Ọ̀pọ ninu ijọ enia si gbà a gbọ́, nwọn si wipe, Nigbati Kristi na ba de, yio ha ṣe iṣẹ àmi jù wọnyi lọ, ti ọkunrin yi ti ṣe?
Awọn Farisi gbọ́ pe, ijọ enia nsọ nkan wọnyi labẹlẹ̀ nipa rẹ̀; awọn Farisi ati awọn olori alufã si rán awọn onṣẹ lọ lati mu u.
Nitorina Jesu wi fun wọn pe, Niwọn igba diẹ si i li emi wà pẹlu nyin, emi o si lọ sọdọ ẹniti o rán mi.
Ẹnyin yio wá mi, ẹnyin kì yio si ri mi: ati ibiti emi ba wà, enyin kì yio le wá.
Nitorina li awọn Ju mba ara wọn sọ pe, Nibo ni ọkunrin yi yio gbé lọ, ti awa kì yio fi ri i? yio ha lọ sarin awọn Hellene ti nwọn fọnká kiri, ki o si ma kọ́ awọn Hellene bi?
Ọrọ kili eyi ti o sọ yi, Ẹnyin ó wá mi, ẹ kì yio si ri mi: ati ibiti emi ba wà, ẹnyin kì yio le wá?
Lọjọ ikẹhìn, ti iṣe ọjọ nla ajọ, Jesu duro, o si kigbe, wipe, Bi òrùngbẹ ba ngbẹ ẹnikẹni, ki o tọ mi wá, ki o si mu.
Ẹnikẹni ti o ba gbà mi gbọ́, gẹgẹ bi iwe-mimọ́ ti wi, lati inu rẹ̀ ni odò omi ìye yio ti mã ṣàn jade wá.
(Ṣugbọn o sọ eyi niti Ẹmí, ti awọn ti o gbà a gbọ́ mbọ̀wá gbà: nitori a kò ti ifi Ẹmí Mimọ́ funni; nitoriti a kò ti iṣe Jesu logo.)
Nitorina nigbati ọ̀pọ ninu ijọ enia gbọ́ ọ̀rọ wọnyi, nwọn wipe, Lotọ eyi ni woli na.
Awọn miran wipe, Eyi ni Kristi na. Ṣugbọn awọn kan wipe Kinla, Kristi yio ha ti Galili wá bi?
Iwe-mimọ́ kò ha wipe, Kristi yio ti inu irú ọmọ Dafidi wá, ati Betlehemu, ilu ti Dafidi ti wà?
Bẹ̃ni iyapa wà larin ijọ enia nitori rẹ̀.
Awọn miran ninu wọn si fé lati mu u; ṣugbọn kò si ẹnikan ti o gbé ọwọ́ le e.
Nitorina awọn onṣẹ pada tọ̀ awọn olori alufa ati awọn Farisi wá; nwọn si wi fun wọn pe, Ẽṣe ti ẹnyin kò fi mu u wá?
Awọn onṣẹ dahùn wipe, Kò si ẹniti o ti isọ̀rọ bi ọkunrin yi ri.
Nitorina awọn Farisi da wọn lohùn wipe, A ha tàn ẹnyin jẹ pẹlu bi?
O ha si ẹnikan ninu awọn ijoye, tabi awọn Farisi ti o gbà a gbọ́?
Ṣugbọn ijọ enia yi, ti kò mọ̀ ofin, di ẹni ifibu.
Nikodemu si wi fun wọn pe, (ẹniti o tọ̀ Jesu wá loru, o jẹ ọkan ninu wọn),
Ofin wa nṣe idajọ enia ki o to gbọ ti ẹnu rẹ̀, ati ki o to mọ̀ ohun ti o ṣe bi?
Nwọn dahùn nwọn si wi fun u pe, Iwọ pẹlu nṣe ara Galili bí? Wá kiri, ki o si wò: nitori kò si woli kan ti o ti Galili dide.
Nwọn si lọ olukuluku si ile rẹ̀.