Johanu 9:6-11
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò