Joh 7:31-53
Joh 7:31-53 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ọ̀pọ̀ nínú ìjọ ènìyàn sì gbà á gbọ́, wọ́n sì wí pé, “Nígbà tí Kristi náà bá dé, yóò ha ṣe iṣẹ́ ààmì jù wọ̀nyí, tí ọkùnrin yìí ti ṣe lọ?” Àwọn Farisi gbọ́ pé, ìjọ ènìyàn ń sọ nǹkan wọ̀nyí lábẹ́lẹ̀ nípa rẹ̀; àwọn Farisi àti àwọn olórí àlùfáà sì rán àwọn oníṣẹ́ lọ láti mú un. Nítorí náà Jesu wí fún wọn pé, “Níwọ́n ìgbà díẹ̀ ni èmi yóò wà pẹ̀lú yín, èmi yóò lọ sí ọ̀dọ̀ ẹni tí ó rán mi. Ẹ̀yin yóò wá mi, ẹ̀yin kì yóò sì rí mi: àti ibi tí èmi bá wà, ẹ̀yin kì yóò le wà.” Nítorí náà ni àwọn Júù ń bá ara wọn sọ pé, “Níbo ni ọkùnrin yìí yóò gbé lọ tí àwa kì yóò fi rí i? Yóò ha lọ sí àárín àwọn Helleni tí wọ́n fọ́n káàkiri, kí ó sì máa kọ́ àwọn Helleni bí. Ọ̀rọ̀ kín ni èyí tí ó sọ yìí, ẹ̀yin yóò wá mi, ẹ kì yóò sì rí mi, àti ibi tí èmi bá wà ẹ̀yin kì yóò le wà?” Lọ́jọ́ tó kẹ́yìn, tí í ṣe ọjọ́ ńlá àjọ, Jesu dúró, ó sì kígbe wí pé, “Bí òǹgbẹ bá ń gbẹ ẹnikẹ́ni, kí ó tọ̀ mí wá, kí ó sì mu. Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbà mí gbọ́ gẹ́gẹ́ bí ìwé mímọ́ ti wí, láti inú rẹ̀ ni odò omi ìyè yóò ti máa sàn jáde wá.” (Ṣùgbọ́n ó sọ èyí ní ti ẹ̀mí, tí àwọn tí ó gbà á gbọ́ ń bọ̀ wá gbà: nítorí a kò tí ì fi ẹ̀mí mímọ́ fún ni; nítorí tí a kò tí ì ṣe Jesu lógo.) Nítorí náà nígbà tí ọ̀pọ̀ nínú ìjọ ènìyàn gbọ́ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, wọ́n wí pé, “Lóòótọ́ èyí ni wòlíì náà.” Àwọn mìíràn wí pé, “Èyí ni Kristi náà.” Ṣùgbọ́n àwọn kan wí pé kínla, “Kristi yóò ha ti Galili wá bí? Ìwé mímọ́ kò ha wí pé, Kristi yóò ti inú irú-ọmọ Dafidi wá, àti Bẹtilẹhẹmu, ìlú tí Dafidi ti wá?” Bẹ́ẹ̀ ni ìyapa wà láàrín ìjọ ènìyàn nítorí rẹ̀. Àwọn mìíràn nínú wọn sì fẹ́ láti mú un; ṣùgbọ́n kò sí ẹnìkan tí ó gbé ọwọ́ lé e. Ní ìparí, àwọn ẹ̀ṣọ́ tẹmpili padà tọ àwọn olórí àlùfáà àti àwọn Farisi lọ, wọ́n sì wí fún wọn pé, “Èéṣe tí ẹ̀yin kò fi mú un wá?” Àwọn ẹ̀ṣọ́ dáhùn wí pé, “Kò sí ẹni tí ó tí ì sọ̀rọ̀ bí ọkùnrin yìí rí!” Nítorí náà àwọn Farisi dá wọn lóhùn pé, “A ha tan ẹ̀yin jẹ pẹ̀lú bí? Ǹjẹ́ nínú àwọn ìjòyè, tàbí àwọn Farisi ti gbà á gbọ́ bí? Ṣùgbọ́n ìjọ ènìyàn yìí, tí ko mọ òfin di ẹni ìfibú.” Nikodemu ẹni tí ó tọ Jesu wá lóru rí, tí ó sì jẹ́ ọ̀kan nínú wọn sì sọ fún wọn pé, “Òfin wa ha ń ṣe ìdájọ́ ènìyàn kí ó tó gbọ́ ti ẹnu rẹ̀ àti kí ó tó mọ ohun tí ó ṣe bí?” Wọ́n dáhùn wọ́n sì wí fún un pé, “Ìwọ pẹ̀lú wá láti Galili bí? Wá kiri, kí o sì wò nítorí kò sí wòlíì kan tí ó ti Galili dìde.” Wọ́n sì lọ olúkúlùkù sí ilé rẹ̀.
Joh 7:31-53 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ọ̀pọ ninu ijọ enia si gbà a gbọ́, nwọn si wipe, Nigbati Kristi na ba de, yio ha ṣe iṣẹ àmi jù wọnyi lọ, ti ọkunrin yi ti ṣe? Awọn Farisi gbọ́ pe, ijọ enia nsọ nkan wọnyi labẹlẹ̀ nipa rẹ̀; awọn Farisi ati awọn olori alufã si rán awọn onṣẹ lọ lati mu u. Nitorina Jesu wi fun wọn pe, Niwọn igba diẹ si i li emi wà pẹlu nyin, emi o si lọ sọdọ ẹniti o rán mi. Ẹnyin yio wá mi, ẹnyin kì yio si ri mi: ati ibiti emi ba wà, enyin kì yio le wá. Nitorina li awọn Ju mba ara wọn sọ pe, Nibo ni ọkunrin yi yio gbé lọ, ti awa kì yio fi ri i? yio ha lọ sarin awọn Hellene ti nwọn fọnká kiri, ki o si ma kọ́ awọn Hellene bi? Ọrọ kili eyi ti o sọ yi, Ẹnyin ó wá mi, ẹ kì yio si ri mi: ati ibiti emi ba wà, ẹnyin kì yio le wá? Lọjọ ikẹhìn, ti iṣe ọjọ nla ajọ, Jesu duro, o si kigbe, wipe, Bi òrùngbẹ ba ngbẹ ẹnikẹni, ki o tọ mi wá, ki o si mu. Ẹnikẹni ti o ba gbà mi gbọ́, gẹgẹ bi iwe-mimọ́ ti wi, lati inu rẹ̀ ni odò omi ìye yio ti mã ṣàn jade wá. (Ṣugbọn o sọ eyi niti Ẹmí, ti awọn ti o gbà a gbọ́ mbọ̀wá gbà: nitori a kò ti ifi Ẹmí Mimọ́ funni; nitoriti a kò ti iṣe Jesu logo.) Nitorina nigbati ọ̀pọ ninu ijọ enia gbọ́ ọ̀rọ wọnyi, nwọn wipe, Lotọ eyi ni woli na. Awọn miran wipe, Eyi ni Kristi na. Ṣugbọn awọn kan wipe Kinla, Kristi yio ha ti Galili wá bi? Iwe-mimọ́ kò ha wipe, Kristi yio ti inu irú ọmọ Dafidi wá, ati Betlehemu, ilu ti Dafidi ti wà? Bẹ̃ni iyapa wà larin ijọ enia nitori rẹ̀. Awọn miran ninu wọn si fé lati mu u; ṣugbọn kò si ẹnikan ti o gbé ọwọ́ le e. Nitorina awọn onṣẹ pada tọ̀ awọn olori alufa ati awọn Farisi wá; nwọn si wi fun wọn pe, Ẽṣe ti ẹnyin kò fi mu u wá? Awọn onṣẹ dahùn wipe, Kò si ẹniti o ti isọ̀rọ bi ọkunrin yi ri. Nitorina awọn Farisi da wọn lohùn wipe, A ha tàn ẹnyin jẹ pẹlu bi? O ha si ẹnikan ninu awọn ijoye, tabi awọn Farisi ti o gbà a gbọ́? Ṣugbọn ijọ enia yi, ti kò mọ̀ ofin, di ẹni ifibu. Nikodemu si wi fun wọn pe, (ẹniti o tọ̀ Jesu wá loru, o jẹ ọkan ninu wọn), Ofin wa nṣe idajọ enia ki o to gbọ ti ẹnu rẹ̀, ati ki o to mọ̀ ohun ti o ṣe bi? Nwọn dahùn nwọn si wi fun u pe, Iwọ pẹlu nṣe ara Galili bí? Wá kiri, ki o si wò: nitori kò si woli kan ti o ti Galili dide. Nwọn si lọ olukuluku si ile rẹ̀.