Joh 19:1-30

Joh 19:1-30 Bibeli Mimọ (YBCV)

NITORINA ni Pilatu mu Jesu, o si nà á. Awọn ọmọ-ogun si hun ade ẹgún, nwọn si fi de e li ori, nwọn si fi aṣọ igunwà elesè àluko wọ̀ ọ. Nwọn si wipe, Kabiyesi, Ọba awọn Ju! nwọn si fi ọwọ́ wọn gbá a loju. Pilatu si tún jade, o si wi fun wọn pe, Wo o, mo mu u jade tọ̀ nyin wá, ki ẹnyin ki o le mọ̀ pe, emi kò ri ẹ̀ṣẹ kan lọwọ rẹ̀. Nitorina Jesu jade wá, ti on ti ade ẹgún ati aṣọ elesè àluko. Pilatu si wi fun wọn pe, Ẹ wò ọkunrin na! Nitorina nigbati awọn olori alufa, ati awọn onṣẹ ri i, nwọn kigbe wipe, Kàn a mọ agbelebu, kàn a mọ agbelebu. Pilatu wi fun wọn pe, Ẹ mu u fun ara nyin, ki ẹ si kàn a mọ agbelebu: nitoriti emi ko ri ẹ̀ṣẹ lọwọ rẹ̀. Awọn Ju da a lohùn wipe, Awa li ofin kan, ati gẹgẹ bi ofin wa o yẹ lati kú, nitoriti o fi ara rẹ̀ ṣe Ọmọ Ọlọrun. Nitorina nigbati Pilatu gbọ́ ọ̀rọ yi ẹ̀ru tubọ ba a. O si tun wọ̀ inu gbọ̀ngan idajọ lọ, o si wi fun Jesu pe, Nibo ni iwọ ti wá? Ṣugbọn Jesu kò da a lohùn. Nitorina Pilatu wi fun u pe, Emi ni iwọ ko fọhun si? iwọ kò mọ̀ pe, emi li agbara lati dá ọ silẹ, emi si li agbara lati kàn ọ mọ agbelebu? Jesu da a lohun pe, Iwọ kì ba ti li agbara kan lori mi, bikoṣepe a fi i fun ọ lati oke wá: nitorina ẹniti o fi mi le ọ lọwọ li o ni ẹ̀ṣẹ pọ̀ju. Nitori eyi Pilatu nwá ọ̀na lati dá a silẹ: ṣugbọn awọn Ju kigbe, wipe, Bi iwọ ba dá ọkunrin yi silẹ, iwọ kì iṣe ọrẹ́ Kesari: ẹnikẹni ti o ba ṣe ara rẹ̀ li ọba, o sọ̀rọ òdi si Kesari. Nitorina nigbati Pilatu gbọ́ ọ̀rọ wọnyi, o mu Jesu jade wá, o si joko lori itẹ́ idajọ ti a npè ni Okuta-titẹ, ṣugbọn li ede Heberu, Gabbata. O jẹ Ipalẹmọ́ ajọ irekọja, o jẹ iwọn wakati ẹkẹfa: o si wi fun awọn Ju pe, Ẹ wò Ọba nyin! Nitorina nwọn kigbe wipe, Mu u kuro, mu u kuro, kàn a mọ agbelebu. Pilatu wi fun wọn pe, Emi o ha kàn Ọba nyin mọ agbelebu bi? Awọn olori alufa dahùn wipe, Awa kò li ọba bikoṣe Kesari. Nigbana li o fà a le wọn lọwọ lati kàn a mọ agbelebu. Wọ́n bá gba Jesu lọ́wọ́ Pilatu. Nitorina nwọn mu Jesu, o si jade lọ, o rù agbelebu fun ara rẹ̀ si ibi ti a npè ni Ibi-agbari, li ede Heberu ti a npè ni Golgota: Nibiti nwọn gbé kàn a mọ agbelebu, ati awọn meji miran pẹlu rẹ̀, niha ikini ati nìha keji, Jesu si wà larin. Pilatu si kọ iwe akọle kan pẹlu, o si fi i le ori agbelebu na. Ohun ti a si kọ ni, JESU TI NASARETI ỌBA AWỌN JU. Nitorina ọpọ awọn Ju li o kà iwe akọle yi: nitori ibi ti a gbé kàn Jesu mọ agbelebu sunmọ eti ilu: a si kọ ọ li ède Heberu, ati ti Latini, ati ti Helene. Nitorina awọn olori alufa awọn Ju wi fun Pilatu pe, Máṣe kọ ọ pe, Ọba awọn Ju; ṣugbọn pe on wipe, Emi li Ọba awọn Ju. Pilatu dahùn pe, Ohun ti mo ti kọ tan, mo ti kọ na. Nigbana li awọn ọmọ-ogun, nigbati nwọn kàn Jesu mọ agbelebu tan, nwọn mu aṣọ rẹ̀, nwọn si pín wọn si ipa mẹrin, apakan fun ọmọ-ogun kọkan, ati àwọtẹlẹ rẹ̀: ṣugbọn àwọ̀tẹlẹ na kò li ojuran, nwọn hun u lati oke titi jalẹ. Nitorina nwọn wi fun ara wọn pe, Ẹ má jẹ ki a fà a ya, ṣugbọn ki a ṣẹ kèké nitori rẹ̀, ti ẹniti yio jẹ: ki iwe-mimọ́ ki o le ṣẹ, ti o wipe, Nwọn pín aṣọ mi larin ara wọn, nwọn si ṣẹ kèké fun aṣọ ileke mi. Nkan wọnyi li awọn ọmọ-ogun ṣe. Iya Jesu ati arabinrin iya rẹ̀ Maria aya Klopa, ati Maria Magdalene, si duro nibi agbelebu. Nitorina nigbati Jesu ri iya rẹ̀, ati ọmọ-ẹhin na duro, ẹniti Jesu fẹràn, o wi fun iya rẹ̀ pe, Obinrin, wò ọmọ rẹ! Lẹhin na li o si wi fun ọmọ-ẹhin na pe, Wò iya rẹ! Lati wakati na lọ li ọmọ-ẹhin na si ti mu u lọ si ile ara rẹ̀. Lẹhin eyi, bi Jesu ti mọ̀ pe, a ti pari ohun gbogbo tan, ki iwe-mimọ́ le ba ṣẹ, o wipe, Orungbẹ ngbẹ mi. A gbé ohun èlo kan kalẹ nibẹ̀ ti o kún fun ọti kikan: nwọn si fi sponge ti o kun fun ọti kikan, sori igi hissopu, nwọn si fi si i li ẹnu. Nitorina nigbati Jesu si ti gbà ọti kikan na, o wipe, O pari: o si tẹ ori rẹ̀ ba, o jọwọ ẹmí rẹ̀ lọwọ.

Joh 19:1-30 Yoruba Bible (YCE)

Nígbà náà ni Pilatu mú Jesu, ó ní kí wọ́n nà án. Àwọn ọmọ-ogun bá fi ìtàkùn ẹlẹ́gùn-ún hun adé, wọ́n fi dé e lórí; wọn wọ̀ ọ́ ní ẹ̀wù kan bíi ẹ̀wù àlàárì, wọ́n wá ń lọ sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n ń kí i pé, “Kabiyesi! Ọba àwọn Juu!” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń gbá a létí. Pilatu tún jáde lọ sóde, ó sọ fún àwọn Juu pé, “Mò ń mú un tọ̀ yín bọ̀ wá sóde, kí ẹ lè mọ̀ pé èmi kò rí i pé ó jẹ̀bi ohunkohun.” Nígbà náà ni Jesu jáde pẹlu adé ẹ̀gún ati ẹ̀wù àlàárì. Pilatu wá sọ fún wọn pé, “Ẹ wò ó, ọkunrin náà nìyí.” Nígbà tí àwọn olórí alufaa ati àwọn ẹ̀ṣọ́ rí i, wọ́n kígbe pé, “Kàn án mọ́ agbelebu!” Pilatu sọ fún wọn pé, “Ẹ̀yin fúnra yín ẹ mú un, kí ẹ kàn án mọ́ agbelebu, nítorí ní tèmi, n kò rí ẹ̀bi kankan tí ó jẹ.” Àwọn Juu dá a lóhùn pé, “A ní òfin kan, nípa òfin náà, ikú ni ó tọ́ sí i, nítorí ó fi ara rẹ̀ ṣe Ọmọ Ọlọrun.” Nígbà tí Pilatu gbọ́ gbolohun yìí, ẹ̀rù túbọ̀ bà á. Ó bá tún wọ ààfin lọ, ó bi Jesu pé, “Níbo ni o ti wá?” Ṣugbọn Jesu kò dá a lóhùn. Nígbà náà ni Pilatu sọ fún un pé, “Èmi ni ìwọ kò dá lóhùn? O kò mọ̀ pé mo ní àṣẹ láti dá ọ sílẹ̀, mo sì ní àṣẹ láti kàn ọ́ mọ́ agbelebu?” Jesu dá a lóhùn pé, “O kò ní àṣẹ lórí mi àfi èyí tí a ti fi fún ọ láti òkè wá. Nítorí náà, ẹni tí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ pọ̀jù ni ẹni tí ó fà mí lé ọ lọ́wọ́.” Láti ìgbà náà ni Pilatu ti ń wá ọ̀nà láti dá Jesu sílẹ̀. Ṣugbọn àwọn Juu ń kígbe pé, “Bí o bá dá ọkunrin yìí sílẹ̀, ìwọ kì í ṣe ọ̀rẹ́ Kesari, gbogbo ẹni tí ó bá fi ara rẹ̀ jọba lòdì sí Kesari.” Nígbà tí Pilatu gbọ́ bẹ́ẹ̀, ó mú Jesu jáde, ó wá jókòó lórí pèpéle ìdájọ́ níbìkan tí wọn ń pè ní “Pèpéle olókùúta,” tí ń jẹ́ “Gabata” ní èdè Heberu. Ọjọ́ ìpalẹ̀mọ́ fún Àjọ̀dún Ìrékọjá ni ọjọ́ náà. Ó tó nǹkan agogo mejila ọ̀sán. Pilatu sọ fún àwọn Juu pé, “Ọba yín nìyí!” Ṣugbọn àwọn Juu kígbe pé, “Mú un kúrò! Mú un kúrò! Kàn án mọ́ agbelebu!” Pilatu sọ fún wọn pé, “Kí n kan ọba yín mọ́ agbelebu?” Àwọn olórí alufaa dá a lóhùn pé, “A kò ní ọba lẹ́yìn Kesari.” Pilatu bá fa Jesu fún wọn láti kàn mọ́ agbelebu. Wọ́n bá gba Jesu lọ́wọ́ Pilatu. Ó ru agbelebu rẹ̀ jáde lọ sí ibìkan tí ó ń jẹ́ “Ibi Agbárí,” tí wọn ń pè ní “Gọlgọta” ní èdè Heberu. Níbẹ̀ ni wọ́n ti kàn án mọ́ agbelebu, òun ati àwọn meji kan, ọ̀kan ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀tún, ọ̀kan ní ẹ̀gbẹ́ òsì, Jesu wá wà láàrin. Pilatu kọ àkọlé kan, ó fi sórí agbelebu. Ohun tí ó kọ sórí rẹ̀ ni pé, “Jesu ará Nasarẹti, ọba àwọn Juu.” Pupọ ninu àwọn Juu ni ó ka àkọlé náà ní èdè Heberu ati ti Latini ati ti Giriki. Àwọn olórí alufaa àwọn Juu sọ fún Pilatu pé, “Má ṣe kọ ọ́ pé ‘Ọba àwọn Juu,’ ṣugbọn kọ ọ́ báyìí: ‘Ó ní: èmi ni ọba àwọn Juu.’ ” Ṣugbọn Pilatu dá wọn lóhùn pé, “Ohun tí mo ti kọ, mo ti kọ ọ́ ná.” Nígbà tí wọ́n kan Jesu mọ́ agbelebu tán, àwọn ọmọ-ogun pín àwọn aṣọ rẹ̀ sí ọ̀nà mẹrin, wọ́n mú un ní ọ̀kọ̀ọ̀kan. Ó wá tún ku àwọ̀tẹ́lẹ̀ rẹ̀. Àwọ̀tẹ́lẹ̀ yìí kò ní ojúùrán, híhun ni wọ́n hun ún láti òkè dé ilẹ̀. Wọ́n bá ara wọn sọ pé, “Ẹ má jẹ́ kí á ya á, gègé ni kí ẹ jẹ́ kí á ṣẹ́ láti mọ ti ẹni tí yóo jẹ́.” Èyí rí bẹ́ẹ̀ kí Ìwé Mímọ́ lè ṣẹ tí ó wí pé, “Wọ́n pín aṣọ mi láàrin ara wọn, wọ́n ṣẹ́ gègé lórí ẹ̀wù mi.” Bẹ́ẹ̀ gan-an ni àwọn ọmọ-ogun sì ṣe. Ìyá Jesu ati arabinrin ìyá rẹ̀ ati Maria aya Kilopasi ati Maria Magidaleni dúró lẹ́bàá agbelebu Jesu. Nígbà tí Jesu rí ìyá rẹ̀ ati ọmọ-ẹ̀yìn tí ó fẹ́ràn tí wọ́n dúró, ó wí fún ìyá rẹ̀ pé, “Obinrin, wo ọmọ rẹ.” Ó bá sọ fún ọmọ-ẹ̀yìn náà pé, “Wo ìyá rẹ.” Láti ìgbà náà ni ọmọ-ẹ̀yìn náà ti mú ìyá Jesu lọ sílé ara rẹ̀. Lẹ́yìn èyí, nígbà tí Jesu mọ̀ pé ohun gbogbo ti parí, kí Ìwé Mímọ́ lè ṣẹ, ó ní, “Òùngbẹ ń gbẹ mí.” Àwo ọtí kan wà níbẹ̀. Wọ́n bá fi kinní kan bíi kànìnkànìn bọ inú ọtí náà, wọ́n fi sórí ọ̀pá gígùn kan, wọ́n nà án sí i lẹ́nu. Lẹ́yìn tí Jesu ti gba ọtí náà tán, ó wí pé, “Ó ti parí!” Lẹ́yìn náà ó tẹrí ba, ó bá dákẹ́.

Joh 19:1-30 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Nítorí náà ni Pilatu mú Jesu, ó sì nà án. Àwọn ọmọ-ogun sì hun adé ẹ̀gún, wọ́n sì fi dé e ní orí, wọ́n sì fi aṣọ ìgúnwà elése àlùkò wọ̀ ọ́. Wọ́n sì wí pé, “Kábíyèsí, ọba àwọn Júù!” Wọ́n sì fi ọwọ́ wọn gbá a ní ojú. Pilatu sì tún jáde, ó sì wí fún wọn pé, “Wò ó, mo mú u jáde tọ̀ yín wá, kí ẹ̀yin kí ó lè mọ̀ pé, èmi kò rí ẹ̀ṣẹ̀ kan lọ́wọ́ rẹ̀.” Nítorí náà Jesu jáde wá, ti òun ti adé ẹ̀gún àti aṣọ elése àlùkò. Pilatu sì wí fún wọn pé, Ẹ wò ọkùnrin náà! Nítorí náà nígbà tí àwọn olórí àlùfáà, àti àwọn oníṣẹ́ rí i, wọ́n kígbe wí pé, “Kàn án mọ́ àgbélébùú, kàn án mọ́ àgbélébùú.” Pilatu wí fún wọn pé, “Ẹ mú un fún ara yín, kí ẹ sì kàn án mọ́ àgbélébùú: nítorí èmi kò rí ẹ̀ṣẹ̀ lọ́wọ́ rẹ̀.” Àwọn Júù dá a lóhùn wí pé, “Àwa ní òfin kan, àti gẹ́gẹ́ bí òfin, wa ó yẹ fún un láti kú, nítorí ó gbà pé ọmọ Ọlọ́run ni òun ń ṣe.” Nítorí náà nígbà tí Pilatu gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, ẹ̀rù túbọ̀ bà á. Ó sì tún wọ inú gbọ̀ngàn ìdájọ́ lọ, ó sì wí fún Jesu pé, “Níbo ni ìwọ ti wá?” Ṣùgbọ́n Jesu kò dá a lóhùn. Nítorí náà, Pilatu wí fún un pé, “Èmi ni ìwọ kò fọhùn sí? Ìwọ kò mọ̀ pé, èmi ní agbára láti dá ọ sílẹ̀, èmi sì ní agbára láti kàn ọ́ mọ́ àgbélébùú?” Jesu dá a lóhùn pé, “Ìwọ kì bá tí ní agbára kan lórí mi, bí kò ṣe pé a fi í fún ọ láti òkè wá: nítorí náà ẹni tí ó fi mí lé ọ lọ́wọ́ ni ó ní ẹ̀ṣẹ̀ pọ̀jù.” Nítorí èyí, Pilatu ń wá ọ̀nà láti dá a sílẹ̀: ṣùgbọ́n àwọn Júù kígbe, wí pé, “Bí ìwọ bá dá ọkùnrin yìí sílẹ̀, ìwọ kì í ṣe ọ̀rẹ́ Kesari: ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe ara rẹ̀ ní ọba, ó sọ̀rọ̀-òdì sí Kesari.” Nítorí náà nígbà tí Pilatu gbọ́ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, ó mú Jesu jáde wá, ó sì jókòó lórí ìtẹ́ ìdájọ́ ní ibi tí a ń pè ní Òkúta-títẹ́, ṣùgbọ́n ní èdè Heberu, Gabata. Ó jẹ́ ìpalẹ̀mọ́ àjọ ìrékọjá, ó sì jẹ́ ìwọ̀n wákàtí ẹ̀kẹfà: Ó sì wí fún àwọn Júù pé, “Ẹ wo ọba yín!” Nítorí náà wọ́n kígbe wí pé, “Mú un kúrò, mú un kúrò. Kàn án mọ́ àgbélébùú.” Pilatu wí fún wọn pé, “Èmi yóò ha kan ọba yín mọ́ àgbélébùú bí?” Àwọn olórí àlùfáà dáhùn wí pé, “Àwa kò ní ọba bí kò ṣe Kesari.” Nítorí náà ni Pilatu fà á lé wọn lọ́wọ́ láti kàn án mọ́ àgbélébùú. Àwọn ológun gba Jesu lọ́wọ́ Pilatu. Nítorí náà, wọ́n mú Jesu, ó sì jáde lọ, ó ru àgbélébùú fúnrarẹ̀ sí ibi tí à ń pè ní ibi agbárí, ní èdè Heberu tí à ń pè ní Gọlgọta: Níbi tí wọ́n gbé kàn án mọ́ àgbélébùú, àti àwọn méjì mìíràn pẹ̀lú rẹ̀, níhà ìhín àti níhà kejì, Jesu sì wà láàrín. Pilatu sì kọ ìwé kan pẹ̀lú, ó sì fi lé e lórí àgbélébùú náà. Ohun tí a sì kọ ni, jesu ti nasareti ọba àwọn júù. Nítorí náà, ọ̀pọ̀ àwọn Júù ni ó ka ìwé àkọlé yìí: nítorí ibi tí a gbé kan Jesu mọ́ àgbélébùú súnmọ́ etí ìlú: a sì kọ ọ́ ní èdè Heberu àti Latin, àti ti Giriki. Nítorí náà àwọn olórí àlùfáà àwọn Júù wí fún Pilatu pé, “Má ṣe kọ, ‘ọba àwọn Júù;’ ṣùgbọ́n pé ọkùnrin yìí wí pé, èmi ni ọba àwọn Júù.” Pilatu dáhùn pé, ohun tí mo ti kọ, mo ti kọ ọ́. Nígbà náà ni àwọn ọmọ-ogun, nígbà tí wọ́n kan Jesu mọ́ àgbélébùú tán, wọ́n mú aṣọ rẹ̀, wọ́n sì pín wọn sí ipa mẹ́rin, apá kan fún ọmọ-ogun kọ̀ọ̀kan, àti ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀ rẹ̀: ṣùgbọ́n ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀ náà kò ní ojúràn-án, wọ́n hun ún láti òkè títí jálẹ̀. Nítorí náà wọ́n wí fún ara wọn pé, “Ẹ má jẹ́ kí a fà á ya, ṣùgbọ́n kí a ṣẹ́ gègé nítorí rẹ̀.” Ti ẹni tí yóò jẹ́: kí ìwé mímọ́ kí ó le ṣẹ, tí ó wí pé, “Wọ́n pín aṣọ mi láàrín ara wọn, wọ́n sì ṣẹ́ gègé fún aṣọ ìlekè mi.” Nǹkan wọ̀nyí ni àwọn ọmọ-ogun ṣe. Ìyá Jesu àti arábìnrin ìyá rẹ̀ Maria aya Kilopa, àti Maria Magdalene sì dúró níbi àgbélébùú, Nígbà tí Jesu rí ìyá rẹ̀ àti ọmọ-ẹ̀yìn náà dúró, ẹni tí Jesu fẹ́ràn, ó wí fún ìyá rẹ̀ pé, “Obìnrin, wo ọmọ rẹ!” Lẹ́yìn náà ni ó sì wí fún ọmọ-ẹ̀yìn náà pé, “Wo ìyá rẹ!” Láti wákàtí náà lọ ni ọmọ-ẹ̀yìn náà sì ti mú un lọ sí ilé ara rẹ̀. Lẹ́yìn èyí, bí Jesu ti mọ̀ pé, a ti parí ohun gbogbo tán, kí ìwé mímọ́ bà á lè ṣẹ, ó wí pé, “Òrùngbẹ ń gbẹ mí.” Ohun èlò kan tí ó kún fún ọtí kíkan wà níbẹ̀, wọ́n tẹ kànìnkànìn tí ó kún fún ọtí kíkan bọ inú rẹ̀, wọ́n sì fi lé orí igi hísópù, wọ́n sì nà án sí i lẹ́nu. Nígbà tí Jesu sì ti gba ọtí kíkan náà, ó wí pé, “Ó parí!” Ó sì tẹ orí rẹ̀ ba, ó jọ̀wọ́ ẹ̀mí rẹ̀.