Nígbà náà ni Pilatu mú Jesu, ó ní kí wọ́n nà án. Àwọn ọmọ-ogun bá fi ìtàkùn ẹlẹ́gùn-ún hun adé, wọ́n fi dé e lórí; wọn wọ̀ ọ́ ní ẹ̀wù kan bíi ẹ̀wù àlàárì, wọ́n wá ń lọ sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n ń kí i pé, “Kabiyesi! Ọba àwọn Juu!” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń gbá a létí.
Pilatu tún jáde lọ sóde, ó sọ fún àwọn Juu pé, “Mò ń mú un tọ̀ yín bọ̀ wá sóde, kí ẹ lè mọ̀ pé èmi kò rí i pé ó jẹ̀bi ohunkohun.” Nígbà náà ni Jesu jáde pẹlu adé ẹ̀gún ati ẹ̀wù àlàárì. Pilatu wá sọ fún wọn pé, “Ẹ wò ó, ọkunrin náà nìyí.”
Nígbà tí àwọn olórí alufaa ati àwọn ẹ̀ṣọ́ rí i, wọ́n kígbe pé, “Kàn án mọ́ agbelebu!”
Pilatu sọ fún wọn pé, “Ẹ̀yin fúnra yín ẹ mú un, kí ẹ kàn án mọ́ agbelebu, nítorí ní tèmi, n kò rí ẹ̀bi kankan tí ó jẹ.”
Àwọn Juu dá a lóhùn pé, “A ní òfin kan, nípa òfin náà, ikú ni ó tọ́ sí i, nítorí ó fi ara rẹ̀ ṣe Ọmọ Ọlọrun.”
Nígbà tí Pilatu gbọ́ gbolohun yìí, ẹ̀rù túbọ̀ bà á. Ó bá tún wọ ààfin lọ, ó bi Jesu pé, “Níbo ni o ti wá?”
Ṣugbọn Jesu kò dá a lóhùn. Nígbà náà ni Pilatu sọ fún un pé, “Èmi ni ìwọ kò dá lóhùn? O kò mọ̀ pé mo ní àṣẹ láti dá ọ sílẹ̀, mo sì ní àṣẹ láti kàn ọ́ mọ́ agbelebu?”
Jesu dá a lóhùn pé, “O kò ní àṣẹ lórí mi àfi èyí tí a ti fi fún ọ láti òkè wá. Nítorí náà, ẹni tí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ pọ̀jù ni ẹni tí ó fà mí lé ọ lọ́wọ́.”
Láti ìgbà náà ni Pilatu ti ń wá ọ̀nà láti dá Jesu sílẹ̀. Ṣugbọn àwọn Juu ń kígbe pé, “Bí o bá dá ọkunrin yìí sílẹ̀, ìwọ kì í ṣe ọ̀rẹ́ Kesari, gbogbo ẹni tí ó bá fi ara rẹ̀ jọba lòdì sí Kesari.”
Nígbà tí Pilatu gbọ́ bẹ́ẹ̀, ó mú Jesu jáde, ó wá jókòó lórí pèpéle ìdájọ́ níbìkan tí wọn ń pè ní “Pèpéle olókùúta,” tí ń jẹ́ “Gabata” ní èdè Heberu. Ọjọ́ ìpalẹ̀mọ́ fún Àjọ̀dún Ìrékọjá ni ọjọ́ náà. Ó tó nǹkan agogo mejila ọ̀sán. Pilatu sọ fún àwọn Juu pé, “Ọba yín nìyí!”
Ṣugbọn àwọn Juu kígbe pé, “Mú un kúrò! Mú un kúrò! Kàn án mọ́ agbelebu!”
Pilatu sọ fún wọn pé, “Kí n kan ọba yín mọ́ agbelebu?”
Àwọn olórí alufaa dá a lóhùn pé, “A kò ní ọba lẹ́yìn Kesari.”
Pilatu bá fa Jesu fún wọn láti kàn mọ́ agbelebu.
Wọ́n bá gba Jesu lọ́wọ́ Pilatu. Ó ru agbelebu rẹ̀ jáde lọ sí ibìkan tí ó ń jẹ́ “Ibi Agbárí,” tí wọn ń pè ní “Gọlgọta” ní èdè Heberu. Níbẹ̀ ni wọ́n ti kàn án mọ́ agbelebu, òun ati àwọn meji kan, ọ̀kan ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀tún, ọ̀kan ní ẹ̀gbẹ́ òsì, Jesu wá wà láàrin. Pilatu kọ àkọlé kan, ó fi sórí agbelebu. Ohun tí ó kọ sórí rẹ̀ ni pé, “Jesu ará Nasarẹti, ọba àwọn Juu.” Pupọ ninu àwọn Juu ni ó ka àkọlé náà ní èdè Heberu ati ti Latini ati ti Giriki. Àwọn olórí alufaa àwọn Juu sọ fún Pilatu pé, “Má ṣe kọ ọ́ pé ‘Ọba àwọn Juu,’ ṣugbọn kọ ọ́ báyìí: ‘Ó ní: èmi ni ọba àwọn Juu.’ ”
Ṣugbọn Pilatu dá wọn lóhùn pé, “Ohun tí mo ti kọ, mo ti kọ ọ́ ná.”
Nígbà tí wọ́n kan Jesu mọ́ agbelebu tán, àwọn ọmọ-ogun pín àwọn aṣọ rẹ̀ sí ọ̀nà mẹrin, wọ́n mú un ní ọ̀kọ̀ọ̀kan. Ó wá tún ku àwọ̀tẹ́lẹ̀ rẹ̀. Àwọ̀tẹ́lẹ̀ yìí kò ní ojúùrán, híhun ni wọ́n hun ún láti òkè dé ilẹ̀. Wọ́n bá ara wọn sọ pé, “Ẹ má jẹ́ kí á ya á, gègé ni kí ẹ jẹ́ kí á ṣẹ́ láti mọ ti ẹni tí yóo jẹ́.” Èyí rí bẹ́ẹ̀ kí Ìwé Mímọ́ lè ṣẹ tí ó wí pé,
“Wọ́n pín aṣọ mi láàrin ara wọn,
wọ́n ṣẹ́ gègé lórí ẹ̀wù mi.”
Bẹ́ẹ̀ gan-an ni àwọn ọmọ-ogun sì ṣe.
Ìyá Jesu ati arabinrin ìyá rẹ̀ ati Maria aya Kilopasi ati Maria Magidaleni dúró lẹ́bàá agbelebu Jesu. Nígbà tí Jesu rí ìyá rẹ̀ ati ọmọ-ẹ̀yìn tí ó fẹ́ràn tí wọ́n dúró, ó wí fún ìyá rẹ̀ pé, “Obinrin, wo ọmọ rẹ.”
Ó bá sọ fún ọmọ-ẹ̀yìn náà pé, “Wo ìyá rẹ.” Láti ìgbà náà ni ọmọ-ẹ̀yìn náà ti mú ìyá Jesu lọ sílé ara rẹ̀.
Lẹ́yìn èyí, nígbà tí Jesu mọ̀ pé ohun gbogbo ti parí, kí Ìwé Mímọ́ lè ṣẹ, ó ní, “Òùngbẹ ń gbẹ mí.”
Àwo ọtí kan wà níbẹ̀. Wọ́n bá fi kinní kan bíi kànìnkànìn bọ inú ọtí náà, wọ́n fi sórí ọ̀pá gígùn kan, wọ́n nà án sí i lẹ́nu. Lẹ́yìn tí Jesu ti gba ọtí náà tán, ó wí pé, “Ó ti parí!”
Lẹ́yìn náà ó tẹrí ba, ó bá dákẹ́.